Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Benedictions: Apostolic, forms of

11 ẹsẹ · 6 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Apostolic, forms of

  1. Kí Ọlọ́run, ẹni tí ń fún ni ní sùúrù àti ìtùnú fún yin láti ní inú kan sí ara yín gẹ́gẹ́ bí i Jesu Kristi,

  2. kí ẹ̀yin kí ó lè fi ọkàn kan àti ẹnu kan fi ògo fún Ọlọ́run, Baba Olúwa wa Jesu Kristi.

  3. Àlàáfíà fún àwọn ará, àti ìfẹ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wà, àti Olúwa wà Jesu Kristi.

  4. Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó fẹ́ Olúwa wa Jesu Kristi ni àìṣẹ̀tàn.

  5. Ǹjẹ́ Ọlọ́run àlàáfíà, ẹni tí o tún mu olùṣọ́-àgùntàn ńlá ti àwọn àgùntàn, ti inú òkú wá, nípa ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú ayérayé, àní Olúwa wa Jesu.

  6. Kí ó mú yín pé nínú iṣẹ́ rere gbogbo láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, kí ó máa ṣiṣẹ́ ohun tí i ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú rẹ̀ nínú yín nípasẹ̀ Jesu Kristi; ẹni tí ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín.

  7. Ọlọ́run oore-ọ̀fẹ́ gbogbo, tí ó ti pè yín sínú ògo rẹ̀ tí kò nípẹ̀kun nínú Kristi Jesu, nígbà tí ẹ̀yin bá ti jìyà díẹ̀, òun tìkára rẹ̀, yóò sì ṣe yín ní àṣepé, yóò fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, yóò fún yín lágbára, yóò fi ìdí yín kalẹ̀.

  8. Tìrẹ ni ògo àti agbára títí láé. Àmín.

  9. Kí oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà máa bí sí i fún yín nínú ìmọ̀ Ọlọ́run àti ti Jesu Olúwa wa.

  10. Bí agbára rẹ̀ bí Ọlọ́run ti fún wa ní ohun gbogbo tí a nílò fún ṣe ti ìyè àti ti ìwà-bí-Ọlọ́run, nípa ìmọ̀ ẹni tí ó pè wá nípa Ògo àti ìṣeun rẹ̀.

  11. Nípa èyí tí ó fi àwọn ìlérí rẹ̀ tí ó tóbi púpọ̀ tí ó ṣe iyebíye fún wa: pé nípa ìwọ̀nyí ni kí ẹ̀yin lè di alábápín nínú àbùdá ti Ọlọ́run, nígbà tí ẹ̀yin bá ti yọ kúrò nínú ìbàjẹ́ tí ó ń bẹ nínú ayé nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.