God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
“Wá! Wá! Sá kúrò ni ilẹ̀ àríwá,” ni Olúwa wí, “nítorí pé bí afẹ́fẹ́ mẹ́rin ọ̀run ni mo tú yín káàkiri,” ni Olúwa wí.
Nítorí báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Lẹ́yìn ògo rẹ̀ ni a ti rán mi sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ń kó yin: nítorí ẹni tí ó tọ́ yin, ó tọ́ ọmọ ojú rẹ̀.
Nítorí kíyèsi i, èmi ó gbọn ọwọ́ mi sí orí wọn, wọn yóò sì jẹ́ ìkógun fún ìránṣẹ́ wọn: ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi.
“Kọrin kí o sì yọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Sioni. Nítorí èmi ń bọ̀ àti pé èmi yóò sì gbé àárín rẹ,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ni yóò dàpọ̀ mọ́ Olúwa ní ọjọ́ náà, wọn yóò sì di ènìyàn mi, èmi yóò sì gbé àárín rẹ, ìwọ yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi sí ọ.
Olúwa yóò sì jogún Juda ìní rẹ̀, ni ilẹ̀ mímọ́, yóò sì tún yan Jerusalẹmu.
Ẹ̀ dákẹ́, gbogbo ẹran-ara níwájú Olúwa: nítorí a jí i láti ibùgbé mímọ́ rẹ̀ wá.”
Ó sì fi Joṣua olórí àlùfáà hàn mí, ó dúró níwájú angẹli Olúwa, Satani sí dúró lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ láti kọjú ìjà sí i.
Olúwa si wí fún Satani pé, “Olúwa bá ọ wí ìwọ Satani; àní Olúwa tí ó ti yan Jerusalẹmu, bá ọ wí, igi iná kọ́ ni èyí tí a mú kúrò nínú iná?”
Mó sì wí pé, “Jẹ kí wọn fi gèlè mímọ́ wé e lórí.” Wọn sì fi gèlè mímọ́ wé e lórí, wọn sì fi aṣọ wọ̀ ọ́. Angẹli Olúwa sì dúró tì í.
Angẹli Olúwa sì tẹnumọ́ ọn fún Joṣua pé:
“Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Bí ìwọ ọ́ bá rìn ní ọ̀nà mi, bí ìwọ yóò bá sì pa àṣẹ mi mọ́, ìwọ yóò sì ṣe ìdájọ́ ilé mi pẹ̀lú, ìwọ yóò sì ṣe àkóso ààfin mi, èmi yóò fún ọ ní ààyè láti rìn láàrín àwọn tí ó dúró yìí.
“ ‘Gbọ́, ìwọ Joṣua olórí àlùfáà, ìwọ, àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ tí ó jókòó níwájú rẹ: nítorí ẹni ìyanu ni wọ́n: nítorí kíyèsi i, èmi yóò mú ẹ̀ka náà wá fun ìránṣẹ́ mi.
Nítorí kíyèsi i, òkúta tí mo tí gbé kalẹ̀ níwájú Joṣua; lórí òkúta kan ni ojú méje wà: kíyèsi i, èmi yóò fín àkọlé rẹ̀,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Èmi yóò sì mú ẹ̀bi ilẹ̀ náà kúrò ní ọjọ́ kan.
“ ‘Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ní ọjọ́ náà ni olúkúlùkù yóò pe ẹnìkejì láti jókòó rẹ̀ sábẹ́ igi àjàrà àti sábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́.’ ”
Ó sì dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Serubbabeli tó wí pé: ‘Kì í ṣe nípa ipá, kì í ṣe nípa agbára, bí kò ṣe nípa Ẹ̀mí mi,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé:
“Ọwọ́ Serubbabeli ni a ti ṣe ìpìlẹ̀ ilé yìí, ọwọ́ rẹ̀ ni yóò sì parí rẹ̀; ìwọ yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi sí i yín.
“Ṣùgbọ́n ta ni ha kẹ́gàn ọjọ́ ohun kékeré? Nítorí wọn ó yọ̀ nígbà ti wọ́n bá rí okùn ìwọ̀n nì lọ́wọ́ Serubbabeli. “(Àwọn méje wọ̀nyí ni àwọn ojú Olúwa, tí ó ń sáré síyìn-ín sọ́hùn-ún ní gbogbo ayé.)”
Ó sì wí pé, “Àwọn méjì wọ̀nyí ni àwọn tí a fi òróró yàn, tí ó dúró ti Olúwa gbogbo ayé.”
Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ‘Èmi yóò mú un jáde, Èmi yóò si wọ inú ilé olè lọ, àti inú ilé ẹni ti o bá fi orúkọ mi búra èké, yóò si wà ni àárín ilé rẹ̀, yóò si rún pẹ̀lú igi àti òkúta inú rẹ̀.’ ”
Angẹli náà si dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀mí mẹ́rin ti ọ̀run, tí wọn ń lọ kúrò lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ara wọn hàn níwájú Olúwa gbogbo ayé.
Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé:
Sì sọ fún un pé, ‘Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ wí pé, wo ọkùnrin náà ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹ̀ka; yóò sì yọ ẹ̀ka láti abẹ́ rẹ̀ wá, yóò si kọ́ tẹmpili Olúwa wa.
Òun ni yóò sì kọ́ tẹmpili Olúwa òun ni yóò sì wọ̀ ní ògo, yóò sì jókòó, yóò sì jẹ ọba lórí ìtẹ́ rẹ̀; òun ó sì jẹ́ àlùfáà lórí ìtẹ́ rẹ̀; ìmọ̀ àlàáfíà yóò sì wá láàrín àwọn méjèèjì.’