Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Moon: Worshipped as the queen of heaven

5 ẹsẹ · 29 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Worshipped as the queen of heaven

  1. Àwọn ọmọ ṣa igi jọ, àwọn baba fi iná sí i, àwọn ìyá sì po ìyẹ̀fun láti ṣe àkàrà fún ayaba ọ̀run, wọ́n tú ẹbọ ọrẹ mímu sí àwọn ọlọ́run àjèjì láti ru bínú mi sókè.

  2. Dájúdájú, à ó ṣe gbogbo nǹkan tí a sọ pé à ò ṣe. A ó sun tùràrí sí ayaba ọ̀run, à ó sì da ohun mímu sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sí àwa àti àwọn baba wa, àwọn ọba àti àwọn aláṣẹ ti ṣe ní àwọn ìlú Juda àti ni àwọn ìgboro Jerusalẹmu. Nígbà náà àwa ní oúnjẹ púpọ̀, a sì ṣe rere a kò sì rí ibi.

  3. Ṣùgbọ́n láti ìgbà tí a ti dáwọ́ tùràrí sísun sí Ayaba Ọ̀run àti láti da ẹbọ ohun mímu fún un, àwa ti ṣaláìní ohun gbogbo, a sì run nípa idà àti nípa ìyàn.”

  4. Àwọn obìnrin náà fi kún un pé, “Nígbà tí à ń jó tùràrí sí ayaba ọ̀run, tí a sì ń fi ohun mímu rú ẹbọ si; ǹjẹ́ àwọn ọkọ wa kò mọ pé àwa ń ṣe àkàrà bí i, àwòrán rẹ, àti wí pé à ń da ọtí si gẹ́gẹ́ bi ohun ìrúbọ?”

  5. Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí. Ìwọ àti àwọn ìyàwó rẹ fihàn pẹ̀lú àwọn ìhùwà rẹ àti àwọn ohun tí ó ṣèlérí nígbà tí o wí pé, ‘Àwa yóò mú ẹ̀jẹ́ tí a jẹ́ ṣẹ lórí sísun tùràrí àti dída ẹbọ ohun mímu sí orí ère Ayaba Ọ̀run.’ “Tẹ̀síwájú nígbà náà, ṣe ohun tí o sọ, kí o sì mú ẹ̀jẹ́ rẹ ṣẹ.