Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Macedonian Empire

39 ẹsẹ · 13 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Ẹni tí kò níláárí kan yóò rọ́pò rẹ̀, ẹni tí a kò tí ì fi ọlá ọba fún rí. Yóò sì gbógun sí ìjọba nígbà tí ọkàn àwọn ènìyàn balẹ̀ láìbẹ̀rù, yóò sì gbà á pẹ̀lú àrékérekè.

  2. Nígbà náà, ni a ó gbà ogunlọ́gọ̀ ogun kúrò níwájú u rẹ̀, pẹ̀lú òun àti ọmọ-aládé ti májẹ̀mú náà ni a ó parun.

  3. Lẹ́yìn tí ó wá ṣe ìpinnu pẹ̀lú u rẹ̀, yóò hùwà ẹ̀tàn, pẹ̀lú ìwọ̀nba ènìyàn kékeré ni yóò gba ìjọba.

  4. Nígbà tí àwọn agbègbè tí ó lọ́rọ̀ gidigidi wà láìbẹ̀rù ni yóò gbóguntì wọ́n, yóò ṣe ohun tí baba rẹ̀ tàbí baba ńlá rẹ̀ kò ṣe rí, yóò pín ìkógun ẹrù àti ọrọ̀ fún àwọn ọmọ lẹ́yìn in rẹ̀. Yóò pète àti bi àwọn ìlú olódi ṣubú, ṣùgbọ́n fún ìgbà díẹ̀ ni.

  5. “Pẹ̀lú ogun púpọ̀, yóò sì ru agbára rẹ̀ àti ìgboyà rẹ̀ sókè sí ọba gúúsù. Ọba gúúsù yóò dìde ogun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ-ogun tí ó lágbára gidigidi, ṣùgbọ́n kò ní le è dúró, nítorí ọ̀tẹ̀ tí ó gbèrò sí i.

  6. Àwọn tí ó jẹ nínú oúnjẹ ọba yóò gbìyànjú láti parun, a ó gbá ogun rẹ̀ dànù, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò ṣubú sí ogun.

  7. Àwọn ọba méjèèjì, ọkàn wọn tẹ̀ sí búburú, wọn yóò jókòó lórí tábìlì kan, wọn yóò máa parọ́ sí ara wọn, ṣùgbọ́n kò ní yọrí sí nǹkan kan nítorí òpin yóò wá ní àsìkò tí a yàn.

  8. Ọba àríwá yóò padà sí ilẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀, ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ yóò lòdì sí májẹ̀mú mímọ́, yóò sì ṣiṣẹ́ lòdì sí i, yóò sì padà sí orílẹ̀-èdè òun fúnra rẹ̀.

  9. “Ní àsìkò tí a yàn, yóò gbógun sí gúúsù lẹ́ẹ̀kan sí i, ṣùgbọ́n ní ìgbà yí àyọríṣí yóò yàtọ̀ sí ti ìṣáájú.

  10. Pẹ̀lúpẹ̀lú, ará, àwa ń sọ fún yín ní ti oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fífún àwọn ìjọ Makedonia.

  11. Bí ó ti jẹ́ pé a dán wọn wò nípa ìpọ́njú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ àti àìlódiwọ̀n àìní wọn ti kún àkúnwọ́sílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ ìlawọ́ wọn.

  12. Nítorí mo jẹ́rìí pé gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, àní ju agbára wọn, wọ́n ṣe é láti ìfẹ́ inú ara wọn.

  13. Wọ́n ń fi ẹ̀bẹ̀ púpọ̀ rọ̀ wá ní ti ẹ̀bùn àtinúwá yìí, láti ba à lè ní ìpín nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn mímọ́.

  14. Àti èyí, kì í ṣe bí àwa tí rò rí, ṣùgbọ́n wọ́n tètè kọ́ fi àwọn fúnra wọn fún Olúwa, àti fún wá, nípa ìfẹ́ Ọlọ́run.