Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Atonement: Unclassified scriptures relating to

91 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Unclassified scriptures relating to

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ẹbọ àti ẹran ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́, ìwọ ti ṣí mi ní etí. Ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni ìwọ kò béèrè.

  2. Nígbà náà ni mo wí pé, “Èmi nìyí; nínú ìwé kíká ni a kọ ọ nípa tèmi wí pé.

  3. Mo ní inú dídùn láti ṣe ìfẹ́ ẹ̀ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, òfin rẹ̀ ń bẹ ní àyà mi.”

  4. Lóòtítọ́ ó ti ru àìlera wa lọ ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa pẹ̀lú, síbẹ̀ a kà á sí ẹni tí Ọlọ́run lù, tí ó lù, tí a sì pọ́n lójú.

  5. Ṣùgbọ́n a sá a lọ́gbẹ́ nítorí àìṣedéédéé wa a pa á lára nítorí àìṣòdodo wa; ìjìyà tí ó mú àlàáfíà wá fún wa wà lórí i rẹ̀, àti nípa ọgbẹ́ rẹ̀ ni a fi mú wa láradá.

  6. Gbogbo wa bí àgùntàn, ti ṣìnà lọ, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti yà sí ọ̀nà ara rẹ̀; Olúwa sì ti gbé e ka orí ara rẹ̀ gbogbo àìṣedéédéé wa.

  7. A jẹ ẹ́ ní yà, a sì pọ́n ọn lójú, síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀; a mú un wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sọ́dọ̀ alápatà, àti gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí ó dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀, síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀.

  8. Pẹ̀lú ìpọ́nlójú àti ìdánilẹ́jọ́ ni a mú un jáde lọ, ta ni ó sì le sọ nípa ìrànlọ́wọ́ rẹ̀? Nítorí a ké e kúrò ní ilẹ̀ àwọn alààyè; nítorí àìṣedéédéé àwọn ènìyàn mi ni a ṣe lù ú.

  9. A fún un ní ibojì pẹ̀lú àwọn ìkà, àti pẹ̀lú àwọn ọlọ́rọ̀ ní ikú rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò hùwà jàgídíjàgan kan, tàbí kí a rí ẹ̀tàn kan ní ẹnu rẹ̀.

  10. Síbẹ̀, ó wu Olúwa láti pa á lára àti láti mú kí ó jìyà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fi ayé rẹ̀ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, Òun yóò rí àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ àti ọjọ́ ayé rẹ̀ yóò pẹ́ títí, àti ète Olúwa ni yóò gbèrú ní ọwọ́ rẹ̀.

  11. Lẹ́yìn ìpọ́njú ẹ̀mí rẹ̀, òun yóò rí ìmọ́lẹ̀, ààyè yóò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn; nípa ìmọ̀ rẹ̀ ìránṣẹ́ mi olódodo yóò dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ láre, Òun ni yóò sì ru àìṣedéédéé wọn.

  12. Nítorí náà èmi yóò fún un ní ìpín pẹ̀lú àwọn ẹni ńlá òun yóò sì pín ìkógun pẹ̀lú àwọn alágbára, nítorí pé òun jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ fún ikú, tí a sì kà á mọ́ àwọn alárékọjá. Nítorí ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀, ó sì ṣe ìlàjà fún àwọn alárékọjá.

  13. “Àádọ́rin ọ̀sẹ̀ ni a pàṣẹ fún àwọn ènìyàn rẹ àti fún àwọn ìlú mímọ́ rẹ láti parí ìrékọjá, láti fi òpin sí ẹ̀ṣẹ̀, láti ṣe ètùtù sí ìwà búburú, láti mú òdodo títí ayé wá, láti ṣe èdìdì ìran àti wòlíì àti láti fi òróró yan Ibi Mímọ́ Jùlọ.

  14. “Nítorí náà, mọ èyí pé, láti ìgbà tí a ti gbé ọ̀rọ̀ náà jáde wí pé kí a tún Jerusalẹmu ṣe, kí a sì tún kọ́, títí dé ìgbà ọmọ-aládé, ẹni òróró náà, alákòóso wa yóò fi dé, ó jẹ́ ọ̀sẹ̀ méje àti ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta, a ó sì tún ìgboro àti yàrá rẹ̀ mọ, ṣùgbọ́n ní àkókò wàhálà ni.

  15. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta, a ó ké Ẹni òróró náà kúrò, kò sì ní ní ohun kan. Àwọn ènìyàn ọmọ-aládé náà tí yóò wá ni yóò pa ìlú náà àti ibi mímọ́ run. Òpin yóò dé bí ìkún omi, ogun yóò máa jà títí dé òpin, a sì ti pàṣẹ ìdahoro.

  16. Yóò sì fi ìdí i májẹ̀mú kan múlẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún ọ̀sẹ̀ kan. Ní àárín ọ̀sẹ̀ ni yóò mú òpin bá ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ. Àti lórí apá kan ni yóò dà ìríra tí ó mú ìdahoro wá, títí tí òpin tí a ti pàṣẹ lórí asọnidahoro yóò fi padà fi dé bá a.”

  17. Ó sì wí fún wọn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni a ti kọ̀wé rẹ̀, pé: kí Kristi jìyà, àti kí ó sì jíǹde ní ọjọ́ kẹta kúrò nínú òkú,

  18. àti pé kí a wàásù ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lórúkọ rẹ̀, ní orílẹ̀-èdè gbogbo, bẹ̀rẹ̀ láti Jerusalẹmu lọ.

  19. Ṣùgbọ́n Kaiafa, ọ̀kan nínú wọn, ẹni tí í ṣe olórí àlùfáà ní ọdún náà, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin kò mọ ohunkóhun rárá!

  20. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì ronú pé, ó ṣàǹfààní fún wa, kí ènìyàn kan kú fún àwọn ènìyàn kí gbogbo orílẹ̀-èdè má ba à ṣègbé.”

  21. Kì í ṣe fún ara rẹ̀ ni ó sọ èyí ṣùgbọ́n bí ó ti jẹ́ olórí àlùfáà ní ọdún náà, ó sọtẹ́lẹ̀ pé, Jesu yóò kú fún orílẹ̀-èdè náà,

  22. Àti Paulu, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó wọlé tọ̀ wọ́n lọ, ni ọjọ́ ìsinmi mẹ́ta ó sì ń bá wọn fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ nínú ìwé mímọ́.

  23. Ó ń túmọ̀, ó sì ń fihàn pé, Kristi kò lè ṣàìmá jìyà, kí o sì jíǹde kúrò nínú òkú; àti pé, “Jesu yìí ẹni tí èmi ń wàásù fún yin, òun ni Kristi náà.”

  24. àwọn ẹni tí a ń dá láre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, nípa ìdáǹdè tí ó wà nínú Kristi Jesu.

  25. Ẹni tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ láti jẹ́ ètùtù nípa ìgbàgbọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, láti fi òdodo rẹ̀ hàn nítorí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti kọjá, nínú ìpamọ́ra Ọlọ́run,