Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Fatherless

26 ẹsẹ · 31 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ọmọbìnrin Selofehadi ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri ọmọ Manase tó jẹ́ ìdílé Manase, ọmọ Josẹfu wá. Orúkọ àwọn ọmọbìnrin náà ni Mahila, Noa, Hogla, Milka àti Tirsa.

  2. Wọ́n súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé wọ́n sì dúró níwájú Mose, àti Eleasari àlùfáà, àti níwájú àwọn olórí àti ìjọ, wọ́n sì wí pé,

  3. “Baba wa kú sí aginjù. Kò sí lára àwọn ẹgbẹ́ Kora tí wọ́n kó ara wọn pọ̀ lòdì sí Olúwa, ṣùgbọ́n ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kò sì fi ọmọkùnrin sílẹ̀.

  4. Kín ni ó dé tí orúkọ baba wa yóò parẹ́ nínú ìdílé rẹ̀ nítorí pé kò ní ọmọkùnrin? Fún wa ní ilẹ̀ ìní láàrín àwọn arákùnrin baba wa.”

  5. Nígbà náà Mose mú ọ̀rọ̀ wọn wá síwájú Olúwa.

  6. “Báyìí tí ó bá jẹ́ pé ẹ̀yin ṣe ohun tí ó ní ọlá àti pẹ̀lú ẹ̀mí òtítọ́ ní fífi Abimeleki jẹ ọba, tí ó bá ṣe pé ohun tí ó tọ́ ni ẹ ṣe sí Jerubbaali àti ìdílé rẹ̀, bí ẹ bá san ẹ̀san tó yẹ fún un.

  7. Nítorí pé baba mi jà nítorí yín, ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu láti gbà yín sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Midiani;

  8. ṣùgbọ́n lónìí ẹ̀yin ṣọ̀tẹ̀ sí ilé baba mi, ní orí òkúta kan ṣoṣo ni ẹ ti pa àwọn àádọ́rin ọmọ rẹ̀, ẹ̀yin sì ti fi Abimeleki ọmọ ẹrúbìnrin rẹ̀ jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn Ṣekemu nítorí tí ó jẹ́ arákùnrin yín.

  9. Bí ohun tí ẹ ṣe sí Jerubbaali àti ìdílé rẹ̀ bá jẹ́ ohun tí ó yẹ, tí ẹ sì ṣe òtítọ́ inú sí i, kí ẹ ní ayọ̀ nínú Abimeleki kí òun náà sì ní ayọ̀ nínú yín.

  10. Ṣùgbọ́n tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí iná jó jáde wá láti ọ̀dọ̀ Abimeleki kí ó sì jó yín run. Ẹ̀yin ará Ṣekemu àti ará Beti-Milo, kí iná pẹ̀lú jáde láti ọ̀dọ̀ yín wá ẹ̀yin ará Ṣekemu àti ará Beti-Milo kí ó sì jó Abimeleki run.”

  11. Lẹ́yìn tí Jotamu ti sọ èyí tan, ó sá àsálà lọ sí Beeri, ó sì gbé níbẹ̀ nítorí ó bẹ̀rù arákùnrin rẹ̀ Abimeleki.

  12. Nígbà tí Ataliah ìyá Ahasiah rí i wí pé ọmọ rẹ̀ ti kú, ó tẹ̀síwájú láti pa gbogbo ìdílé ọba náà run.

  13. Ṣùgbọ́n Jehoṣeba ọmọbìnrin ọba Jehoramu àti arábìnrin Ahasiah, mú Joaṣi ọmọ Ahasiah, ó sì jí i lọ kúrò láàrín àwọn ọmọ-aládébìnrin ti ọba náà, tí ó kù díẹ̀ kí a pa. Ó gbé òhun àti olùtọ́jú rẹ̀ sínú ìyẹ̀wù láti fi pamọ́ kúrò fún Ataliah; bẹ́ẹ̀ ni a kò pa á.

  14. Ó wà ní ìpamọ́ pẹ̀lú olùtọ́jú ní ilé tí a kọ́ fún Olúwa fún ọdún mẹ́fà nígbà tí Ataliah fi jẹ ọba lórí ilẹ̀ náà.

  15. Ní ọdún keje, Jehoiada ránṣẹ́ ó sí mú àwọn olórí lórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, pẹ̀lú àwọn balógun àti àwọn olùṣọ́, ó sì mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Ó ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú wọn, ó sì fi wọ́n sí abẹ́ ìbúra nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Níbẹ̀ ni ó fi ọmọkùnrin ọba hàn wọ́n.

  16. Ó pàṣẹ fún wọn, wí pé, “Ìwọ tí ó wà nínú àwọn ẹgbẹ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ó ń lọ fún iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi—ìdámẹ́ta yín fún ṣíṣọ́ ààfin ọba.

  17. Ìdámẹ́ta ní ẹnu ìlẹ̀kùn huri, àti ìdámẹ́ta ní ẹnu ìlẹ̀kùn ní ẹ̀yìn olùṣọ́, tí ó yípadà ní ṣíṣọ́ ilé tí a kọ́,

  18. àti ẹ̀yin tí ó wà ní ẹgbẹ́ kejì yòókù tí kì í lọ ibi iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi gbogbo ni kí ó ṣọ́ ilé tí a kọ́ fún Olúwa fún ọba.

  19. Ẹ mú ibùjókòó yín yí ọba ká, olúkúlùkù ọkùnrin pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ọgbà yìí gbọdọ̀ kú. Ẹ dúró súnmọ́ ọba ní ibikíbi tí ó bá lọ.”

  20. Olórí àwọn ọ̀rọ̀ọ̀rún ṣe gẹ́gẹ́ bí Jehoiada àlùfáà ti pa á láṣẹ. Olúkúlùkù mú àwọn ọkùnrin rẹ̀ àwọn tí ó ń lọ sí iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi àti àwọn tí wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Jehoiada àlùfáà.

  21. Nígbà náà, ó fún àwọn olórí ní àwọn ọ̀kọ̀ àti àwọn àpáta tí ó ti jẹ́ ti ọba Dafidi tí ó sì wà nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa.

  22. Àwọn olùṣọ́, olúkúlùkù pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀, wọ́n sì dúró ṣinṣin yìí ọba ká—lẹ́bàá pẹpẹ àti ilé ìhà gúúsù sí ìhà àríwá ilé tí a kọ́ fun Olúwa náà.

  23. Jehoiada mú ọmọkùnrin ọba jáde, ó sì gbé adé náà lé e: ó fún un ní ẹ̀dà májẹ̀mú, wọ́n sì kéde ọba rẹ̀. Wọ́n fi àmì òróró yàn án, àwọn ènìyàn pa àtẹ́wọ́, wọ́n sì kígbe, “Kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn.”

  24. Ègbé ni fún àwọn ti ń ṣe òfin àìṣòdodo,

  25. láti dún àwọn aláìní ní ẹ̀tọ́ wọn àti láti fa ọwọ́ ìdájọ́ sẹ́yìn kúrò níwájú àwọn olùpọ́njú ènìyàn mi, wọ́n sọ àwọn ọ̀pọ̀ di ìjẹ fún wọn, wọ́n sì ń ja àwọn aláìní baba lólè.