Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Ọmọ ènìyàn, àwọn arákùnrin rẹ, àní àwọn ará rẹ, àwọn ọkùnrin nínú ìbátan rẹ, àti gbogbo ilé Israẹli pátápátá, ni àwọn ará Jerusalẹmu ti wí fún pé, ‘Ẹ jìnnà sí Olúwa, àwa ni a fi ilẹ̀ yìí fún yín ní ìní.’

  2. “Nítorí náà, sọ fún àwọn tó wà ní ìgbèkùn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fọ́n wọn káàkiri orílẹ̀-èdè, síbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, èmi yóò jẹ́ ibi mímọ́ fún wọn níbi tí wọ́n lọ.’

  3. “Nítorí náà, wí pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, Èmi yóò kó wọn jọ kúrò láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tí mo fọ́n wọn ká sí, Èmi yóò sì fún wọn ní ilẹ̀ Israẹli padà.’

  4. Èmi yóò fún wọn ní ọ̀kankan; èmi yóò sì fi ẹ̀mí tuntun sínú wọn, Èmi yóò mú ọkàn òkúta kúrò lára wọn, èmi yóò sì fún wọn ní ọkàn tó rọ̀ bí ara ẹran.

  5. Kí wọn le tẹ̀lé àṣẹ mi, kí wọn sì le pa òfin mi mọ́. Wọ́n yóò jẹ́ ènìyàn mi, Èmi náà yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.

  6. Ṣùgbọ́n fún àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sin àwọn àwòrán ìríra àti àwọn òrìṣà, Èmi yóò mú ẹ̀san ohun tí wọ́n ṣe wá sí orí wọn bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí.”

  7. Àwọn kérúbù sì gbé ìyẹ́ wọn sókè pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, ògo Ọlọ́run Israẹli sì wà lókè orí wọn.

  8. Ògo Olúwa sì gòkè lọ kúrò láàrín ìlú, ó sì dúró lórí òkè tó wà ní ìlà-oòrùn ìlú náà.

  9. Lẹ́yìn náà, Ẹ̀mí gbé mi sókè, ó sì mú mi wá sí Kaldea lójú ìran, nípa ti Ẹ̀mí Ọlọ́run sí ọ̀dọ̀ àwọn ti ìgbèkùn. Bẹ́ẹ̀ ni ìran tí mo rí lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ mi,

  10. mo sì sọ gbogbo ohun tí Olúwa fihàn mí fún àwọn tó wà ní ìgbèkùn.

  11. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

  12. Gbé ẹrù rẹ lé èjìká ní ojú wọn, bo ojú rẹ, kí ìwọ má ba à rí ilẹ̀, sì ru ẹrù rẹ lọ ní alẹ́ nítorí pé mo fi ọ́ ṣe àmì fún ilé Israẹli.”

  13. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

  14. “Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ yìí kan àwọn ọmọ-aládé Jerusalẹmu àti gbogbo ilé Israẹli tí ó wà ní àárín rẹ.

  15. Sọ fún wọn pé, Èmi jẹ́ àmì fún yín’. “Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe sí wọn. Wọn ó kó lọ sí ìgbèkùn. Gẹ́gẹ́ bí ẹni ti a dè ní ìgbèkùn.

  16. Èmi yóò ta àwọ̀n mi lé e lórí, yóò sì kó sínú okùn, Èmi yóò sì mú lọ sí Babeli, ní ilẹ̀ Kaldea, ṣùgbọ́n kò ní fojúrí ilẹ̀ náà ibẹ̀ ni yóò kú sí.

  17. Gbogbo àwọn tó yí i ká láti ràn án lọ́wọ́ ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ni Èmi yóò túká sí afẹ́fẹ́, èmi yóò sì tún fi idà lé wọn kiri.

  18. “Wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa nígbà tí mo bá tú wọn ká ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè, tí mo sì fọ́n wọn ká sí ilẹ̀ káàkiri.

  19. Ṣùgbọ́n èmi yóò ṣẹ́ díẹ̀ kù lára wọn, ní ọwọ́ idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn, kí wọn le jẹ́wọ́ gbogbo ìṣe ìríra wọn ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè yìí. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.”

  20. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

  21. Sọ fún àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí fún àwọn olùgbé Jerusalẹmu àti ilẹ̀ Israẹli pé, pẹ̀lú àìbalẹ̀ àyà ni wọn yóò máa jẹun wọn, wọn yóò sì mu omi pẹ̀lú àìnírètí, kí ilẹ̀ wọn lè di ahoro torí ìwà ipá àwọn tó ń gbé ibẹ̀.

  22. Ìlú tó jẹ́ ibùgbé ènìyàn tẹ́lẹ̀ yóò di òfo, ilẹ̀ náà yóò sì di ahoro. Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.’ ”

  23. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé:

  24. Nítorí náà wí fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, Èmi yóò fi òpin sí òwe yìí, wọn kò ní ipa mọ́ ní Israẹli.’ Sọ fún wọn, ‘Ọjọ́ náà súnmọ́ tòsí nígbà tí gbogbo ìran àti ìsọtẹ́lẹ̀ yóò sì wá sí ìmúṣẹ.

  25. Ṣùgbọ́n, Èmi Olúwa yóò sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ tí mo sọ yóò sì ṣẹ láì falẹ̀. Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, ní àsìkò yín, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀ ilé ni Èmi yóò mú ọ̀rọ̀ yówù tí mo bá sọ ṣẹ.’ ”