Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Zoar: Not destroyed with Sodom and Gomorrah

5 ẹsẹ · 4 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Not destroyed with Sodom and Gomorrah

  1. Wò ó, ìlú kékeré kan nìyí ní tòsí láti sá sí: jẹ́ kí n sálọ síbẹ̀, ìlú kékeré ha kọ́? Ẹ̀mí mi yóò sì yè.”

  2. Ó sì wí fún un pé, “Ó dára, mo gba ẹ̀bẹ̀ rẹ. Èmi kì yóò run ìlú náà tí ìwọ sọ̀rọ̀ rẹ̀.

  3. Tètè! Sálọ síbẹ̀, nítorí èmi kò le ṣe ohun kan àyàfi tí ó bá dé ibẹ̀.” (ìdí nìyí tí a fi ń pe ìlú náà ní Soari).

  4. Nígbà tí Lọti yóò fi dé ìlú Soari, oòrùn ti yọ.

  5. Lọti àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin méjèèjì sì kúrò ní Soari, wọ́n sì ń lọ gbé ní orí òkè ní inú ihò àpáta, nítorí ó bẹ̀rù láti gbé ní ìlú Soari.