Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà náà ni Hagai dáhùn ó sì wí pé, “ ‘Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn wọ̀nyí rí, bẹ́ẹ̀ sì ni orílẹ̀-èdè yìí rí níwájú mi,’ ni Olúwa wí. ‘Bẹ́ẹ̀ sì ni olúkúlùkù iṣẹ́ ọwọ́ wọn; èyí tí wọ́n sì fi rú ẹbọ níbẹ̀ jẹ́ aláìmọ́.

  2. “ ‘Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ ro èyí dáradára láti òní yìí lọ, ẹ kíyèsi bí nǹkan ṣe rí tẹ́lẹ̀, a to òkúta kan lé orí èkejì ní tẹmpili Olúwa.

  3. Mo fi ìrẹ̀dànù, ìmúwòdù àti yìnyín bá gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín jẹ; síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí ọ̀dọ̀ mi,’ ni Olúwa wí.

  4. ‘Láti òní lọ, láti ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsànán yìí kí ẹ kíyèsi, kí ẹ sì rò ó dáradára, ọjọ́ ti a fi ìpìlẹ̀ tẹmpili Olúwa lélẹ̀, rò ó dáradára.

  5. Ǹjẹ́ èso ha wà nínú abà bí? Títí di àkókò yìí, àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ àti pomegiranate, àti igi olifi kò ì tí ì so èso kankan. “ ‘Láti òní lọ ni èmi yóò bùkún fún un yin.’ ”

  6. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ Hagai wá nígbà kejì, ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù náà pé,

  7. “Sọ fún Serubbabeli baálẹ̀ Juda pé èmi yóò mi àwọn ọ̀run àti ayé.

  8. Èmi yóò bi ìtẹ́ àwọn ìjọba ṣubú, Èmi yóò sì pa agbára àwọn aláìkọlà run, Èmi yóò sì dojú àwọn kẹ̀kẹ́ ogun dé, àti àwọn tí ń gùn wọ́n; ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin yóò ṣubú; olúkúlùkù nípa idà arákùnrin rẹ̀.”

  9. Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Ní ọjọ́ náà, ìwọ ìránṣẹ́ mi Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, Èmi yóò mú ọ, Èmi yóò sì sọ ọ di bí òrùka èdìdì mi, nítorí mo ti yan ọ, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”

  10. Ní oṣù kẹjọ ọdún kejì ọba Dariusi, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ wòlíì Sekariah ọmọ Berekiah, ọmọ Iddo pé:

  11. “Olúwa ti bínú sí àwọn baba ńlá yín.

  12. Nítorí náà sọ fún àwọn ènìyàn. Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Ẹ padà sí ọ̀dọ̀ mi,’ báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘èmi náà yóò sì padà sí ọ̀dọ̀ yín,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  13. Ẹ má dàbí àwọn baba yín, àwọn tí àwọn wòlíì ìṣáájú ti ké sí wí pé, báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Ẹ yípadà nísinsin yìí kúrò ní ọ̀nà búburú yín,’ àti kúrò nínú ìwà búburú yín; ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fetí sí ti èmi, ni Olúwa wí.

  14. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi àti ìlànà mi, ti mo pa ní àṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì, kò ha tún bá àwọn baba yín? “Wọ́n sì padà wọ́n wí pé, ‘Gẹ́gẹ́ bí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti rò láti ṣe sí wa, gẹ́gẹ́ bi ọ̀nà wa, àti gẹ́gẹ́ bí ìṣe wa, bẹ́ẹ̀ ní o ti ṣe sí wa.’ ”

  15. Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kọkànlá, tí ó jẹ́, oṣù Sebati, ní ọdún kejì Dariusi, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ wòlíì Sekariah, ọmọ Berekiah ọmọ Iddo wá, pé.

  16. Ọkùnrin tí ó dúró láàrín àwọn igi maritili sì dáhùn ó sì wí pé, “Wọ̀nyí ní àwọn tí Olúwa ti rán láti máa rìn sókè sódò ni ayé.”

  17. Wọ́n si dá angẹli Olúwa tí ó dúró láàrín àwọn igi maritili náà lóhùn pé, “Àwa ti rìn sókè sódò já ayé, àwa sí ti rí i pé gbogbo ayé wà ní ìsinmi àti àlàáfíà.”

  18. Nígbà náà ni angẹli Olúwa náà dáhùn ó sì wí pé, “Olúwa àwọn ọmọ-ogun, yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ kì yóò fi ṣàánú fún Jerusalẹmu, àti fún àwọn ìlú ńlá Juda, ti ìwọ ti bínú sí ni àádọ́rin ọdún wọ̀nyí?”

  19. Olúwa sì fi ọ̀rọ̀ rere àti ọ̀rọ̀ ìtùnú dá angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ lóhùn.

  20. Angẹli ti ń bá mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Ìwọ kígbe wí pé, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Èmi ń fi ìjowú ńlá jowú fún Jerusalẹmu àti fún Sioni.

  21. Èmi sì bínú púpọ̀púpọ̀ si àwọn orílẹ̀-èdè tí ó rò wí pé òun ní ààbò. Nítorí nígbà tí mo bínú díẹ̀, wọ́n ran ìparun lọ́wọ́ láti tẹ̀síwájú.’

  22. “Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí: ‘Mo padà tọ Jerusalẹmu wá pẹ̀lú àánú; ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, a ó kọ́ ilé mi sínú rẹ̀, a o sí ta okùn ìwọ̀n kan jáde sórí Jerusalẹmu.’

  23. “Máa ké síbẹ̀ pé, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘A o máa fi ìre kún ìlú ńlá mi síbẹ̀; Olúwa yóò sì máa tu Sioni nínú síbẹ̀, yóò sì yan Jerusalẹmu síbẹ̀.’ ”

  24. Olúwa sì fi alágbẹ̀dẹ mẹ́rin kan hàn mí.

  25. Olúwa wí pé: Èmi ó sì jẹ́ odi iná fún un yíká, èmi ó sì jẹ́ ògo láàrín rẹ̀.’