Horonaim
31.2800, 35.5100 Wo lórí Google Maps
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Horonaim
Ọkàn mi kígbe sókè lórí Moabu; àwọn ìsáǹsá rẹ sálà títí dé Soari, títí fi dé Eglati-Ṣeliṣi. Wọ́n gòkè lọ títí dé Luhiti wọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń lọ, ní òpópónà tí ó lọ sí Horonaimu wọ́n ń pohùnréré ìparun wọn.
Gbọ́ igbe ní Horonaimu, igbe ìrora àti ìparun ńlá.
Wọ́n gòkè lọ sí Luhiti, wọ́n ń sọkún kíkorò bí wọ́n ti ń lọ; ní ojú ọ̀nà sí Horonaimu igbe ìrora ìparun ni à ń gbọ́ lọ.
“Ohùn igbe wọn gòkè láti Heṣboni dé Eleale àti Jahasi, láti Soari títí dé Horonaimu àti Eglati-Ṣeliṣi, nítorí àwọn omi Nimrimu pẹ̀lú yóò gbẹ.