Skip to content
Daniẹli 9:3-19

Àdúrà Ìjẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ Dáníẹ́lì

Daniẹli 9:3-19

Àdúrà Ìjẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ Dáníẹ́lì

3
Nígbà náà, ni mo yípadà sí Olúwa Ọlọ́run, mo bẹ̀ ẹ́ pẹ̀lú àdúrà àti ẹ̀bẹ̀, pẹ̀lú àwẹ̀, aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú.
4
Mo gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run mi, mo sì jẹ́wọ́ wí pé: “Ìwọ Olúwa, Ọlọ́run tí ó tóbi, tí ó sì ní ẹ̀rù, ẹni tí ń pa májẹ̀mú ìfẹ́ mọ́, pẹ̀lú àwọn tí ó ní ìfẹ́ rẹ̀ àti àwọn tí ó ń pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́.
5
Àwa ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe búburú. Àwa ti hu ìwà búburú, a sì ti ṣe ọ̀tẹ̀, a ti yí padà kúrò nínú àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà rẹ̀.
6
Àwa kò fetí sí àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ sí àwọn ọba wa, àwọn ọmọ-aládé àti àwọn baba wa, àti sí gbogbo ènìyàn ilẹ̀ náà.
7
“Olúwa ìwọ ni olódodo, ṣùgbọ́n báyìí ìtìjú dé bá àwọn ènìyàn Juda, àwọn ènìyàn Jerusalẹmu àti gbogbo Israẹli ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti fọ́n wa ká sí nítorí àìṣòótọ́ ọ wa sí ọ.
8
Háà! Olúwa, àwa àti àwọn ọba wa, àwọn ọmọ-aládé, àti àwọn baba wa, ìtìjú dé bá wa nítorí àwa ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ.
9
Olúwa Ọlọ́run wa ní àánú, ó sì ń dáríjì, bí àwa tilẹ̀ ti ṣe ọ̀tẹ̀ sí i;
10
àwa kò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa, a kò sì pa àwọn òfin rẹ mọ́, èyí tí ó fún wa nípasẹ̀ àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀.
11
Gbogbo Israẹli ti ṣẹ̀ sí òfin rẹ, wọ́n ti yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, wọ́n kọ̀ láti ṣe ìgbọ́ràn sí ọ. “Nígbà náà ni ègún àti ìdájọ́ tí a kọ sílẹ̀ pẹ̀lú ìbúra nínú òfin Mose ìránṣẹ́ Ọlọ́run dà sórí i wa, nítorí tí àwa ti sẹ̀ sí ọ.
12
Ìwọ ti mú ọ̀rọ̀ tí o sọ sí wa sẹ àti lórí àwọn alákòóso wa, nípa mímú kí ibi ńlá bá wa, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí lábẹ́ ọ̀run, bí ó ti ṣẹlẹ̀ sí Jerusalẹmu yìí.
13
Bí a ti kọ ọ́ sínú òfin Mose bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ibi yìí ti dé bá wa, síbẹ̀ a kò bẹ̀bẹ̀ fún ojúrere Olúwa Ọlọ́run wa, nípa yíyí padà kí a kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa kí a sì mọ òtítọ́ rẹ.
14
Olúwa kò jáfara láti mú ibi náà wá sórí wa, nítorí olódodo ni Olúwa Ọlọ́run wa nínú u gbogbo ohun tí ó ń ṣe; síbẹ̀ àwa kò ṣe ìgbọ́ràn sí i.
15
“Ní ìsinsin yìí, Olúwa Ọlọ́run wa, ẹni tí ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá, pẹ̀lú ọwọ́ agbára, tí ó fún ara rẹ̀ ní orúkọ tí ó wà títí di òní, a ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe búburú.
16
Olúwa, ní ìbámu pẹ̀lú ìwà òdodo rẹ, yí ìbínú àti ìrunú rẹ padà kúrò ní Jerusalẹmu ìlú u rẹ, òkè mímọ́ rẹ. Ẹ̀ṣẹ̀ wa àti àìṣedéédéé àwọn baba wa ti mú Jerusalẹmu àti ènìyàn rẹ di ẹ̀gàn fún gbogbo àwọn tí ó yí wọn ká.
17
“Nísinsin yìí, Ọlọ́run wa, gbọ́ àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ, nítorí i tìrẹ Olúwa, fi ojú àánú wo ibi mímọ́ rẹ tí ó ti dahoro.
18
Tẹ́ etí rẹ sílẹ̀, Ọlọ́run, kí o gbọ́; ya ojú rẹ sílẹ̀, kí o sì wo ìdahoro ìlú tí a ń fi orúkọ rẹ pè. Àwa kò gbé ẹ̀bẹ̀ wa kalẹ̀ níwájú u rẹ nítorí pé a jẹ́ olódodo, bí kò ṣe nítorí àánú ńlá rẹ.
19
Olúwa, fetísílẹ̀! Olúwa, dáríjì! Olúwa, gbọ́ kí o sì ṣe é! Nítorí i tìrẹ, Ọlọ́run mi, má ṣe pẹ́ títí, nítorí ìlú rẹ àti àwọn ènìyàn rẹ ń jẹ́ orúkọ mọ́ ọ lára.”

Kẹ́kọ̀ọ́ ẹsẹ wọ̀nyí

Àlàyé lórí gbogbo ẹsẹ wọ̀nyí, kì í ṣe ẹsẹ kan ṣoṣo

Ibi mìíràn tí Ìwé Mímọ́ ti sọ èyí

  • Jeremiah 33:3

    ‘Pè mí, èmi ó sì dá ọ lóhùn, èmi ó sì sọ ohun alágbára ńlá àti ọ̀pọ̀ ohun tí kò ṣe é wádìí tí ìwọ kò mọ̀ fún ọ.’
    láti ẹsẹ 3
  • Jeremiah 29:10

    Báyìí ni Olúwa wí: “Nígbà tí ẹ bá lo àádọ́rin ọdún pé ní Babeli, èmi yóò tọ̀ yín wá láti ṣe àmúṣẹ ìlérí ńlá mi fún un yín, àní láti kó o yín padà sí Jerusalẹmu.
    láti ẹsẹ 3
  • Jeremiah 29:13

    Ẹ̀yin yóò wá mi, bí ẹ̀yin bá sì fi gbogbo ọkàn yín wá mi: ẹ̀yin yóò rí mi ni Olúwa Ọlọ́run wí.
    láti ẹsẹ 3
  • Romu 8:28

    Àwa sì mọ̀ pé ohun gbogbo ni ó ń ṣiṣẹ́ pọ̀ sí rere fún àwọn tí ó fẹ́ Ọlọ́run, àní fún àwọn ẹni tí a pè gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ̀.
    láti ẹsẹ 4
  • Eksodu 20:6

    Èmi a sì máa fi àánú hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ó fẹ́ mi, tí wọ́n sì ń pa òfin mi mọ́.
    láti ẹsẹ 4
  • Jakọbu 5:16

    Ẹ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún ara yín, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún ara yín, kí a lè mú yín láradá. Iṣẹ́ tí àdúrà olódodo ń ṣe ní agbára púpọ̀.
    láti ẹsẹ 3
  • Jakọbu 5:18

    Ó sì tún gbàdúrà, ọ̀run sì tún rọ̀jò, ilẹ̀ sì so èso rẹ̀ jáde.
    láti ẹsẹ 3
  • Deuteronomi 5:10

    Èmi a sì máa fi àánú hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ó fẹ́ mi, tí wọ́n sì ń pa òfin mi mọ́.
    láti ẹsẹ 4
  • Efesu 1:6

    fún ìyìn ògo oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, èyí tí ò ti fi fún wa nínú Àyànfẹ́ rẹ̀.
    láti ẹsẹ 9
  • Efesu 1:8

    èyí tí ó fún wa lọ́pọ̀lọ́pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọgbọ́n àti ìmòye,
    láti ẹsẹ 9
  • Daniẹli 9:5

    Àwa ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe búburú. Àwa ti hu ìwà búburú, a sì ti ṣe ọ̀tẹ̀, a ti yí padà kúrò nínú àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà rẹ̀.
    láti ẹsẹ 4
  • Daniẹli 9:12

    Ìwọ ti mú ọ̀rọ̀ tí o sọ sí wa sẹ àti lórí àwọn alákòóso wa, nípa mímú kí ibi ńlá bá wa, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí lábẹ́ ọ̀run, bí ó ti ṣẹlẹ̀ sí Jerusalẹmu yìí.
    láti ẹsẹ 4
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options