Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Righteousness of God

73 ẹsẹ · 46 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Jẹ́ kí ahọ́n mi kọ orin ọ̀rọ̀ rẹ, nítorí gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òdodo.

  2. Saamu ti Dafidi. Olúwa gbọ́ àdúrà mi, fetísí igbe mi fún àánú; nínú òtítọ́ àti òdodo rẹ, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi.

  3. Nítorí orúkọ rẹ, Olúwa, sọ mi di ààyè; nínú òdodo rẹ, mú ọkàn mi jáde nínú wàhálà.

  4. Wọn yóò ṣe ìrántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà rere rẹ àti orin ayọ̀ òdodo rẹ.

  5. Olúwa jẹ́ olódodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀ àti ìfẹ́ rẹ̀ sí gbogbo ohun tí o dá.

  6. Nítorí náà má bẹ̀rù, nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ; má ṣe jẹ́ kí àyà kí ó fò ọ́, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Èmi yóò fún ọ lókun èmi ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́. Èmi ó gbé ọ ró pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi.

  7. Ẹ jẹ́ kí ẹni tí ń ṣògo nípa èyí nì wí pé: òun ní òye, òun sì mọ̀ mí wí pé, Èmi ni Olúwa tí ń ṣe òtítọ́, ìdájọ́ àti òdodo ní ayé, nínú èyí ni mo ní inú dídùn sí,” Olúwa wí.

  8. Olúwa, olódodo ni ọ́ nígbàkígbà, nígbà tí mo mú ẹjọ́ kan tọ̀ ọ́ wá. Síbẹ̀ èmi yóò bá ọ sọ̀rọ̀ nípa òdodo rẹ. Èéṣe tí ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú fi ń ṣe déédé? Èéṣe tí gbogbo àwọn aláìṣòdodo sì ń gbé ní ìrọ̀rùn?

  9. “Olúwa ìwọ ni olódodo, ṣùgbọ́n báyìí ìtìjú dé bá àwọn ènìyàn Juda, àwọn ènìyàn Jerusalẹmu àti gbogbo Israẹli ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti fọ́n wa ká sí nítorí àìṣòótọ́ ọ wa sí ọ.

  10. Olúwa, ní ìbámu pẹ̀lú ìwà òdodo rẹ, yí ìbínú àti ìrunú rẹ padà kúrò ní Jerusalẹmu ìlú u rẹ, òkè mímọ́ rẹ. Ẹ̀ṣẹ̀ wa àti àìṣedéédéé àwọn baba wa ti mú Jerusalẹmu àti ènìyàn rẹ di ẹ̀gàn fún gbogbo àwọn tí ó yí wọn ká.

  11. Nítorí èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá, mo sì rà yín padà láti ilẹ̀ ẹrú wá. Mo rán Mose láti darí yín, bákan náà mo rán Aaroni àti Miriamu síwájú rẹ̀.

  12. Ìwọ ènìyàn mi, rántí ohun tí Balaki ọba Moabu gbèrò àti ohun tí Balaamu ọmọ Beori dáhùn. Rántí ìrìnàjò rẹ̀ láti Ṣittimu dé Gilgali, kí ìwọ ba le mọ òdodo Olúwa.”

  13. Nítorí èmi ti dẹ́ṣẹ̀ sí i, èmi yóò faradà ìbínú Olúwa, títí òun yóò ṣe gba ẹjọ́ mi rò, tí yóò sì ṣe ìdájọ́ mi. Òun yóò sì mú mi wá sínú ìmọ́lẹ̀; èmi yóò sì rí òdodo rẹ̀.

  14. “Baba olódodo, ayé kò mọ̀ ọ́n; ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n, àwọn wọ̀nyí sì mọ̀ pé ìwọ ni ó rán mi.

  15. Níwọ́n bí ó ti dá ọjọ́ kan, nínú èyí tí yóò ṣe ìdájọ́ ayé lódodo nípasẹ̀ ọkùnrin náà tí ó ti yàn, nígbà tí ó ti fi ohun ìdánilójú fún gbogbo ènìyàn, ní ti pé ó jí dìde kúrò nínú òkú.”

  16. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí líle àti àìronúpìwàdà ọkàn rẹ̀, ìwọ ń to ìbínú jọ fún ara rẹ de ọjọ́ ìbínú àti ìfihàn ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run.

  17. Ẹni tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ láti jẹ́ ètùtù nípa ìgbàgbọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, láti fi òdodo rẹ̀ hàn nítorí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti kọjá, nínú ìpamọ́ra Ọlọ́run,

  18. láti fi òdodo rẹ̀ hàn ní ìgbà ìsinsin yìí: kí ó lè jẹ́ olódodo àti olùdáláre ẹni tí ó gba Jesu gbọ́.

  19. Olódodo ni Ọlọ́run: Òun yóò pọ́n àwọn tí ń pọ́n yín lójú, lójú,

  20. Ẹni, nígbà tí a kẹ́gàn rẹ̀, tí kò sì padà kẹ́gàn; nígbà tí ó jìyà tí kò sì halẹ̀; ṣùgbọ́n ó fi ọ̀ràn rẹ̀ lé ẹni ti ń ṣe ìdájọ́ òdodo lọ́wọ́.

  21. Mo sì gbọ́ angẹli tí ó n wí pé: “Olódodo ni ìwọ ninu gbogbo ìdájọ́ wọ̀nyí, ìwọ ẹni tí ó n bẹ àti tí ó tí wa, Ẹni Mímọ́ nítorí tí ìwọ ṣe ìdájọ́ bẹ́ẹ̀.

  22. Mo sì gbọ́ ti pẹpẹ ń ké wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè, òtítọ́ àti òdodo ní ìdájọ́ rẹ.”

  23. nítorí òtítọ́ àti òdodo ni ìdájọ́ rẹ̀. Nítorí o ti ṣe ìdájọ́ àgbèrè ńlá a nì, tí o fi àgbèrè rẹ̀ ba ilẹ̀ ayé jẹ́, ó sì ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ náà.”