Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Satan

135 ẹsẹ · 4 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. A sì lé dragoni ńlá náà jáde, ejò láéláé nì, tí a ń pè ni Èṣù, àti Satani, tí ń tan gbogbo ayé jẹ: a sì lé e jù sí ilẹ̀ ayé, a sì lé àwọn angẹli rẹ̀ jáde pẹ̀lú rẹ̀.

  2. Mo sì gbọ́ ohùn ńlá ní ọ̀run, wí pè: “Nígbà yìí ni ìgbàlà dé, àti agbára, àti ìjọba Ọlọ́run wá, àti ọlá àti Kristi rẹ̀. Nítorí a tí le olùfisùn àwọn arákùnrin wa jáde, tí o ń fi wọ́n sùn níwájú Ọlọ́run wa lọ́sàn án àti lóru.

  3. Wọ́n sì ti ṣẹ́gun rẹ̀ nítorí ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́-àgùntàn náà, àti nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀rí wọn, wọn kò sì fẹ́ràn ẹ̀mí wọn àní títí dé ikú.

  4. Nítorí náà ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn. Ègbé ni fún ayé àti Òkun; nítorí èṣù sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá ní ìbínú ńlá, nítorí ó mọ̀ pé ìgbà kúkúrú sá ni òun ní.”

  5. Mo sì rí angẹli kan ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, ti òun ti kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun, àti ẹ̀wọ̀n ńlá kan ní ọwọ́ rẹ̀.

  6. O sì di dragoni náà mú, ejò àtijọ́ nì, tí í ṣe èṣù, àti Satani, ó sì dè é ní ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún.

  7. Ó sì gbé e sọ sínú ọ̀gbun náà, ó sì tì í, ó sì fi èdìdì dì í lórí rẹ̀, kí ó má ba à tan àwọn orílẹ̀-èdè jẹ mọ́ títí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún náà yóò fi pé. Lẹ́yìn èyí, a kò le ṣàì tú u sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.

  8. Nígbà tí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún náà bá sì pé, a ó tú Satani sílẹ̀ kúrò nínú túbú rẹ̀.

  9. Yóò sì jáde lọ láti máa tan àwọn orílẹ̀-èdè tí ń bẹ ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé jẹ, Gogu àti Magogu, láti gbá wọn jọ sí ogun: àwọn tí iyè wọn dàbí iyanrìn Òkun.

  10. A sì wọ́ Èṣù tí ó tàn wọ́n jẹ lọ sínú adágún iná àti sulfuru, níbi tí ẹranko àti wòlíì èké nì gbé wà, a ó sì máa dá wọn lóró tọ̀sán tòru láé àti láéláé.