Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Bí mo ṣe ń fetí sí èyí, O tún sọ fún àwọn yòókù pé, “Tẹ̀lé ọkùnrin náà lọ sí àárín ìlú láti pa láì dá sí àti láì ṣàánú rárá.

  2. Ẹ pa arúgbó àti ọ̀dọ́mọkùnrin, ẹ pa ọlọ́mọge, obìnrin àti ọmọ kéékèèké, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe fi ọwọ́ kan àwọn tó ní àmì. Ẹ bẹ̀rẹ̀ láti ibi mímọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbàgbà tó wà níwájú tẹmpili.

  3. Nígbà náà lo sọ fún wọn pé, “Ẹ sọ tẹmpili náà di àìmọ́, kí òkú sì kún àgbàlá náà. Ẹ lọ!” Wọ́n jáde síta, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í pa ènìyàn láàrín ìlú.

  4. Èmi nìkan ló ṣẹ́kù nígbà tí wọ́n lọ pa àwọn ènìyàn, mo dójú mi bolẹ̀, mo kígbe pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè! Ìwọ yóò ha pa ìyókù Israẹli nípa dída ìbínú gbígbóná rẹ sórí Jerusalẹmu?”

  5. Ó dá mi lóhùn pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli àti Juda pọ gidigidi; ilé wọn kún fún ìtàjẹ̀ sílẹ̀ àti àìṣòótọ́. Wọ́n ní, ‘Olúwa tí kọ ilẹ̀ náà sílẹ̀; Olúwa kò sì rí wa.’

  6. Nítorí náà, èmi kò ní wò wọ́n pẹ̀lú àánú, èmi kò sì ní dá wọn sí, ṣùgbọ́n Èmi yóò dá ohun tí wọ́n ti ṣe padà sórí wọn.”

  7. Ọkùnrin tí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀, tí ó ní ìwo tàdáwà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ròyìn pé, “Mo ti ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti pàṣẹ fún mi.”

  8. Olúwa sì sọ fún ọkùnrin tó wọ aṣọ funfun pé, “Lọ sí àárín àwọn kẹ̀kẹ́ tó wà lábẹ́ kérúbù. Bu ẹyin iná tó kúnwọ́ rẹ láàrín kérúbù, kí o sì fọ́n sórí ìlú náà.” Ó sì lọ lójú mi.

  9. Ògo Olúwa sì kúrò lórí àwọn kérúbù, ó bọ́ sí ibi ìloro tẹmpili. Ìkùùkuu sì bo inú tẹmpili, àgbàlá sì kún fún ìmọ́lẹ̀ àti ògo Olúwa.

  10. A sì gbọ́ ariwo ìyẹ́ àwọn kérúbù yìí títí dé àgbàlá tó wà ní ìta gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí Ọlọ́run Olódùmarè bá ń sọ̀rọ̀.

  11. Nígbà tí Olúwa pàṣẹ fún ọkùnrin aláṣọ funfun yìí pé, “Mú iná láàrín àwọn kẹ̀kẹ́, láàrín àwọn kérúbù,” ó sì lọ dúró ṣẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kẹ̀kẹ́ náà.

  12. Ògo Olúwa kúrò níbi ìloro tẹmpili, ó sì dúró sórí àwọn kérúbù.

  13. Àwọn kérúbù gbé ìyẹ́ wọn sókè, wọ́n sì fò kúrò nílẹ̀ lójú mi, wọ́n sì lọ pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ wọn lẹ́ẹ̀kan náà. Wọ́n dúró níbi ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà ìlà-oòrùn ilé Olúwa, ògo Ọlọ́run Israẹli sì wà lórí wọn.

  14. Àwọn wọ̀nyí ni ẹ̀dá alààyè tí mo rí lábẹ́ Ọlọ́run Israẹli létí odò Kebari, mo sì mọ̀ pé kérúbù ni wọ́n.

  15. Ẹ̀mí sì gbé mi sókè, ó mú mi lọ sí ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa èyí tó dojúkọ ìlà-oòrùn. Ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà yìí ni àwọn ọkùnrin mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n wá, mo rí Jaaṣaniah ọmọ Assuri àti Pelatiah ọmọ Benaiah, tí wọ́n jẹ́ ìjòyè àwọn ènìyàn.

  16. Olúwa sì sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, àwọn ọkùnrin yìí ló ń pète ibi, wọ́n sì ń gbé ìmọ̀ràn búburú kalẹ̀ nínú ìlú.

  17. Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé mi, ó sì wí pé, “Sọ̀rọ̀!” Báyìí ni Olúwa wí, ohun tí ẹ ń sọ nìyìí, ilé Israẹli, mo mọ ohun tó wà lọ́kàn yín.

  18. “Torí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, àwọn òkú tí ẹ fọn sílẹ̀ sí àárín yín ni ẹran, ìlú yìí sì ni ìkòkò ìdáná ṣùgbọ́n èmi yóò le yín jáde níbẹ̀.

  19. Ẹ bẹ̀rù idà, èmi yóò sì mú idà wá sórí yín, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí.

  20. Èmi yóò lé yín jáde kúrò ní ìlú yìí, èmi yóò sì fà yín lé àjèjì lọ́wọ́, èmi yóò sì mú ìdájọ́ ṣẹ lé yín lórí.

  21. Nípa idà ni ẹ̀yin yóò ṣubú, èmi yóò sì ṣe ìdájọ́ yín ní àwọn ààlà ìlú Israẹli. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.

  22. Ìlú yìí kò ní i jẹ́ ìkòkò ìdáná, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin náà kò sì ní jẹ́ ẹran nínú rẹ̀, Èmi yóò ṣe ìdájọ́ yín ní àwọn ààlà ìlú Israẹli.

  23. Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, nítorí pé ẹ̀yin kò tẹ̀lé àṣẹ mi ẹ̀yin kò sì pa òfin mi mọ́, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìgbàgbọ́ orílẹ̀-èdè tó yí yín ká.”

  24. Bí mo ṣe ń sọtẹ́lẹ̀ lọ́wọ́, Pelatiah ọmọ Benaiah kú. Mo sì dojúbolẹ̀, mo sì kígbe sókè pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè! Ṣé ìwọ yóò ha pa ìyókù Israẹli run pátápátá ni?”

  25. Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé,