Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Punishment of the Wicked: Hell
Àwọn ẹsẹ nípa Hell
Àwọn ènìyàn búburú ni a ó dà sí isà òkú, àti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó gbàgbé Ọlọ́run.
Bí ojú ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ jáde, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sá à ní èrè fún ọ kí ẹ̀yà ara rẹ kan ṣègbé, ju kí a gbé gbogbo ara rẹ jù sí iná ọ̀run àpáàdì.
Ṣùgbọ́n èmi ó sì sọ ẹni tí ẹ̀yin ó bẹ̀rù fún yín: Ẹ bẹ̀rù ẹni tí ó lágbára lẹ́yìn tí ó bá pànìyàn tan, láti wọ́ ni lọ sí ọ̀run àpáàdì. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín òun ni kí ẹ bẹ̀rù.
Ní ipò òkú ni ó gbé ojú rẹ̀ sókè, ó ń bẹ nínú ìjìyà oró, ó sì rí Abrahamu ní òkèrè, àti Lasaru ní oókan àyà rẹ̀.