Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Sabbath

85 ẹsẹ · 63 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ní ọjọ́ keje Ọlọ́run sì parí iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ti ń ṣe; ó sì sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo tí ó ti ń ṣe.

  2. Ọlọ́run sì súre fún ọjọ́ keje, ó sì yà á sí mímọ́, nítorí pé ní ọjọ́ náà ni ó sinmi kúrò nínú iṣẹ́ dídá ayé tí ó ti ń ṣe.

  3. Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ: ‘Ọ̀la jẹ́ ọjọ́ ìsinmi, ìsinmi mímọ́ fún Olúwa. Ẹ yan èyí ti ẹ̀yin ní yan, kí ẹ sì bọ èyí ti ẹ̀yin ní bọ̀. Ẹ tọ́jú èyí ti ó kù sílẹ̀, kí ẹ pa á mọ́ di òwúrọ̀.’ ”

  4. Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ènìyàn kan jáde lọ ní ọjọ́ keje láti kó o, ṣùgbọ́n wọn kò ri nǹkan kan kó.

  5. Rántí ọjọ́ ìsinmi láti yà á sí mímọ́.

  6. Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò fi ṣiṣẹ́, kí ìwọ kí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ,

  7. ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi Olúwa Ọlọ́run rẹ: nínú rẹ̀ ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan: ìwọ, àti ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin, àti ẹran ọ̀sìn rẹ, àti àlejò rẹ, tí ń bẹ nínú ibodè rẹ.

  8. Nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni Olúwa dá ọ̀run àti ayé, òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn, ó sì sinmi ní ọjọ́ keje: nítorí náà ni Olúwa ṣe bùkún ọjọ́ ìsinmi tí ó sì yà á sí mímọ́.

  9. “Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò ṣe iṣẹ́ rẹ, ìwọ yóò sì sinmi ní ọjọ́ keje, kí akọ màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ bá à lè ní ìsinmi, kí a sì tú ọmọ ìránṣẹ́bìnrin rẹ àti àlejò ti ń gbé ni ilé rẹ lára.

  10. “Kí ìwọ kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ẹ̀yin gbọdọ̀ máa pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́. Èyí ni yóò jẹ́ àmì láàrín Èmi àti ẹ̀yin fún ìrandíran tó ń bọ̀, nítorí kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé Èmi ni Olúwa, ẹni tí ó yà yín sí mímọ́.

  11. “ ‘Nítorí náà, kí ẹ̀yin kí ó máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, nítorí mímọ́ ni fún un yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá bà á jẹ́, ni a yóò pa; ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà ni a yóò gé kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ.

  12. Ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ní ọjọ́ ìsinmi tí ẹ̀yin yóò fi sinmi, mímọ́ ni fún Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ni a ó pa nítòótọ́.

  13. Nítorí náà ni àwọn ọmọ Israẹli yóò ṣe máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, ẹ máa ṣe àkíyèsí rẹ̀ dé ìrandíran tó ń bọ̀ bí i májẹ̀mú títí láé.

  14. Yóò jẹ́ àmì láàrín Èmi àti àwọn ọmọ Israẹli títí láé, nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni Olúwa dá ọ̀run àti ayé, àti ní ọjọ́ keje ni ó fi iṣẹ́ sílẹ̀, ó sì sinmi.’ ”

  15. “ ‘Ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ bọ̀wọ̀ fún ìyá àti baba rẹ̀, kí ẹ sì ya ọjọ́ ìsinmi mi sí mímọ́. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

  16. “ ‘Ẹ gbọdọ̀ máa pa ìsinmi mi mọ́ kí ẹ sì fi ọ̀wọ̀ fún ibi mímọ́ mi. Èmi ni Olúwa.

  17. “ ‘Ọjọ́ mẹ́fà ni ẹ le fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi. Ọjọ́ àjọ̀dún tí a yàn. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé. Ọjọ́ ìsinmi Olúwa ni.

  18. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli wà nínú aginjù, wọ́n rí ọkùnrin kan tí ń ṣá igi ní ọjọ́ Ìsinmi.

  19. Àwọn tó sì rí i níbi tó ti ń ṣá igi wọ́n sì mú un wá sí ọ̀dọ̀ Mose àti Aaroni àti síwájú gbogbo ìjọ ènìyàn,

  20. wọ́n fi sí ìpamọ́ nítorí pé ohun tí wọn ó ṣe fún un kò tí ì yé wọn.

  21. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Kíkú ni ọkùnrin náà yóò kú kí gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli sọ ọ́ lókùúta pa ní ẹ̀yìn ibùdó.”

  22. Wọ́n mú un jáde sí ẹ̀yìn ibùdó, gbogbo ìjọ ènìyàn sì sọ ọ́ lókùúta pa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  23. “ ‘Ní ọjọ́ ìsinmi, pèsè akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méjì ọlọ́dún kan tí kò lábùkù, pẹ̀lú ẹbọ ohun mímu àti ẹbọ ohun jíjẹ tí i ṣe ìdá méjì nínú ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò.

  24. Ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi Olúwa Ọlọ́run rẹ: nínú rẹ̀ ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan: ìwọ, àti ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin, àti akọ màlúù rẹ, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ, àti ohun ọ̀sìn rẹ kan, àti àlejò tí ń bẹ nínú ibodè rẹ; kí ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin kí ó lè sinmi gẹ́gẹ́ bí ìwọ.

  25. Sì rántí pé, ìwọ ti jẹ́ ẹrú ní Ejibiti rí, àti pé Olúwa Ọlọ́run rẹ yọ ọ́ kúrò níbẹ̀ pẹ̀lú agbára ńlá, àti nína ọwọ́ rẹ̀. Torí èyí ni Olúwa Ọlọ́run rẹ ṣe pàṣẹ fún ọ láti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́.