Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Vineyard

56 ẹsẹ · 9 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Òun sì ṣẹ́gun wọn, ó sì pa wọ́n ní à pa tán láti Aroeri títí dé agbègbè Minniti, ó jẹ́ ogún ìlú, títí dé Abeli-Keramimu. Báyìí ni Israẹli ti ṣẹ́gun àwọn ará Ammoni.

  2. Esri ọmọ Kelubu wà ní ìdí àwọn òṣìṣẹ́ lórí pápá, tí wọ́n ń ko ilẹ̀ náà.

  3. Ṣimei ará Ramoti wà ní ìdí àwọn ọgbà àjàrà. Sabdi ará Sifmi wà ní ìdí mímú jáde ti èso àjàrà fún ọpọ́n ńlá tí a ń fi ọ̀tún èso àjàrà sí.

  4. Baali-Hanani ará Gederi wà ní ìdí olifi àti àwọn igi sikamore ní apá ìhà ìwọ̀-oòrùn àwọn ní ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀. Joaṣi wà ní ìdí fífún ni ní òróró olifi.

  5. Mo kọjá níbi oko ọ̀lẹ, mo kọjá níbi ọgbà àjàrà aláìgbọ́n ènìyàn;

  6. ẹ̀gún ti hù ní ibi gbogbo, koríko ti gba gbogbo oko náà.

  7. Mo ṣe àwọn iṣẹ́ ńlá ńlá. Mo kọ́ ilé púpọ̀ fún ara mi, mo sì gbin ọgbà àjàrà púpọ̀.

  8. Mo gbẹ́ adágún láti máa bu omi rin àwọn igi tí ó ń hù jáde nínú ọgbà.

  9. Solomoni ní ọgbà àjàrà kan ní Baali-Hamoni ó gbé ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàtọ́jú olúkúlùkù ni ó ń mú èso rẹ̀ wá ẹgbẹ̀rún (1,000) fàdákà.

  10. Ṣùgbọ́n ọgbà àjàrà mi jẹ́ tèmi, ó wà fún mi; ẹgbẹ̀rún ṣékélì jẹ́ tìrẹ, ìwọ Solomoni, igba sì jẹ́ ti àwọn alágbàtọ́jú èso.

  11. Ọmọbìnrin Sioni ni a fi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àtíbàbà nínú ọgbà àjàrà, gẹ́gẹ́ bí abà nínú oko ẹ̀gúnsí, àti bí ìlú tí a dó tì.

  12. Èmi yóò kọrin fún ẹni tí mo fẹ́ràn orin kan nípa ọgbà àjàrà rẹ̀. Olùfẹ́ mi ní ọgbà àjàrà kan ní ẹ̀gbẹ́ òkè ẹlẹ́tù lójú.

  13. Ó tu ilẹ̀ rẹ̀, ó ṣa òkúta ibẹ̀ kúrò ó sì gbin àyànfẹ́ àjàrà sí i. Ó kọ́ ilé ìṣọ́ sí inú rẹ̀ ó sì ṣe ìfúntí kan síbẹ̀ pẹ̀lú. Lẹ́yìn náà, ó ń retí èso àjàrà dáradára, ṣùgbọ́n èso búburú ni ó ti ibẹ̀ wá.

  14. “Ní ìsinsin yìí ẹ̀yin olùgbé Jerusalẹmu àti ẹ̀yin ènìyàn Juda ẹ ṣe ìdájọ́ láàrín èmi àti ọgbà àjàrà mi.

  15. Kín ni ó kù tí n ò bá túnṣe sí ọgbà àjàrà mi. Ju èyí tí mo ti ṣe lọ? Nígbà tí mo ń wá èso dáradára, èéṣe tí ó fi so kíkan?

  16. Ní ìsinsin yìí, èmi yóò wí fún ọ ohun tí n ó ṣe sí ọgbà àjàrà mi. Èmi yóò gé igi inú rẹ̀ kúrò, a ó sì pa á run, Èmi yóò wó ògiri rẹ̀ lulẹ̀ yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀.

  17. Èmi yóò sì sọ ọ́ di ahoro láì kọ ọ́ láì ro ó, ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún ni yóò hù níbẹ̀. Èmi yóò sì pàṣẹ fún kurukuru láti má ṣe rọ̀jò sórí i rẹ̀.”

  18. Ọgbà àjàrà Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ilé Israẹli àwọn ọkùnrin Juda sì ni àyànfẹ́ ọgbà rẹ̀. Ó retí ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ṣùgbọ́n, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni ó rí. Òun ń retí òdodo ṣùgbọ́n ó gbọ́ ẹkún ìpayínkeke.

  19. Ní ọjọ́ náà, ni gbogbo ibi tí àjàrà tí ó tó ẹgbẹ̀rún (1,000) ṣékélì fàdákà, ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n nìkan ni yóò wà níbẹ̀.

  20. Ní ọjọ́ náà, “Kọrin nípa ọgbà àjàrà eléso kan.

  21. Èmi Olúwa ń bojútó o, Èmi ó bomirin ín láti ìgbàdégbà. Èmi ó ṣọ́ ọ tọ̀sán tòru kí ẹnikẹ́ni má ba à pa á lára.

  22. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùṣọ́-àgùntàn ni yóò sì ba ọgbà àjàrà mi jẹ́, tí wọn yóò sì tẹ oko mi mọ́lẹ̀; wọ́n ó sọ oko dídára mi di ibi tí a ń da ìdọ̀tí sí.

  23. “Nítorí ìjọba ọ̀run dàbí ọkùnrin tí ó jẹ́ baálé kan, tí ó jíjáde lọ ní kùtùkùtù òwúrọ̀, tí ó gba àwọn alágbàṣe sínú ọgbà àjàrà rẹ̀.

  24. Òun pinnu láti san dínárì kan fún iṣẹ́ òòjọ́ kan. Lẹ́yìn èyí ó sì rán wọn lọ sínú ọgbà àjàrà rẹ̀.

  25. “Ní wákàtí kẹta ọjọ́ bí ó ti ń kọjá níwájú ilé ìgbanisíṣẹ́, ó rí díẹ̀ nínú àwọn aláìríṣẹ́ tí wọ́n dúró ní ọjà.