God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Nítorí náà, Olúwa Olódùmarè wí pé, bí mo ṣe wà láààyè, nítorí pé ìwọ ti sọ ibi mímọ́ mi di àìmọ́ pẹ̀lú àwọn àwòrán ẹ̀gbin àti àwọn ohun ìríra rẹ, èmi yóò mú ojúrere mi kúrò lára rẹ, èmi kò ní í da ọ sí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò wò ọ́ pẹ̀lú àánú mọ́.
Ìdámẹ́ta nínú àwọn ènìyàn rẹ yóò kú nípa àjàkálẹ̀-ààrùn tàbí kí ìyàn run wọ́n: ìdámẹ́ta yóò ṣubú nípa idà lẹ́yìn odi rẹ, èmi yóò sì tú ìdámẹ́ta yòókù ká sínú ẹ̀fúùfù, èmi yóò sì máa fi idà lé wọn.
“Ìbínú mi yóò sì dúró, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú gbígbóná mi yóò sì rọlẹ̀, èmi yóò sì ti gba ẹ̀san mi. Nígbà tí mo bá sì parí ìbínú mi lórí wọn, wọn ó mọ̀ pé, Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀ nínú ìtara mi.
“Èmi yóò fi ọ́ ṣòfò, èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹ̀gàn fún àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká, àti lójú àwọn tó ń kọjá.
O ó wá di ẹ̀gàn, ẹ̀sín àti ẹ̀kọ̀ àti ohun ẹ̀rù àti ìyanu fún àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká, nígbà tí mo bá fìyà jẹ ọ́ nínú ìbínú àti nínú ìbínú gbígbóná mi. Èmi Olúwa ni ó sọ bẹ́ẹ̀.
Nígbà tí èmi ó rán ọfà búburú ìyàn sí wọn, èyí tí yóò jẹ́ fún ìparun wọn. Èmí tí èmi yóò rán run yín. Èmí yóò sì sọ ìyàn di púpọ̀ fún yín. Èmí yóò sì ṣẹ́ ọ̀pá oúnjẹ yín.
Èmi yóò rán ìyàn àti ẹranko búburú sí i yín, wọn yóò fi yín sílẹ̀ ni àìlọ́mọ. Àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìtàjẹ̀ sílẹ̀ yóò kọjá láàrín yín. Èmi yóò si mú idà wá sórí rẹ. Èmi Olúwa ló sọ bẹ́ẹ̀.”
Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé,
wí pé, ‘Ẹ̀yin òkè Israẹli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Olódùmarè. Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí sí ẹ̀yin òkè ńlá àti àwọn òkè kéékèèké, sí àwọn odò ṣíṣàn àti sí àfonífojì, èmi yóò mú idà wa sórí yín, èmí yóò sì pa ibi gíga yín run.
Èmi yóò wó pẹpẹ yín lulẹ̀, èmi yóò sì fọ́ pẹpẹ tùràrí yín túútúú; èmi yóò sì pa àwọn ènìyàn yín síwájú àwọn òrìṣà wọn.
Èmi yóò tẹ́ òkú àwọn ará Israẹli síwájú òrìṣà wọn, èmi yóò sì fọ́n egungun wọn yí pẹpẹ wọn ká.
Àwọn ènìyàn yín yóò ṣubú láàrín yín, ẹ ó sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.
“ ‘Ṣùgbọ́n èmi yóò dá àwọn kan sí nítorí pé díẹ̀ nínú yín ni yóò bọ́ lọ́wọ́ idà, nígbà tí a bá fọ́n yín ká sí gbogbo ilẹ̀ àti orílẹ̀-èdè.
Àwọn ti ó bọ́ nínú yin yóò sì rántí mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè níbi tí wọn yóò dìwọ́n ní ìgbèkùn lọ, nítorí wọ́n yóò máa rántí mi bí wọ́n ti bà mí lọ́kàn jẹ́ nípa àgbèrè wọn, tí ó yà wọ́n kúrò lọ́dọ̀ mi àti nípa ojú wọn tí ó ṣàfẹ́rí àwọn òrìṣà. Wọn yóò sì ṣú ara wọn nítorí ìwà ibi tí wọ́n ti hù nípa gbogbo ìríra wọn.
Wọn yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa; àti pé kì í ṣe lásán ni mo ń lérí pé èmi yóò mú ìdààmú bá wọn.
“ ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí, Pàtẹ́wọ́ kí o tún fẹsẹ̀ janlẹ̀, kí o wá kígbe síta pé, “Ó ṣe!” Ilé Israẹli yóò ṣubú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn nítorí gbogbo ìwà ìríra búburú tí wọ́n hù. Wọn yóò ṣubú nípa idà àti ìyàn.
Ẹni tó wà lókèèrè yóò kú pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn, àti ẹni tó wà nítòsí yóò ṣubú pẹ̀lú idà, ìyàn ni yóò pa ẹni tó bá ṣẹ́kù sílẹ̀. Báyìí ni èmi yóò ṣe mú ìbínú gbígbóná mi wá sórí wọn.
Wọn yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, nígbà tí òkú àwọn ènìyàn wọn bá wà níbẹ̀ láàrín òrìṣà wọn yí pẹpẹ wọn ká, lórí àwọn òkè gíga gbogbo, àti lórí góńgó òkè àti lábẹ́ igi tútù àti lábẹ́ igi óákù, níbi tí wọ́n ti ń fi tùràrí olóòórùn dídùn rú ẹbọ sí gbogbo òrìṣà wọn.
Èmi yóò na ọwọ́ mi jáde sí wọn láti mú kí ilẹ̀ náà ṣòfò, kí ó sì dahoro dé aṣálẹ̀ ìhà Dibila—ní gbogbo ibùgbé wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.’ ”
Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
“Ọmọ ènìyàn, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí sí ilé Israẹli: “ ‘Òpin! Òpin ti dé sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ náà!
Òpin tí dé sí ọ báyìí, èmi yóò sì tú ìbínú mi jáde sí ọ, èmi yóò dájọ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìwà rẹ, èmi yóò sì san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìwà ìríra rẹ.
Ojú mi kò ní i dá ọ sì, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò ṣàánú; ṣùgbọ́n èmi yóò san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ àti gbogbo ìwà ìríra tó wà láàrín rẹ. Nígbà náà ní ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’
“Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Ibi! Ibi kan ṣoṣo. Kíyèsi, ó bọ̀ ní orí rẹ!
Mo ṣetán láti tú ìbínú gbígbóná mi lé ọ lórí àti láti lo ìbínú mi lórí rẹ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀nà rẹ, èmi yóò sì dá ọ lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ àti gẹ́gẹ́ bí ìwà ìríra rẹ ni èmi yóò sì san án fún ọ.