Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Sabbath: Pollute

3 ẹsẹ · 63 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Pollute

  1. Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣe èyí, àti fún ọmọ ènìyàn tí ó dìímú ṣinṣin, tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́, tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi ṣíṣe.”

  2. “ ‘Síbẹ̀; ilé Israẹli ṣọ̀tẹ̀ sí mí nínú aginjù. Wọn kò tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn sì kọ àwọn òfin mi sílẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó bá pa á mọ́ yóò yè nínú rẹ̀. Wọn sì sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́ lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Nítorí náà, mo sọ pé èmi yóò tú ìbínú gbígbóná mi sórí wọn, èmi yóò sì pa wọ́n run nínú aginjù.

  3. Nítorí pé, wọn kọ òfin mi sílẹ̀, wọn kò sì tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn sọ ọjọ́ ìsinmi mi dí aláìmọ́. Nítorí pé tọkàntọkàn ni wọn ń tẹ̀lé òrìṣà wọn.