Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Adé wọ̀nyí yóò sì wà fún Helemu àti fún Tobiah, àti fún Jedaiah, àti fún Heni ọmọ Sefaniah fún ìrántí ni tẹmpili Olúwa.

  2. Àwọn tí ó jìnnà réré yóò wá láti kọ́ tẹmpili Olúwa, ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti rán mi sí yín. Yóò sì rí bẹ́ẹ̀ bí ẹ̀yin yóò bá gbà ohùn Olúwa, Ọlọ́run yín gbọ́ nítòótọ́.”

  3. Ó sì ṣe ní ọdún kẹrin Dariusi ọba, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ́ Sekariah wá ni ọjọ́ kẹrin oṣù Kisleu tí ń ṣe oṣù kẹsànán.

  4. Nígbà tí wọ́n ènìyàn Beteli rán Ṣareseri àti Regemmeleki, àti àwọn ènìyàn wọn sí ilé Ọlọ́run láti wá ojúrere Olúwa.

  5. Àti láti bá àwọn àlùfáà tí ó wà ní ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun, àti àwọn wòlíì sọ̀rọ̀ wí pé, “Ṣé kí èmi ó sọkún ní oṣù karùn-ún kí èmi ya ara mi sọ́tọ̀, bí mo ti ń ṣe láti ọdún mélòó wọ̀nyí wá bí?”

  6. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tọ̀ mí wá pé,

  7. “Sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti fún àwọn àlùfáà pé, ‘Nígbà tí ẹ̀yin gbààwẹ̀, tí ẹ sì ṣọ̀fọ̀ ní oṣù karùn-ún àti keje, àní fun àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, ǹjẹ́ èmi ni ẹ̀yin ha ń gbààwẹ̀ yín fún?

  8. Wọ̀nyí kọ́ ni ọ̀rọ̀ ti Olúwa ti kígbe láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì ìṣáájú wá, nígbà tí a ń gbé Jerusalẹmu, tí ó sì wà ní àlàáfíà, pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀ tí ó yí i káàkiri, nígbà tí a ń gbé gúúsù àti pẹ̀tẹ́lẹ̀.’ ”

  9. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Sekariah wá, wí pé,

  10. “Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ‘Ṣe ìdájọ́ òtítọ́, kí ẹ sì ṣe àánú àti ìyọ́nú olúkúlùkù sí arákùnrin rẹ̀.

  11. Wọ́n sé ọkàn wọn bí òkúta líle, kí wọn má ba à gbọ́ òfin, àti ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti fi ẹ̀mí rẹ̀ rán nípa ọwọ́ àwọn wòlíì ìṣáájú wá. Ìbínú ńlá sì dé láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

  12. “ ‘Ó sì ṣe, gẹ́gẹ́ bí ó ti kígbe, tí wọn kò sì fẹ́ gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kígbe, tí èmi kò sì fẹ́ gbọ́,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  13. ‘Mo sì fi ìjì tú wọn ká sí gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọn kò mọ̀. Ilẹ̀ náà sì dahoro lẹ́yìn wọn, tí ẹnikẹ́ni kò là á kọjá tàbí kí ó padà bọ̀, wọ́n sì sọ ilẹ̀ ààyò náà dahoro.’ ”

  14. Ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun si tún tọ́ mí wá.

  15. Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Owú ńlá ńlá ni mo jẹ fún Sioni, pẹ̀lú ìbínú ńlá ńlá ni mo fi jowú fún un.”

  16. Báyìí ni Olúwa wí, “Mo yípadà sí Sioni èmi ó sì gbé àárín Jerusalẹmu. Nígbà náà ni a ó sì pé Jerusalẹmu ni ìlú ńlá òtítọ́; àti òkè ńlá Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ni a ó pè ní òkè ńlá mímọ́.”

  17. Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Arúgbó ọkùnrin, àti arúgbó obìnrin, yóò gbé ìgboro Jerusalẹmu, àti olúkúlùkù pẹ̀lú ọ̀pá ni ọwọ́ rẹ̀ fún ogbó.

  18. Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Bí ó bá ṣe ìyanu ní ojú ìyókù àwọn ènìyàn yìí ni ọjọ́ wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó ha lè jẹ́ ìyanu ni ojú mi bí?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  19. Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Kíyèsi i, èmi ó gba àwọn ènìyàn mi kúrò ni ilẹ̀ ìlà-oòrùn, àti kúrò ni ilẹ̀ ìwọ̀-oòrùn.

  20. Èmi ó sì mú wọn padà wá, wọn ó sì máa gbé àárín Jerusalẹmu. Wọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi, èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, ní òtítọ́, àti ní òdodo.”

  21. Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Jẹ́ kí ọwọ́ yín le ẹ̀yin ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ọjọ́ wọ̀nyí ni ẹnu àwọn wòlíì tí ó wà ni ọjọ́ tí a fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun lélẹ̀, jẹ́ ki ọwọ́ rẹ̀ le kí a bá lè kọ́ tẹmpili.

  22. Nítorí pé, ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí, owó ọ̀yà ènìyàn kò tó nǹkan, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀yà ẹran pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àlàáfíà fún ẹni ń jáde lọ, tàbí ẹni ti ń wọlé bọ, nítorí ìpọ́njú náà: nítorí mo dojú gbogbo ènìyàn, olúkúlùkù kọ aládùúgbò rẹ̀.

  23. Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí èmi kì yóò ṣè sí ìyókù àwọn ènìyàn yìí gẹ́gẹ́ bí tí ìgbà àtijọ́,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  24. “Nítorí irúgbìn yóò gbilẹ̀, àjàrà yóò ṣo èso rẹ̀, ilẹ̀ yóò sì hu ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan rẹ̀ jáde, àwọn ọ̀run yóò sì mu ìrì wọn wá; èmi ó sì mu kí èyí jẹ ogún ìní àwọn ìyókù ènìyàn yìí ni gbogbo nǹkan wọ̀nyí.

  25. Yóò sì ṣe, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí jẹ́ ègún láàrín àwọn kèfèrí, ẹ̀yin ilé Juda, àti ilé Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó gbà yín sílẹ̀; ẹ̀yin o sì jẹ́ ìbùkún, ẹ má bẹ̀rù, ṣùgbọ́n jẹ́ ki ọwọ́ yín le.”