Skip to content
Gẹnẹsisi 14:13-24

Gẹnẹsisi 14:13-24

13
Ẹnìkan tí ó sá àsálà sì wá ròyìn fún Abramu, ará Heberu ni. Abramu sá ti tẹ̀dó sí ẹ̀gbẹ́ igi ńlá igbó Mamre ará Amori, arákùnrin Eṣkolu àti Aneri: àwọn ẹni tí ó ń bá Abramu ní àṣepọ̀.
14
Nígbà tí Abramu gbọ́ wí pé, a di Lọti ní ìgbèkùn, ó kó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí a bí sí ilẹ̀ rẹ̀ tí ó sì ti kọ́ ni ogun jíjà jáde, wọ́n jẹ́ okòó lé lọ́ọ̀dúnrún ó dín méjì (318) ènìyàn, ó sì lépa wọn títí dé Dani.
15
Ní ọ̀gànjọ́ òru, Abramu pín àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sí méjì, ó sì kọlù wọ́n, ó sì ṣẹ́gun wọn, ó sì lé wọn títí dé Hoba tí ó wà ní apá òsì Damasku.
16
Gbogbo ìkógun ni ó rí gbà padà àti ọmọ arákùnrin rẹ̀, Lọti pẹ̀lú ohun ìní rẹ̀, àti àwọn obìnrin pẹ̀lú àwọn ènìyàn tókù.
17
Nígbà tí Abramu ti ṣẹ́gun Kedorlaomeri àti àwọn ọba tí ó pẹ̀lú rẹ̀, ọba Sodomu lọ pàdé rẹ̀ ní àfonífojì Ṣafe (èyí ni àfonífojì Ọba).
18
Melkisedeki ọba Salẹmu sì mú oúnjẹ àti ọtí wáìnì jáde wá. Òun ni àlùfáà Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo.
19
Ó sì súre fún Abramu, wí pé, “Ìbùkún ni fún Abramu ti Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, Ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.
20
Ìbùkún sì ni fún Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ, tí ó fi àwọn ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́.” Abramu sì fún un ní ìdámẹ́wàá ohun gbogbo.
21
Ọba Sodomu sì wí fún Abramu pé, “Kó àwọn ènìyàn mi fún mi, ṣùgbọ́n mú àwọn ẹrù fún ara rẹ.”
22
Ṣùgbọ́n Abramu dá ọba Sodomu lóhùn pé, “Mo ti búra fún Olúwa, Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, tí ó dá ọ̀run àti ayé, mo sì ti gbọ́wọ́ sókè,
23
pé, èmi kì yóò mú láti fọ́nrán òwú títí dé okùn bàtà, àti pé, èmi kí yóò mú ohun kan tí ṣe tìrẹ, kí ìwọ kí ó má ba à wí pé, ‘Mo sọ Abramu di ọlọ́rọ̀.’
24
Èmi kì yóò gba ohunkóhun yàtọ̀ sí ohun tí àwọn ọkùnrin mi ti jẹ́, ṣùgbọ́n fi ìpín fún àwọn ọkùnrin tí ó bá mi lọ, Aneri, Eṣkolu àti Mamre. Jẹ́ kí wọn kí ó gba ìpín wọn.”
Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options