Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Stability of Character

16 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Ọkàn mi ti múra Ọlọ́run; ọkàn mi ti múra, èmi ó kọrin, èmi ó si máa kọrin ìyìn.

  2. Orin. Saamu ti Dafidi. Ọlọ́run, ọkàn mi dúró ṣinṣin èmi ó máa kọrin, èmi ó máa fi ọkàn mi kọrin.

  3. Òun kì yóò béèrè ìyìn búburú: ọkàn rẹ̀ ti dúró, ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa.

  4. Gbogbo ènìyàn yóò sì kórìíra yín nítorí mi, ṣùgbọ́n gbogbo ẹni tí ó bá dúró ṣinṣin dé òpin ni a ó gbàlà.

  5. ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá forítì í dópin ni a ó gbàlà.

  6. Ṣùgbọ́n àwọn tí ó bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, ní àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì gbà á lóòtítọ́, wọ́n sì mú èso púpọ̀ jáde fún Ọlọ́run ní ọgbọọgbọ̀n, ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún, gẹ́gẹ́ bí a ti gbìn ín sí ọkàn wọn.”

  7. Ó yẹ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan máa ṣe iṣẹ́ tí ó ń ṣe tẹ́lẹ̀, kí Ọlọ́run tó pé é sínú ìgbàgbọ́ nínú Kristi.

  8. Nítorí náà ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ ẹ máa dúró ṣinṣin, láìyẹsẹ̀, kí ẹ máa pọ̀ si í ní iṣẹ́ Olúwa nígbà gbogbo, ní ìwọ̀n bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé iṣẹ́ yin kì í ṣe asán nínú Olúwa.

  9. Nítorí náà ará, ẹ dúró ṣinṣin, kí ẹ sì di àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀n-ọn-nì tí a kọ́ yín mú, yálà nípa ọ̀rọ̀ ẹnu tàbí lẹ́tà.

  10. Ṣùgbọ́n olódodo ni Olúwa, ẹni tí yóò fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, tí yóò sì pa yín mọ́ kúrò nínú ibi.

  11. Ẹ jẹ́ kí a di ìjẹ́wọ́ ìrètí wa mu ṣinṣin ni àìṣiyèméjì, nítorí pé olóòtítọ́ ní ẹni tí o ṣe ìlérí.

  12. Ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi onírúurú àti àjèjì ẹ̀kọ́ gbá yin kiri. Nítorí ó dára kí a mú yin lọ́kàn le nípa oore-ọ̀fẹ́, kì í ṣe nípa oúnjẹ nínú èyí tí àwọn tí ó ti rìn nínú wọn kò ní èrè.

  13. Nítorí bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí kò sì jẹ́ olùṣe, òun dàbí ọkùnrin tí ó ń ṣàkíyèsí ojú ara rẹ̀ nínú dígí

  14. nítorí, lẹ́yìn tí ó bá ti ṣàkíyèsí ara rẹ̀, tí ó sì bá tirẹ̀ lọ, lójúkan náà òun sì gbàgbé bí òun ti rí.

  15. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé, òfin òmìnira ni, tí ó sì dúró nínú rẹ̀, tí òun kò sì jẹ́ olùgbọ́ tí ń gbàgbé bí kò ṣe olùṣe rẹ̀, òun yóò jẹ́ alábùkún nínú iṣẹ́ rẹ̀.

  16. Ẹni tí ń ṣe aláìṣòótọ́, kí ó máa ṣe aláìṣòótọ́ nì só; àti ẹni tí ń ṣe ẹlẹ́gbin, kí ó máa ṣe ẹ̀gbin nì só; àti ẹni tí ń ṣe olódodo, kí ó máa ṣe òdodo nì só; àti ẹni tí ń ṣe mímọ́, kí ó máa ṣe mímọ́ nì só.”