Fò sí àkóónú

circa 1446 BC

Moses & The Exodus

God raises up Moses to confront Pharaoh; the ten plagues culminate in Israel's dramatic deliverance from four centuries of bondage.

415 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Eksodu 6:28nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Olúwa bá Mose sọ̀rọ̀ ni Ejibiti,

  2. Eksodu 6:29nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Èmi ni Olúwa. Sọ ohun gbogbo ti mo ti sọ fún ọ fún Farao ọba Ejibiti.”

  3. Eksodu 6:30nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n Mose sì wí ní iwájú Olúwa pé, “Níwọ́n ìgbà ti mo jẹ́ akólòlò, ọ̀nà dà ti Farao yóò ṣe fi etí sí mi?”

  4. Eksodu 7:1nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Wò ó, Èmi ti ṣe ọ bí Ọlọ́run fún Farao, Aaroni arákùnrin rẹ ni yóò jẹ́ agbẹnusọ rẹ.

  5. Eksodu 7:2nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ìwọ yóò sì sọ ohun gbogbo tí Èmi ti pàṣẹ fún ọ, Aaroni arákùnrin rẹ yóò sísọ fún Farao kí ó jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ rẹ̀.

  6. Eksodu 7:3nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n èmi yóò sé Farao lọ́kàn le. Bí Mo tilẹ̀ ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì àti ìyanu ni Ejibiti,

  7. Eksodu 7:4nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    síbẹ̀ òun kì yóò fi etí sí ọ. Nígbà náà ni Èmi yóò gbé ọwọ́ mi lé Ejibiti, pẹ̀lú agbára ìdájọ́ ńlá mi ni èmi yóò mú àwọn ènìyàn mi Israẹli jáde ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́.

  8. Eksodu 7:5nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Àwọn ará Ejibiti yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa ní ìgbà tí mo bá na ọwọ́ mi jáde lé Ejibiti, tí mo sì mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò níbẹ̀.”

  9. Eksodu 7:6nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Mose àti Aaroni sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn.

  10. Eksodu 7:7nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Mose jẹ́ ọmọ ọgọ́rin ọdún Aaroni sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin ni ìgbà tí wọ́n bá Farao sọ̀rọ̀.

  11. Eksodu 7:8nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni,

  12. Eksodu 7:9nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    “Ní ìgbà tí Farao bá sọ fún un yín pé, ‘Ẹ ṣe iṣẹ́ ìyanu kan,’ sọ fún Aaroni ní ìgbà náà pé, ‘Mú ọ̀pá rẹ kí ó sì sọ ọ́ sílẹ̀ níwájú Farao,’ yóò sì di ejò.”

  13. Eksodu 7:10nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Mose àti Aaroni tọ Farao lọ, wọ́n sì ṣe bí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn, Aaroni ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀ ní iwájú Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀, ọ̀pá náà sì di ejò.

  14. Eksodu 7:11nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Farao sì pe àwọn amòye, àwọn oṣó àti àwọn onídán ilẹ̀ Ejibiti jọ, wọ́n sì fi idán wọn ṣe ohun tí Mose àti Aaroni ṣe.

  15. Eksodu 7:12nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn sọ ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀, ọ̀pá náà sì di ejò. Ṣùgbọ́n ọ̀pá Aaroni gbé ọ̀pá tiwọn mì.

  16. Eksodu 7:13nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Síbẹ̀ ọkàn Farao sì yigbì, kò si fetí sí wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ.

  17. Eksodu 7:14nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Ọkàn Farao ti di líle, ó kọ̀ láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn náà ó lọ.

  18. Eksodu 7:15nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Tọ Farao lọ ni òwúrọ̀ kùtùkùtù bí ó ti ń lọ sí etí odò, dúró ni etí bèbè odò Naili láti pàdé rẹ, mú ọ̀pá rẹ tí ó di ejò ni ọwọ́ rẹ.

  19. Eksodu 7:16nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Sọ fún un pé, ‘Olúwa Ọlọ́run àwọn Heberu rán mi sí ọ láti sọ fún ọ pé, Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó lè sìn mi ni aginjù. Ṣùgbọ́n títí di àkókò yìí, ìwọ kò gba.

  20. Eksodu 7:17nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Èyí ni Olúwa wí, nípa èyí ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa. Wò ó, èmi yóò fi ọ̀pá ti ó wà ní ọwọ́ mi, èmi yóò ná omi tí ó wà nínú odò Naili yóò sì di ẹ̀jẹ̀.

  21. Eksodu 7:18nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Àwọn ẹja tí ó wà nínú odò Naili yóò kú, odò náà yóò sì máa rùn, àwọn ará Ejibiti kò sì ni lè mu omi rẹ̀.’ ”

  22. Eksodu 7:19nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Olúwa sọ fún Mose, “Sọ fún Aaroni, ‘Mú ọ̀pá rẹ kí ó sì na ọwọ́ rẹ jáde lórí àwọn omi Ejibiti. Lórí àwọn odò kéékèèké àti odò ńlá, lórí àbàtà àti adágún omi, wọn yóò sì di ẹ̀jẹ̀.’ Ẹ̀jẹ̀ yóò wà ni ibi gbogbo ni Ejibiti, àní nínú ọpọ́n àti nínú kete omi àti nínú ìkòkò tí a pọn omi sí nínú ilé.”

  23. Eksodu 7:20nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Mose àti Aaroni sí ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn. Ó gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè ni iwájú Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀, ó sì lu omi odò Naili, omi odò náà sì yípadà sí ẹ̀jẹ̀.

  24. Eksodu 7:21nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ẹja inú odò Naili sì kú, odò náà ń rùn gidigidi tí ó fi jẹ́ pé àwọn ará Ejibiti kò le è mu omi inú rẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ sì wà ni ibi gbogbo ni ilẹ̀ Ejibiti.

  25. Eksodu 7:22nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n àwọn apidán ilẹ̀ Ejibiti sì ṣe bákan náà pẹ̀lú agbára òkùnkùn wọn, ọkàn Farao sì yigbì síbẹ̀ kò sì fetí sí wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ.