Fò sí àkóónú

Jesus

3,872 ẹsẹ · 6 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jesus Christ, Immanuel, Emmanuel, Christ

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jesus

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ṣẹ́ Ẹni Mímọ́ àti Olóòótọ́ náà, ẹ̀yin sì béèrè kí a fi apànìyàn fún un yín.

  2. Nípa ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Jesu, òun ni ó mú ọkùnrin yìí láradá, ẹni tí ẹ̀yin rí, tí ẹ sì mọ̀. Orúkọ Jesu àti ìgbàgbọ́ tí ó wá nípa rẹ̀ ni ó fún un ní ìlera pípé ṣáṣá yìí ni ojú gbogbo yín.

  3. Ṣùgbọ́n báyìí ni Ọlọ́run ti ṣe ìmúṣẹ àwọn ohun tí ó ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu gbogbo àwọn wòlíì pé, Kristi rẹ̀ yóò jìyà.

  4. Nítorí náà ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì yípadà sí Ọlọ́run, kí a lè pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, kí àkókò ìtura bá a lè ti ọ̀dọ̀ Olúwa wá,

  5. àti kí ó ba à lè rán Kristi tí a ti yàn fún yín tẹlẹ̀: àní Jesu.

  6. Mose wí pé, ‘Olúwa Ọlọ́run yín yóò gbé wòlíì kan dìde fún yín nínú àwọn arákùnrin yín, bí èmi; òun ni ẹ̀yin yóò máa gbọ́ tirẹ̀ ní ohun gbogbo tí yóò máa sọ fún un yín.

  7. Yóò sì ṣe, olúkúlùkù ọkàn ti kò bá gbọ́ ti wòlíì náà, òun ni a ó parun pátápátá kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.’

  8. Nígbà ti Ọlọ́run jí Jesu Ọmọ rẹ̀ dìde, ó kọ́ rán an sí i yín láti bùkún fún un yín, nípa yíyí olúkúlùkù yín padà kúrò nínú ìwà búburú rẹ̀.”

  9. Inú bí wọn, nítorí tí wọn kọ́ àwọn ènìyàn, wọ́n sì ń wàásù àjíǹde kúrò nínú òkú nínú Jesu.

  10. kí èyí yé gbogbo yín àti gbogbo ènìyàn Israẹli pé, ni orúkọ Jesu Kristi ti Nasareti, tí ẹ̀yin kàn mọ́ àgbélébùú, tí Ọlọ́run jí dìde kúrò nínú òkú, nípa rẹ̀ ni ọkùnrin yìí fi dúró níwájú yín ni ara dídá-ṣáṣá.

  11. Nígbà tí wọ́n sì kíyèsi ìgboyà Peteru àti Johanu, tí wọ́n mọ̀ pé, aláìkẹ́kọ̀ọ́ àti òpè ènìyàn ni wọn, ẹnu yà wọ́n, wọ́n sì wòye pé, wọ́n ti ń bá Jesu gbé.

  12. Wọ́n sì pè wọ́n, wọ́n pàṣẹ fún wọn, kí wọn má ṣe sọ̀rọ̀ tàbí kọ́ni rárá mọ́ ní orúkọ Jesu.

  13. Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n fi ọkàn kan gbé ohùn wọn sókè sí Ọlọ́run, wọ́n sì wí pé, “Olúwa Olódùmarè, ìwọ tí ó dá ọ̀run àti ayé, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn.

  14. Ìwọ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó ti ẹnu Dafidi baba wa ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé: “ ‘E é ṣe tí àwọn kèfèrí fi ń bínú, àti tí àwọn ènìyàn ń gbèrò ohun asán?

  15. Àwọn ọba ayé dìde, àti àwọn ìjòyè kó ara wọn jọ sí Olúwa, àti sí ẹni àmì òróró rẹ̀.’

  16. Àní nítòótọ́ ní Herodu àti Pọntiu Pilatu, pẹ̀lú àwọn aláìkọlà àti àwọn ènìyàn Israẹli kó ara wọn jọ ní ìlú yìí láti dìtẹ̀ sí Jesu Ìránṣẹ́ mímọ́ rẹ, ẹni tí ìwọ ti fi àmì òróró yàn,

  17. láti ṣe ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ àti ìmọ̀ rẹ̀ ti pinnu ṣáájú pé yóò ṣe.

  18. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, Olúwa, kíyèsi ìhàlẹ̀ wọn; kí ó sì fi fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ láti máa fi ìgboyà ńlá sọ ọ̀rọ̀ rẹ.

  19. Kí ìwọ sì fi nína ọwọ́ rẹ ṣe ìmúláradá, àti kí iṣẹ́ ìyanu máa ṣẹ̀ ní orúkọ Jesu ìránṣẹ́ mímọ́ rẹ.”

  20. Agbára ńlá ni àwọn aposteli sì fi ń jẹ́rìí àjíǹde Jesu Olúwa, oore-ọ̀fẹ́ púpọ̀ sì wà lórí gbogbo wọn.

  21. Peteru sí wí fún un pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fohùn ṣọ̀kan láti dán Ẹ̀mí Olúwa wò? Wò ó, ẹsẹ̀ àwọn tí ó sìnkú ọkọ rẹ ń bẹ ní ẹnu-ọ̀nà, wọn ó sì gbe ìwọ náà jáde.”

  22. Ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀, a sì ń yan àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin tí ó gba Olúwa gbọ́ kún iye wọn sí i.

  23. Ṣùgbọ́n ní òru, angẹli Olúwa ṣí ìlẹ̀kùn túbú; ó sì mú wọn jáde.

  24. Ó wí pé, “Àwa kò ha ti kìlọ̀ fún un yín gidigidi pé, kí ẹ má ṣe fi orúkọ yìí kọ́ni, síbẹ̀ ẹ̀yin ti fi ìkọ́ni yín kún Jerusalẹmu, ẹ sì ń pète àti mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí wá sí orí wá.”

  25. Ọlọ́run àwọn baba wa jí Jesu dìde kúrò ní ipò òkú, ẹni tí ẹ̀yin pa nípa gbígbékọ́ sí orí igi.