Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Amariah

15 ẹsẹ · 7 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Meraioti baba Amariah, Amariah baba Ahitubu

  2. Asariah baba Amariah Amariah baba Ahitubu

  3. Meraioti ọmọ rẹ̀, Amariah ọmọ rẹ̀, Ahitubu ọmọ rẹ̀,

  4. Àwọn ọmọ Hebroni: Jeriah sì ni ẹni àkọ́kọ́, Amariah sì ni ẹni ẹ̀ẹ̀kejì, Jahasieli sì ni ẹ̀ẹ̀kẹ́ta àti Jekameamu ẹ̀ẹ̀kẹrin.

  5. Àwọn ọmọ Hebroni: Jeriah alákọ́kọ́, Amariah ẹlẹ́ẹ̀kejì, Jahasieli ẹlẹ́ẹ̀kẹta àti Jekameamu ẹlẹ́ẹ̀kẹrin.

  6. “Amariah àlùfáà ni yóò jẹ́ olórí yín nínú gbogbo ọ̀ràn tí ó jẹ́ ti Olúwa, àti Sebadiah ọmọ Iṣmaeli alákòóso ìdílé Juda, ní yóò jẹ́ olórí ní gbogbo ọ̀rọ̀ tí ọba, àti àwọn ará Lefi pẹ̀lú yin yóò sìn gẹ́gẹ́ bí ìjòyè níwájú yín. Ẹ ṣe é pẹ̀lú ìmọ́kànle, Olúwa yóò sì wà pẹ̀lú àwọn tó bá ń ṣe rere.”

  7. Edeni, Miniamini, Jeṣua, Ṣemaiah, Amariah àti Ṣekaniah ràn án lọ́wọ́ tọkàntọkàn nínú àwọn ìlú àwọn àlùfáà tí ń dáwó fún àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, àgbà àti kékeré.

  8. Ní àfikún, wọ́n pín sí àwọn ọkùnrin àgbà ọdún mẹ́ta tàbí ọ̀pọ̀ tí orúkọ wọn wà nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn. Gbogbo àwọn ti yóò wọ ilé Olúwa láti ṣe oríṣìí iṣẹ́ ti a gbà wọ́n fún gẹ́gẹ́ bí ìgbẹ́kẹ̀lé wọn àti ìpín wọn.

  9. Wọ́n sì pín àwọn àlùfáà, wọn kọ orúkọ àwọn ìdílé wọn sínú ìtàn ìdílé àti sí àwọn ará Lefi ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu àti ìpín wọn.

  10. Wọ́n fi gbogbo àwọn ọmọ kéékèèké sí i, àwọn ìyàwó, àti àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin gbogbo ará ìlú tí a kọ lẹ́sẹẹsẹ sínú ìtàn ìdílé ti baba ńlá wọn fún ìrántí. Nítorí tí wọ́n ṣe òtítọ́ ní yíya ara wọn sí ọ̀tọ̀.

  11. Ní ti àwọn àlùfáà, àwọn ìran ọmọ Aaroni, tí ń gbé ni àwọn ilẹ̀ oko lẹ́bàá àwọn ìlú wọn tàbí ní àwọn ìlú mìíràn. A yan àwọn ọkùnrin pẹ̀lú orúkọ láti pín ìlú fún gbogbo ọkùnrin láàrín wọn àti sí gbogbo àwọn tí a kọ sínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá àwọn ará Lefi.

  12. ọmọ Amariah, ọmọ Asariah, ọmọ Meraioti,

  13. Ṣallumu, Amariah àti Josẹfu.

  14. Nígbà tí àwọn ènìyàn tókù nínú àwọn Juda àti Benjamini ń gbé ní Jerusalẹmu). Nínú àwọn ọmọ Juda: Ataiah ọmọ Ussiah ọmọ Sekariah, ọmọ Amariah, ọmọ Ṣefatia, ọmọ Mahalaleli, ìran Peresi;

  15. Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Sefaniah ọmọ Kuṣi, ọmọ Gedaliah, ọmọ Amariah, ọmọ Hesekiah, ní ìgbà Josiah ọmọ Amoni ọba Juda.