- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Joash
A tún mọ̀ ọ́n sí: Jehoash
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Joash
Ṣùgbọ́n Jehoṣeba ọmọbìnrin ọba Jehoramu àti arábìnrin Ahasiah, mú Joaṣi ọmọ Ahasiah, ó sì jí i lọ kúrò láàrín àwọn ọmọ-aládébìnrin ti ọba náà, tí ó kù díẹ̀ kí a pa. Ó gbé òhun àti olùtọ́jú rẹ̀ sínú ìyẹ̀wù láti fi pamọ́ kúrò fún Ataliah; bẹ́ẹ̀ ni a kò pa á.
Joaṣi jẹ́ ọmọ ọdún méje nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ ìjọba rẹ̀.
Ní ọdún keje tí Jehu, Jehoaṣi di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ogójì ọdún. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Sibia: Ó wá láti Beerṣeba.
Jehoaṣi ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa ní gbogbo ọdún tí Jehoiada àlùfáà fi àṣẹ fún un.
Jehoaṣi sọ fún àwọn àlùfáà pé, “Gba gbogbo owó tí wọ́n mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ mímọ́ sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa owó tí a gbà ní ìgbà kíka àwọn ènìyàn ìlú, owó tí a gbà láti ọwọ́ olúkúlùkù bí wọ́n ti ṣe jẹ́ ẹ̀yà àti owó tí ó ti ọkàn olúkúlùkù wá tí a mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa.
Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹtàlélógún ọba Jehoaṣi, àwọn àlùfáà kò ì tí ì tún ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe.
Nígbà náà, ọba Jehoaṣi pe Jehoiada àlùfáà àti àwọn àlùfáà yòókù, ó sì bi wọ́n pé, “Kí ni ó dé tí ẹ̀yin kò fi tún ìbàjẹ́ tí a ṣe sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe? Ẹ má ṣe gba owó mọ́ lọ́wọ́ àwọn afowópamọ́, ṣùgbọ́n ẹ gbé e kalẹ̀ fún títún ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe.”
Ṣùgbọ́n Jehoaṣi ọba Juda mú gbogbo ohun mímọ́ tí a gbé ka iwájú tí a yà sọ́tọ̀ nípasẹ̀ baba rẹ̀ Jehoṣafati, Jehoramu àti Ahasiah, àwọn ọba Juda, àti àwọn ẹ̀bùn tí òun tìkára rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀ àti gbogbo wúrà, tí ó rí nínú ibi ìfowópamọ́ sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa àti ní ti ààfin ọba, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí Hasaeli; ọba Siria, tí ó sì fà padà kúrò ní Jerusalẹmu.
Pẹ̀lú ìyókù ìṣe Joaṣi, àti ohun gbogbo tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Juda?
Àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ dìtẹ̀ sí i wọ́n sì lù ú pa ní Beti-Milo ní ọ̀nà sí Silla.
Ní ọdún kẹtàlélógún ti Joaṣi ọmọ ọba Ahasiah ti Juda, Jehoahasi ọmọ Jehu di ọba Israẹli ní Samaria. Ó sì jẹ ọba fún ọdún mẹ́tàdínlógún.
Ó ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa, ṣùgbọ́n kì í ṣe bí i Dafidi baba a rẹ̀ tí ṣe. Nínú ohun gbogbo, ó tẹ̀lé àpẹẹrẹ baba a rẹ̀ Joaṣi.
Jehoramu ọmọ rẹ̀, Ahasiah ọmọ rẹ̀, Joaṣi ọmọ rẹ̀,
Ṣùgbọ́n Jehoṣeba ọmọbìnrin ọba Jehoramu mú Joaṣi, ọmọkùnrin Ahasiah ó sì jí gbé lọ kúrò láàrín àwọn ọmọbìnrin ọba, àwọn tí ó kù díẹ̀ kí wọn pa. Wọn gbé òun àti olùtọ́jú rẹ̀ sínú ìyẹ̀wù. Nítorí Jehoṣeba ọmọbìnrin ọba Jehoramu àti ìyàwó àlùfáà Jehoiada jẹ́ arábìnrin Ahasiah. Ó fi ọmọ náà pamọ́ kúrò fún Ataliah, kí ó má ba à pa á.
Joaṣi jẹ́ ọmọ ọdún méje nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ogójì ọdún. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Sibia ti Beerṣeba.
Joaṣi ṣe ohun tí ó dára ní ojú Olúwa ní gbogbo àkókò Jehoiada àlùfáà.
Ní àkókò kan, Joaṣi pinnu láti tún ilé Olúwa ṣe.
Ọba Joaṣi kò rántí inú rere tí Jehoiada baba Sakariah ti fihàn án ṣùgbọ́n, ó pa ọmọ rẹ̀, tí ó wí bí ó ti ń kú lọ pé, “Kí Olúwa kí ó rí èyí kí ó sì pè ọ́ sí ìṣirò.”
Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọmọ-ogun Aramu ti wá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin díẹ̀ Olúwa sì fi ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ogun lé wọn lọ́wọ́, nítorí tí Juda ti kọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ṣe ìdájọ́ Joaṣi.