Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Citizens

43 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ǹjẹ́ bi a kò tilẹ̀ sọ̀rọ̀-òdì sí nǹkan wọ̀nyí, ó yẹ kí ẹ dákẹ́, kí ẹ̀yin má ṣe fi ìkanra ṣe ohunkóhun.

  2. Nítorí ti ẹ̀yin mú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí wá, wọn kò ja ilé òrìṣà lólè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ̀rọ̀-òdì sí òrìṣà wa.

  3. Ǹjẹ́ nítorí náà tí Demetriusi, àti àwọn oníṣẹ́-ọnà tí o wà pẹ̀lú rẹ̀ bá ní gbólóhùn asọ̀ kan sí ẹnikẹ́ni, ilé ẹjọ́ ṣí sílẹ̀, àwọn onídàájọ́ sì ń bẹ: jẹ́ kí wọn lọ fi ara wọn sùn.

  4. Ṣùgbọ́n bí ẹ ba ń wádìí ohun kan nípa ọ̀ràn mìíràn, a ó parí rẹ̀ ni àjọ tí ó tọ́.

  5. Nítorí àwa ṣa wà nínú ewu, nítorí rògbòdìyàn tí ó bẹ́ sílẹ̀ lónìí yìí; kò ṣáá ní ìdí kan tí rògbòdìyàn yìí fi bẹ́ sílẹ̀, nítorí èyí àwa kì yóò lè dáhùn fún ìwọ́jọ yìí.”

  6. Nígbà tí ó sì ti sọ bẹ́ẹ̀ tan, ó tú ìjọ náà ká.

  7. Kí olúkúlùkù ọkàn kí ó foríbalẹ̀ fún àwọn aláṣẹ tí ó wà ní ipò gíga. Nítorí kò sí àṣẹ kan, bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá; àwọn aláṣẹ tí ó sì wà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni a ti lànà rẹ̀ wá.

  8. Nítorí ẹni tí ó bá tàpá sí àṣẹ, ó tàpá sí ìlànà Ọlọ́run; àwọn ẹni tí ó ba sì ń tàpá, yóò gba ẹ̀bi fún ara wọn.

  9. Nítorí àwọn ìjòyè kò wá láti dẹ́rùbà àwọn tí ń ṣe rere, bí kò ṣe àwọn tó ń ṣe búburú. Ǹjẹ́ ìwọ ha fẹ́ di òmìnira kúrò nínú ẹ̀rù ẹni tó wà ní ipò àṣẹ. Nítorí náà ṣe èyí tó ó dára, ìwọ yóò sì gba ìyìn láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.

  10. Nítorí náà, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ má tẹríba fún àwọn aláṣẹ, kì í ṣe nítorí ti ìbínú nìkan, ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀rí ọkàn pẹ̀lú.

  11. Nítorí ìdí èyí, ẹ san owó òde pẹ̀lú, nítorí ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni wọ́n, èyí náà ni wọ́n ń bojútó nígbà gbogbo.

  12. Ẹ san ohun tí ó tọ́ fún ẹni gbogbo: owó òde fún ẹni tí owó òde í ṣe tirẹ̀: owó bodè fún ẹni tí owó bodè í ṣe tirẹ̀: ẹ̀rù fún ẹni tí ẹ̀rù í ṣe tirẹ̀; ọlá fún ẹni tí ọlá í ṣe tirẹ̀.

  13. Nítorí náà mo gbà yín níyànjú ṣáájú ohun gbogbo, pé kí a máa bẹ̀bẹ̀, kí a máa gbàdúrà, kí a máa ṣìpẹ̀, àti kí a máa dúpẹ́ nítorí gbogbo ènìyàn.

  14. Fún àwọn ọba, àti gbogbo àwọn tí ó wà ni ipò àṣẹ, kí a lè máa lo ayé wa ní àlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ pẹ̀lú nínú gbogbo ìwà-bí-Ọlọ́run àti ìwà mímọ́.

  15. Ẹ máa tẹríba fún gbogbo ìlànà ènìyàn nítorí ti Olúwa, ìbá à ṣe fún ọba tàbí fún olórí.

  16. Tàbí fún àwọn baálẹ̀, fún àwọn tí a rán láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti gbẹ̀san lára àwọn tí ń ṣe búburú, àti fún ìyìn àwọn tí ń ṣe rere.

  17. Ìfẹ́ Ọlọ́run sá ni èyí pé, ní rere í ṣe, kí ẹ lè dẹ́kun ọ̀rọ̀ àìmọ̀kan òmùgọ̀ ènìyàn.

  18. Ẹ máa gbé gẹ́gẹ́ bí ẹni òmìnira, ṣùgbọ́n ẹ ma ṣe lo òmìnira yín láti bo ibi mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n kí ẹ gbé gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run.