Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Sorcery

47 ẹsẹ · 11 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Má ṣe jẹ́ kí àjẹ́ kí ó wà láààyè.

  2. “ ‘Ẹ má ṣe jẹ ẹrankẹ́ran pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. “ ‘Ẹ kò gbọdọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ yẹ̀míwò tàbí oṣó.

  3. “ ‘Ẹ má ṣe dá òṣù sí àárín orí yín (fífá irun ẹ̀gbẹ́ orí, tí a ó sì dá irun àárín orí sí) tàbí kí ẹ ré orí irùngbọ̀n yín bí àwọn aláìkọlà ti ń ṣe.

  4. “ ‘Ẹ má ṣe tìtorí òkú, gé ibi kankan nínú ẹ̀yà ara yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ sín gbẹ́rẹ́ kankan. Èmi ni Olúwa.

  5. “ ‘Ẹ má ṣe tọ abókùúsọ̀rọ̀ tàbí àwọn àjẹ́ lọ, ẹ kò gbọdọ̀ tọ̀ wọ́n lẹ́yìn láti jẹ́ kí wọ́n sọ yín di aláìmọ́. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

  6. “ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá tọ àwọn abókùúsọ̀rọ̀ àti àwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn lọ, tí ó sì ṣe àgbèrè tọ̀ wọ́n lẹ́yìn, Èmi yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀, Èmi yóò sì gé e kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.

  7. “ ‘Ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó jẹ́ abókùúsọ̀rọ̀ tàbí oṣó láàrín yín ni kí ẹ pa. Ẹ sọ wọ́n ní òkúta, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.’ ”

  8. Wòlíì náà tàbí alálàá náà ni kí ẹ pa, nítorí pé wàásù ìṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú yín jáde láti Ejibiti wá, tí ó sì rà yín padà lóko ẹrú. Ó ti gbìyànjú láti fà yín kúrò lójú ọ̀nà tí Olúwa Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún un yín láti máa rìn. Ẹ gbọdọ̀ yọ ibi náà kúrò láàrín yín.

  9. Nígbà tí o bá wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ, ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ láti tẹ̀lé àwọn ọ̀nà ìríra àwọn orílẹ̀-èdè náà tí ó wà níbẹ̀.

  10. Má ṣe jẹ́ kí a rí ẹnikẹ́ni láàrín yín tí ó fi ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ̀ obìnrin la iná já (fi ọmọ rẹ rú ẹbọ) kí ẹnikẹ́ni má ṣe lọ fọ àfọ̀ṣẹ, tàbí ṣẹ́ oṣó, tàbí túmọ̀ àwọn àmì nǹkan tí ń bọ̀, tàbí àjẹ́,

  11. tàbí afògèdè, tàbí jẹ́ a bá iwin gbìmọ̀ tàbí oṣó tàbí abókùúsọ̀rọ̀.

  12. Ẹnikẹ́ni tó bá ṣe nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ìríra sí Olúwa, àti nítorí àwọn ìwà ìríra wọ̀nyí ni Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fi lé àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí jáde kúrò níwájú rẹ.

  13. O ní láti jẹ́ aláìlẹ́gàn níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ.

  14. Àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ yóò gba ilẹ̀ tí wọ́n ń gbé, wọ́n fetí sí tí àwọn tí ó ń ṣe oṣó tàbí ṣe àfọ̀ṣẹ. Ṣùgbọ́n, ní ti ìwọ, Olúwa Ọlọ́run rẹ kò fi ààyè gbà ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

  15. Nítorí pé ìṣọ̀tẹ̀ dàbí ẹ̀ṣẹ̀ àfọ̀ṣẹ, àti ìgbéraga bí ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà. Nítorí tí ìwọ ti kọ ọ̀rọ̀ Olúwa, Òun sì ti kọ̀ ọ́ ní ọba.”

  16. Saulu sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ bá mi wá obìnrin kan tí ó ní ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ èmi yóò sì tọ̀ ọ́ lọ, èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Wò ó, obìnrin kan wà ní Endori tí ó ní ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀.”

  17. Saulu sì pa ara dà, ó sì mú aṣọ mìíràn wọ̀, ó sì lọ, àwọn ọmọkùnrin méjì sì pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ obìnrin náà lóru: òun sì wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, fi ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ wo nǹkan fún mi, kí o sì mú ẹni tí èmí ó dárúkọ rẹ̀ fún ọ wá sókè fún mi.”

  18. Obìnrin náà sì dá a lóhùn pé, “Wò ó, ìwọ sá à mọ ohun tí Saulu ṣe, bí òun ti gé àwọn abókùúsọ̀rọ̀ obìnrin, àti àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ọkùnrin kúrò ní ilẹ̀ náà; ǹjẹ́ èéha ṣe tí ìwọ dẹkùn fún ẹ̀mí mi, láti mú kí wọ́n pa mí.”

  19. Saulu sì búra fún un nípa Olúwa pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láààyè, ìyà kan kì yóò jẹ́ ọ́ nítorí nǹkan yìí.”

  20. Obìnrin náà sì bi í pé, “Ta ni ẹ̀mí ó mú wá sókè fún ọ?” Òun sì wí pé, “Mú Samuẹli gòkè wá fún mi.”

  21. Nígbà tí obìnrin náà sì rí Samuẹli, ó kígbe lóhùn rara: obìnrin náà sì bá Saulu sọ̀rọ̀ pè, “Èéṣe tí ìwọ fi tàn mí jẹ? Nítorí pé Saulu ni ìwọ jẹ́.”

  22. Ọba sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù; kín ni ìwọ rí?” Obìnrin náà sì wí fún Saulu pé, “Èmi rí ọlọ́run kan tí ń ti ilẹ̀ wá.”

  23. Ó sì bi í pé, “Báwo ni ó ti rí i sí.” Ó sì wí pé, “Ọkùnrin arúgbó kan ni ó ń bọ; ó sì fi agbádá bora.” Saulu sì mọ̀ pé, Samuẹli ni; ó sì tẹríba, ó sì wólẹ̀.

  24. Samuẹli sì i wí fún Saulu pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń yọ mí lẹ́nu láti mú mi wá sókè?” Saulu sì dáhùn ó sì wí pé, “Ìpọ́njú ńlá bá mi; nítorí tí àwọn Filistini ń bá mi jagun, Ọlọ́run sì kọ̀ mí sílẹ̀, kò sì dá mi lóhùn mọ́, nípa ọwọ́ àwọn wòlíì, tàbí nípa àlá; nítorí náà ni èmi ṣe pè ọ́, kí ìwọ lè fi ohun tí èmi yóò ṣe hàn mi.”

  25. Samuẹli sì wí pé, “Ó ti ṣe ń bi mí léèrè nígbà tí ó jẹ́ pé, Olúwa ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, o sì di ọ̀tá rẹ̀.