- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Rulers
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Síwájú sí i, ọba náà kò gbọdọ̀ kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹṣin jọ fún ara rẹ̀, tàbí kí ó rán àwọn ènìyàn náà padà sí Ejibiti láti wá àwọn ẹṣin sí i, nítorí pé Olúwa ti sọ fún un yín pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ tún padà lọ ní ọ̀nà náà mọ́.”
Kò gbọdọ̀ kó aya jọ, kí ọkàn rẹ̀ má bá a yapa kúrò. Kò gbọdọ̀ kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara rẹ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀.
Nígbà tí ó bá jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, kí ó ṣe àdàkọ àwọn òfin wọ̀nyí sí inú ìwé fún ara rẹ̀, láti inú ti àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi.
Èyí yóò sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀, òun ó sì máa kà nínú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, kí ó lè máa kọ́ àti bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, láti máa tẹ̀lé gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí àti àwọn ìlànà rẹ̀ tọkàntọkàn.
Kí ó má ba à lérò pé òun sàn ju àwọn arákùnrin rẹ̀ yòókù lọ, kí ó sì ti ipa bẹ́ẹ̀ yípadà kúrò nínú òfin wọ̀nyí sí ọ̀tún tàbí sí òsì. Bẹ́ẹ̀ ni òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jẹ ọba pẹ́ títí ní Israẹli.
Àwọn adájọ́ gbọdọ̀ ṣe ìwádìí fínní fínní bí ẹ̀rí bá sì jẹ́ irọ́, tí ó fi ẹ̀rí èké sun arákùnrin rẹ̀,
nígbà náà ni kí ó ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ṣe fẹ́ ṣe sí arákùnrin rẹ̀. O ní láti wẹ búburú kúrò láàrín rẹ.
Baba kò gbọdọ̀ kú fún àwọn ọmọ wọn tàbí kí àwọn ọmọ kú fún baba wọ́n; olúkúlùkù ní láti kú fún ẹ̀ṣẹ̀ òun tìkára rẹ̀.
Nígbà tí àwọn ènìyàn méjì bá ń jà, kí wọn kó ẹjọ́ lọ sí ilé ìdájọ́, kí àwọn onídàájọ́ dá ẹjọ́ náà, kí wọn dá àre fún aláre àti ẹ̀bi fún ẹlẹ́bi.
“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí ìdájọ́ po fún àlejò, aláìní baba tàbí opó.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
Jẹ́ alágbára, kí o sì mú àyà le gidigidi. Kí o sì ṣọ́ra láti pa gbogbo òfin tí Mose ìránṣẹ́ mi fún ọ mọ́, má ṣe yà kúrò nínú u rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì, kí ìwọ kí ó lè ṣe rere níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ.
Má ṣe jẹ́ kí ìwé òfin yìí kúrò ní ẹnu rẹ, máa ṣe àṣàrò nínú u rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, kí ìwọ kí ó lè ṣọ́ra láti ṣe gbogbo nǹkan tí a kọ sí inú u rẹ̀. Nígbà náà ni yóò dára fún ọ, ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí.
Samuẹli sọ gbogbo ọ̀rọ̀ Olúwa sí àwọn ọmọ ènìyàn tí ó ń béèrè fún ọba lọ́wọ́ rẹ̀.
Ó wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba tí yóò jẹ lórí yín yóò ṣe. Yóò kó àwọn ọmọkùnrin yín, yóò sì mú wọn ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti fún ẹlẹ́ṣin rẹ, wọn yóò sì máa sáré níwájú kẹ̀kẹ́ rẹ̀.
Yóò yan díẹ̀ láti jẹ́ olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti olórí àádọ́ta àti àwọn mìíràn. Yóò yan wọ́n láti máa tulẹ̀ oko rẹ̀ àti láti máa kórè rẹ̀ àti àwọn mìíràn láti máa ṣe ohun èlò ogun àti ohun èlò kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀.
Yóò mú àwọn ọmọbìnrin yín láti máa ṣe olùṣe ìkunra olóòórùn dídùn àti láti máa ṣe àsè àti láti máa ṣe àkàrà.
Yóò mú èyí tí ó dára jù nínú oko yín, àti nínú ọgbà àjàrà yín àti nínú igi olifi yín, yóò sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀.
Yóò mú ìdásímẹ́wàá hóró ọkà yín àti àká èso àjàrà yín, yóò sì fi fún àwọn oníṣẹ́ àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀.
Àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin yín àti èyí tí ó dára jù nínú ẹran ọ̀sìn àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín ni yóò mú fún ìlò ti ara rẹ̀.
Yóò sì mú ìdámẹ́wàá nínú àwọn agbo ẹran yín, yóò sì máa ṣe ẹrú u rẹ̀.
Tí ọjọ́ náà bá dé, ẹ̀yin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ ọba tí ẹ̀yin ti yàn. Olúwa kò sì ní dá a yín lóhùn ní ọjọ́ náà.”
Ọlọ́run Israẹli ni, àpáta Israẹli sọ fún mi pé, ‘Ẹnìkan ti ń ṣe alákòóso ènìyàn lódodo, tí ń ṣàkóso ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.
Yóò sì dàbí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí oòrùn bá là, òwúrọ̀ tí kò ní ìkùùkuu, nígbà tí koríko tútù bá hù wá láti ilẹ̀ lẹ́yìn òjò.’
Ní ọdún kẹtàdínlógójì tí Joaṣi ọba Juda, Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi di ọba Israẹli ní Samaria ó sì jẹ ọba fún ọdún mẹ́rìndínlógún.
Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa, kò sì yípadà kúrò nínú ọ̀kankan nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati èyí tí ó ti ti Israẹli láti fà. Ó sì tẹ̀síwájú nínú wọn.