God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
“ ‘Nítorí náà, má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi, má sì ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, ìwọ Israẹli,’ ni Olúwa wí. ‘Èmi yóò gbà ọ́ kúrò láti ọ̀nà jíjìn wá, àní àwọn ìran rẹ láti ilẹ̀ àtìpó wọn. Jakọbu yóò sì tún ní àlàáfíà àti ààbò rẹ̀ padà, kò sì ṣí ẹni tí yóò ṣẹ̀rù bà á mọ́.
Èmi wà pẹ̀lú rẹ, n ó sì gbà ọ́,’ ni Olúwa wí. ‘Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀-èdè run, nínú èyí tí mo ti fọ́n ọn yín ká, síbẹ̀ èmi kì yóò pa yín run pátápátá. Èmi yóò bá yín wí pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo nìkan; Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ láìjìyà.’
“Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “ ‘Ọgbẹ́ yín kò gbóògùn, bẹ́ẹ̀ ni egbò yín kọjá ìwòsàn.
Gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ ti gbàgbé rẹ, wọn kò sì náání rẹ mọ́ pẹ̀lú. Mo ti nà ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá rẹ yóò ti nà ọ, mo sì bá a ọ wí gẹ́gẹ́ bí ìkà, nítorí tí ẹ̀bi rẹ pọ̀ púpọ̀, ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kò sì lóǹkà.
Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń kígbe nítorí ọgbẹ́ yín, ìrora yín èyí tí kò ní oògùn? Nítorí ọ̀pọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ yín àti ẹ̀bi yín tó ga ni mo fi ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí i yín.
“ ‘Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe yín ní ibi ni ibi yóò bá, àní gbogbo àwọn ọ̀tá yín ni a ó sọ di àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì; gbogbo àwọn tí wọ́n bà yín jẹ́ ni a ó bàjẹ́.
Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìlera fún yín, èmi yóò sì wo ọ̀gbẹ́ yín sàn,’ ni Olúwa wí, ‘nítorí tí a pè yín ní alárìnkiri, Sioni tí gbogbo ènìyàn dágunlá sí.’
“Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “ ‘Èmi yóò dá gbogbo ìre àgọ́ Jakọbu padà, èmi yóò sì ṣe àánú fún olùgbé àgọ́ rẹ̀; ìlú náà yóò sì di títúnṣe tí ààfin ìlú náà yóò sì wà ní ipò rẹ̀.
Láti ẹnu wọn ni orin ọpẹ́ àti ìyìn yóò sì ti máa jáde. Èmi yóò sọ wọ́n di púpọ̀, wọn kì yóò sì dínkù ní iye, Èmi yóò fi ọlá fún wọn, wọn kò sì ní di ẹni àbùkù.
Ọmọ ọmọ wọn yóò wà bí i ti ìgbàanì níwájú mi ni wọn yóò sì tẹ àwùjọ wọn dúró sí. Gbogbo ẹni tó bá ni wọ́n lára, ni èmi yóò fì ìyà jẹ.
Ọ̀kan nínú wọn ni yóò jẹ́ olórí wọn, ọba wọn yóò dìde láti àárín wọn. Èmi yóò mú un wá sí ọ̀dọ̀ mi, òun yóò sì súnmọ́ mi, nítorí ta ni ẹni náà tí yóò fi ara rẹ̀ jì láti súnmọ́ mi?’ ni Olúwa wí.
‘Nítorí náà, ẹ̀yin yóò jẹ́ ènìyàn mi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín.’ ”
Wò ó, ìbínú Olúwa yóò tú jáde, ìjì líle yóò sì sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn ènìyàn búburú.
Ìbínú ńlá Olúwa kò ní dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn ìkà títí yóò fi mú èrò ọkàn rẹ̀ ṣẹ. Ní àìpẹ́ ọjọ́, òye rẹ̀ yóò yé e yín.
“Nígbà náà, Èmi yóò jẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo ìdílé ìran Israẹli, àwọn náà yóò sì jẹ́ ènìyàn mi,” ni Olúwa wí.
Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Àwọn ènìyàn tí ó sá àsálà lọ́wọ́ idà yóò rí ojúrere Olúwa ní aṣálẹ̀, Èmi yóò sì fi ìsinmi fún Israẹli.”
Olúwa ti fi ara rẹ̀ hàn wá ní ìgbà kan rí, ó wí pé: “Èmi ti nífẹ̀ẹ́ yín pẹ̀lú ìfẹ́ àìlópin; mo ti fi ìfẹ́ ńlá fà yín,
Èmi yóò tún gbé e yín sókè, àní a ó tún gbé e yín ró ìwọ wúńdíá ilẹ̀ Israẹli. Àní ẹ ó tún tún ohun èlò orin yín gbé, ẹ ó sì jáde síta pẹ̀lú ijó àti ayọ̀.
Ọjọ́ kan máa wà tí àwọn olùṣọ́ yóò kígbe jáde lórí òkè Efraimu wí pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a gòkè lọ sí Sioni, ní ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wa.’ ”
Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ wí pé: “Ẹ fi ayọ̀ kọrin sí Jakọbu; ẹ hó sí olórí àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo. Jẹ́ kí wọ́n gbọ́ ìyìn rẹ kí o sì wí pé, ‘Olúwa, gba àwọn ènìyàn rẹ là; àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Israẹli.’
Wò ó, Èmi yóò mú wọn wá láti ilẹ̀ àríwá; èmi yóò kó gbogbo wọn jọ láti òpin ayé. Lára wọn ni yóò jẹ́ afọ́jú àti arọ, aboyún àti obìnrin tí ń rọbí, ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wá.
Wọn yóò wá pẹ̀lú ẹkún, wọn yóò gbàdúrà bí Èmi yóò ṣe mú wọn padà. Èmi yóò jẹ́ atọ́nà fún wọn ní ẹ̀bá odò omi; ní ọ̀nà tí ó tẹ́jú tí wọn kì yóò le ṣubú, nítorí èmi ni baba Israẹli, Efraimu sì ni àkọ́bí ọkùnrin mi.
“Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin orílẹ̀-èdè ẹ kéde rẹ̀ ní erékùṣù jíjìn; ‘Ẹni tí ó bá tú Israẹli ká yóò kójọ, yóò sì ṣọ́ agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn.’
Nítorí Olúwa ti tú Jakọbu sílẹ̀, o sì rà á padà ní ọwọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ.
Wọn yóò wá, wọn ó sì hó ìhó ayọ̀ lórí òkè Sioni; wọn yóò yọ ayọ̀ níbi oore Olúwa. Àlìkámà ni, ọtí wáìnì tuntun àti òróró ọ̀dọ́-àgùntàn àti ọ̀dọ́ ọ̀wọ́ ẹran. Wọn ó dàbí ọgbà àjàrà tí a bomirin, ìkorò kò ní bá wọn mọ́.