Fò sí àkóónú

Ephraim

160 ẹsẹ · 9 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Ephraim

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Efraimu gbéraga, “Èmi ní ìní fún ara mi, mo sì ti di ọlọ́rọ̀, pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ mi yìí, wọn kò le ká àìṣedéédéé tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kankan mọ́ mi lọ́wọ́.”

  2. Ṣùgbọ́n Efraimu ti mú un bínú gidigidi; Olúwa rẹ̀ yóò sì fi ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sí orí rẹ̀ òun yóò sì san án padà fún un nítorí ìwà ẹ̀gàn an rẹ̀.

  3. Nígbà ti Efraimu bá ń sọ̀rọ̀, àwọn ènìyàn máa ń wárìrì, a gbé e ga ní Israẹli ṣùgbọ́n ó jẹ̀bi ẹ̀sùn pé ó ń sin òrìṣà Baali, ó sì kú.

  4. Ẹ̀bi Efraimu ni a tí ko jọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wà nínú àkọsílẹ̀.

  5. Ìwọ Efraimu, kín ló tún kù tí mo ní ṣe pẹ̀lú ère òrìṣà? Èmi ó dá a lóhùn, èmi ó sì ṣe ìtọ́jú rẹ. Mo dàbí igi junifa tó ń fi gbogbo ìgbà tutù, èso tí ìwọ ń so si ń wá láti ọ̀dọ̀ mi.”

  6. Àwọn ará gúúsù yóò ni òkè Esau, àwọn ará ẹsẹ̀ òkè yóò ni ilẹ̀ àwọn ará Filistini ní ìní. Wọn yóò sì ni oko Efraimu àti Samaria; Benjamini yóò ní Gileadi ní ìní.

  7. Èmi ó sì gbé kẹ̀kẹ́ kúrò ni Efraimu, àti ẹṣin ogun kúrò ni Jerusalẹmu, a ó sì ṣẹ́ ọrun ogun. Òun yóò sì kéde àlàáfíà sí àwọn kèfèrí. Ìjọba rẹ̀ yóò sì gbilẹ̀ láti Òkun dé Òkun, àti láti odò títí de òpin ayé.

  8. Èmi ó fa Juda le bí mo ṣe fa ọrun mi le, mo sì fi Efraimu kún un, Èmi yóò gbé àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin dìde, ìwọ Sioni, sí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ìwọ Giriki, mo ṣe ọ́ bí idà alágbára.

  9. Efraimu yóò sì ṣe bí alágbára, ọkàn wọn yóò sì yọ̀ bi ẹni pé nípa ọtí wáìnì: àní àwọn ọmọ wọn yóò rí í, wọn o sì yọ̀, inú wọn ó sì dùn nínú Olúwa.

  10. Nítorí náà Jesu kò rìn ní gbangba láàrín àwọn Júù mọ́; ṣùgbọ́n ó ti ibẹ̀ lọ sí ìgbèríko kan tí ó súnmọ́ aginjù, sí ìlú ńlá kan tí a ń pè ní Efraimu, níbẹ̀ ni ó sì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.