Fò sí àkóónú

Egypt

561 verses · 4 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Egyptian, Egyptians, Egyptian's

30.1000, 31.3300 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Egypt

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nípa Ejibiti. Èyí ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ-ogun Farao Neko ọba Ejibiti ẹni tí a borí rẹ̀ ní Karkemiṣi, ní odò Eufurate láti ọwọ́ Nebukadnessari ọba Babeli ní ọdún kẹrin Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda:

  2. Ejibiti dìde bí odò náà, bí omi odò tí ń ru. Ó sì wí pé, ‘Èmi yóò dìde, n ó sì bo gbogbo ilẹ̀ ayé.’ Èmi yóò pa ìlú àti àwọn ènìyàn rẹ̀ run.

  3. “Gòkè lọ sí Gileadi, kí o sì mú ìkunra, ìwọ wúńdíá ọmọbìnrin Ejibiti. Ṣùgbọ́n ní asán ni ìwọ ń lo oògùn, kì yóò sí ìwòsàn fún ọ.

  4. Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó bá Jeremiah wòlíì nì sọ nípa wíwá Nebukadnessari ọba Babeli láti lọ dojú ìjà kọ Ejibiti:

  5. “Kéde èyí ní Ejibiti, sì sọ ọ́ ní Migdoli, sọ ọ́ ní Memfisi àti Tafanesi: ‘Dúró sí ààyè rẹ kí o sì múra sílẹ̀, nítorí pé idà náà ń pa àwọn tí ó yí ọ ká.’

  6. Níbẹ̀ ni wọn ó kígbe pé, ‘Ariwo lásán ni Farao ọba Ejibiti pa, ó ti sọ àǹfààní rẹ̀ nù.’

  7. Ìwọ, ọmọbìnrin ti ń gbé Ejibiti pèsè ohun èlò ìrìnàjò fún ara rẹ nítorí Memfisi yóò di ahoro a ó sì fi jóná, láìní olùgbé.

  8. “Ẹgbọrọ abo màlúù tó lẹ́wà ní Ejibiti ṣùgbọ́n eṣinṣin ìparun dé, ó dé láti àríwá.

  9. A ó dójútì ọmọbìnrin Ejibiti, a ó fà á lé ọwọ́ àwọn ènìyàn àríwá.”

  10. Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí pé: “Èmi yóò rọ̀jò ìyà mi sórí Amoni òrìṣà Tebesi, sórí Farao, sórí Ejibiti àti àwọn òrìṣà rẹ̀ àti sórí àwọn ọba rẹ̀ àti sórí àwọn tó gbẹ́kẹ̀lé Farao.

  11. Àwa jọ̀wọ́ ara wa fún Ejibiti àti Asiria láti rí oúnjẹ tó tó jẹ.

  12. Ṣùgbọ́n ọba ṣọ̀tẹ̀ sí i nípa ríran àwọn ikọ̀ rẹ̀ lọ sí Ejibiti, kí wọn bá à lè fún un ni ẹṣin àti àwọn ọmọ-ogun púpọ̀. Yóò ha ṣe àṣeyọrí? Ṣe ẹni tó ṣe irú nǹkan yìí yóò sì bọ́ níbẹ̀? Yóò ha dalẹ̀ tán kí ó sì bọ́ níbẹ̀ bí?

  13. Àwọn orílẹ̀-èdè gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì fi ẹ̀wọ̀n mú un nínú iho wọn. Wọn fi ẹ̀wọ̀n mu nu lọ sí ilẹ̀ Ejibiti.

  14. kí ó sì sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí, ní ọjọ́ tí mo yàn Israẹli, mo gbé ọwọ́ mi sókè nínú ìbúra sí àwọn ọmọ ilé Jakọbu, mo sì fi ara mi hàn wọn ní Ejibiti, mo gbé ọwọ́ mi sókè nínú ẹ̀jẹ́ wí pé, “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.”

  15. Ní ọjọ́ náà mo lọ búra fún wọn pé, èmi yóò mú wọn jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti lọ sí ilẹ̀ ti mo ti wá sílẹ̀ fún wọn, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, ilẹ̀ tí ó lẹ́wà jùlọ láàrín àwọn ilẹ̀ yòókù.

  16. Mo sì wí fún wọn pé, “Kí olúkúlùkù nínú yín gbé ìríra ojú rẹ̀ kúrò, kí ẹ sì má bá sọ ara yín di àìmọ́ pẹ̀lú àwọn òrìṣà Ejibiti, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.”

  17. “ ‘Ṣùgbọ́n wọn ṣọ̀tẹ̀ sí mi wọn kò sì gbọ́rọ̀, wọn kò gbé àwòrán ìríra tí wọ́n dojúkọ kúrò níwájú wọn bẹ́ẹ̀ ni wọn kò si kọ̀ àwọn òrìṣà Ejibiti sílẹ̀, torí náà mo sọ pé èmi yóò tú ìbínú gbígbóná mi lé wọn lórí, èmi yóò sì jẹ́ kí ìbínú mi sẹ̀ lórí wọn ní ilẹ̀ Ejibiti.

  18. Ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mi, mo ṣe ohun tí kò ní jẹ́ kí orúkọ mi bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ń gbé láàrín wọn, lójú àwọn ẹni tí mo ti fi ara hàn fún ara Israẹli nípa mímú wọn jáde ní ilẹ̀ Ejibiti.

  19. Nítorí náà, mo mú wọn jáde ní ilẹ̀ Ejibiti mo sì mú wọn wá sínú aginjù.

  20. Bí mo ṣe ṣe ìdájọ́ àwọn baba yín nínú aginjù nílẹ̀ Ejibiti, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe ìdájọ́ yín ní Olúwa Olódùmarè wí.

  21. Wọn ń ṣe panṣágà ní Ejibiti, wọn ń ṣe panṣágà láti ìgbà èwe wọn. Ní ilẹ̀ yẹn ni wọn ti fi ọwọ́ pa ọyàn wọn, níbẹ̀ ni wọn sì fọwọ́ pa igbá àyà èwe wọn.

  22. kò fi ìwà panṣágà tí ó ti bẹ̀rẹ̀, ni Ejibiti sílẹ̀, ní ìgbà èwe rẹ̀ àwọn ọkùnrin n bá a sùn, wọn fi ọwọ́ pa àyà èwe rẹ̀ lára wọn sì ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí i.

  23. Síbẹ̀síbẹ̀ ó ń pọ̀ sí i nínú ìdàpọ̀ rẹ̀ bí ó ti ń rántí ìgbà èwe rẹ̀ tí ó jẹ́ panṣágà ní Ejibiti.

  24. Èmi yóò sì fi òpin sí ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti iṣẹ́ panṣágà tí ẹ bẹ̀rẹ̀ ni Ejibiti. Ẹ̀yin kò ní wo àwọn nǹkan wọ̀nyí pẹ̀lú ìpòùngbẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní rántí Ejibiti mọ.

  25. Ọ̀gbọ̀ dáradára aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́ láti Ejibiti wá ni èyí tí ìwọ ta láti fi ṣe àsíá ọkọ̀ rẹ; aṣọ aláró àti elése àlùkò láti erékùṣù ti Eliṣa ni èyí tí a fi bò ó.