Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Treasure: Money

8 ẹsẹ · 6 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Money

  1. Josẹfu pàṣẹ pé kí wọn bu ọkà kún inú àpò wọn, kí wọn sì mú owó ẹnìkọ̀ọ̀kan padà sínú àpò rẹ̀, kí wọn sì fún wọn ní ohun tí wọn yóò lò nírín-àjò wọn padà sílé. Lẹ́yìn ìgbà tí a ti ṣe èyí fún wọn,

  2. Níbi tí wọ́n ti dúró láti sùn lóru ọjọ́ náà, ọ̀kan nínú wọn tú àpò rẹ̀ láti mú oúnjẹ fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ó sì rí owó rẹ̀ ní ẹnu àpò rẹ̀.

  3. Ó sì wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “a ti dá owó mi padà, òun nìyí ní ẹnu àpò mi.” Ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì ń gbọ̀n, wọ́n sì wí pé, “Èwo nìyí tí Ọlọ́run ṣe sí wa yìí.”

  4. Bí wọ́n sì ti ń tú àpò ẹrù wọn, ẹnìkọ̀ọ̀kan bá owó tí ó san fún ọjà náà lẹ́nu àpò rẹ̀! Ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi, àwọn àti baba wọn.

  5. Ẹ̀rù sì ba àwọn ọkùnrin náà nígbà tí wọ́n mú wọn lọ sí ilé Josẹfu. Wọ́n rò ó pé, “A mú wa wá sí ìhín nítorí owó tí a fi sí inú àpò wa ní ìgbà àkọ́kọ́. Ó fẹ́ bá wa jà, kí ó mú wa lẹ́rú kí ó sì gba àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa.”

  6. Ṣùgbọ́n níbi tí a ti dúró ní ọ̀nà láti sùn ní alẹ́, nígbà tí a tú àpò oúnjẹ wa, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa bá owó oúnjẹ tirẹ̀ tí ó rà lẹ́nu àpò láì lé, láì dín. Nítorí náà òun nìyí, a ti mu un padà wá pẹ̀lú wa.

  7. A sì tún mú owó mìíràn lọ́wọ́ láti fi ra oúnjẹ. A ò mọ ẹni tí ó fi owó wa sí ẹnu àpò.”

  8. Ó sì wí fún wọn pé, “Àlàáfíà ni fún yín, ẹ má bẹ̀rù, Ọlọ́run yín, àní Ọlọ́run baba yín ni ó fi ìṣúra sí inú àpò yín; mo rí owó tí ẹ san gbà.” Nígbà náà ni ó mú Simeoni jáde tọ̀ wọ́n wá.