Skip to content
Onidajọ 19:1-16

Onidajọ 19:1-16

1
Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì Israẹli kò ní ọba. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Lefi tí ń gbé ibi tí ó sá pamọ́ nínú àwọn agbègbè òkè Efraimu, mú àlè kan láti Bẹtilẹhẹmu ní Juda.
2
Ṣùgbọ́n àlè rẹ̀ náà sì ṣe panṣágà sí i, òun fi sílẹ̀, ó sì padà lọ sí ilé baba rẹ̀ ní Bẹtilẹhẹmu ti Juda, ó sì wà ní ibẹ̀ ní ìwọ̀n oṣù mẹ́rin,
3
ọkọ rẹ̀ lọ sí ibẹ̀ láti rọ̀ ọ́ pé kí ó padà sí ọ̀dọ̀ òun. Nígbà tí ó ń lọ ó mú ìránṣẹ́ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì lọ́wọ́, obìnrin náà mú un wọ inú ilé baba rẹ̀ lọ, nígbà tí baba obìnrin náà rí i ó fi tayọ̀tayọ̀ gbà á.
4
Àna rẹ̀, baba ọmọbìnrin náà rọ̀ ọ́, ó sì borí rẹ̀ láti dá a dúró fún ìgbà díẹ̀, òun sì dúró fún ọjọ́ mẹ́ta, ó ń jẹ, ó ń mu, ó sì ń sùn níbẹ̀.
5
Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n dìde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù òun sì múra láti padà lọ, ṣùgbọ́n baba ọmọbìnrin náà wí fún àna rẹ̀ pé, “Fi ohun jíjẹ díẹ̀ gbé inú ró nígbà náà kí ìwọ máa lọ.”
6
Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ jókòó láti jọ jẹun àti láti jọ mu. Lẹ́yìn èyí ni baba ọmọbìnrin wí pé, “Jọ̀wọ́ dúró ní alẹ́ yìí kí o sì gbádùn ara rẹ.”
7
Nígbà tí ọkùnrin náà dìde láti máa lọ, baba ìyàwó rẹ̀ rọ̀ ọ́, torí náà ó sùn níbẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ náà.
8
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ karùn-ún nígbà tí ó dìde láti lọ, baba ọmọbìnrin wí pé, “Fi oúnjẹ gbé ara ró. Dúró de ọ̀sán!” Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ jọ jẹun.
9
Nígbà tí ọkùnrin náà, pẹ̀lú àlè àti ìránṣẹ́ rẹ̀, dìde láti máa lọ, àna rẹ̀, baba ọmọbìnrin náà ní, “Wò ó ilẹ̀ ti ń ṣú lọ, dúró níbí, ọjọ́ ti lọ. Dúró kí o sì gbádùn ara rẹ. Ìwọ lè jí ní àárọ̀ kùtùkùtù ọ̀la kí ìwọ sì máa lọ ilé.”
10
Ṣùgbọ́n nítorí pé òun kò fẹ́ dúró mọ́ níbẹ̀ ní òru náà ọkùnrin náà kúrò ó sì gba ọ̀nà Jebusi: ọ̀nà Jerusalẹmu pẹ̀lú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ méjèèjì tí ó fi dì í ní gàárì àti àlè rẹ̀.
11
Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Jebusi tí ilẹ̀ ti fẹ́ ṣú tan, ìránṣẹ́ náà sọ fún ọ̀gá rẹ̀ pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a dúró ní ìlú yìí tí í ṣe ti àwọn ará Jebusi kí a sì sùn níbẹ̀.”
12
Ọ̀gá rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Rárá o, àwa kì yóò wọ ìlú àwọn àjèjì, àwọn tí olùgbé ibẹ̀ kì í ṣe ọmọ Israẹli, a yóò dé Gibeah.”
13
Ó fi kún un pé, ẹ wá ẹ jẹ́ kí a gbìyànjú kí a dé Gibeah tàbí Rama kí a sùn ní ọ̀kan nínú wọn.
14
Wọ́n sì tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò wọn, oòrùn wọ̀ bí wọ́n ti súnmọ́ Gibeah tí ṣe ti àwọn Benjamini.
15
Wọ́n yípadà wọ́n lọ sí inú ìlú Gibeah láti wọ̀ síbẹ̀ ní òru náà, wọ́n lọ wọ́n sì jókòó níbi gbọ̀ngàn ìlú náà, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó gbà wọ́n sínú ilé rẹ̀ láti wọ̀ sí.
16
Ní alẹ́ ọjọ́ náà ọkùnrin arúgbó kan láti àwọn òkè Efraimu, ṣùgbọ́n tí ń gbé ní Gibeah (ibẹ̀ ni àwọn ẹ̀yà Benjamini ń gbé) ń ti ibi iṣẹ́ rẹ̀ bọ̀ láti inú oko.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options