- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Rock
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Òun ni ó mú un yín la aginjù ẹlẹ́rù ńlá já, ilẹ̀ tí kò sí omi tí ó sì kún fún òǹgbẹ, pẹ̀lú àwọn ejò olóró ńlá ńlá àti àkéekèe. Ó mú omi jáde fún un yín láti inú àpáta.
Òun ni àpáta, iṣẹ́ ẹ rẹ̀ jẹ́ pípé, gbogbo ọ̀nà an rẹ̀ jẹ́ òdodo. Ọlọ́run olóòtítọ́ tí kò ṣe àṣìṣe kan, Ó dúró ṣinṣin, òdodo àti òtítọ́ ni òun.
Ó mú gun ibi gíga ayé ó sì fi èso oko bọ́ ọ. Ó sì jẹ́ kí ó mú oyin láti inú àpáta wá, àti òróró láti inú akọ òkúta wá.
Nítorí ta ni Ọlọ́run, bí kò ṣe Olúwa? Ta ni àpáta, bí kò ṣe Ọlọ́run wa.
“Olúwa ń bẹ́; olùbùkún sì ni àpáta mi! Gbígbéga sì ni Ọlọ́run àpáta ìgbàlà mi.
Ọlọ́run Israẹli ni, àpáta Israẹli sọ fún mi pé, ‘Ẹnìkan ti ń ṣe alákòóso ènìyàn lódodo, tí ń ṣàkóso ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.
nígbà tí èmi fi òrí-àmọ́ n wẹ ìṣísẹ̀ mi, àti tí àpáta ń tú ìṣàn òróró jáde fún mi wá.
Olúwa ni àpáta àti odi mi, àti olùgbàlà mi; Ọlọ́run mi ni àpáta mi, ẹni tí mo fi ṣe ibi ìsádi mi. Òun ni àpáta ààbò àti ìwo ìgbàlà mi àti ibi ìsádi mi.
Tẹ́ etí rẹ sí mi, gbà mí kíákíá; jẹ́ àpáta ààbò mi, jẹ́ odi alágbára láti gbà mí.
Ó fà mí yọ gòkè láti inú ihò ìparun, láti inú ẹrẹ̀ pọ̀tọ̀pọ́tọ̀, ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé orí àpáta, ó sì jẹ́ kí ìgbésẹ̀ mi wà láìfòyà.
Ó sán àpáta ní aginjù ó sì fún wọn ní omi mímu lọ́pọ̀lọ́pọ̀ bí ẹni pé láti inú ibú wá.
Ó mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta omi ṣíṣàn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí odò.
Nígbà tí ó lu àpáta, omi tú jáde, odò sì sàn lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ṣùgbọ́n òun ha lè fún wa lóúnjẹ ó ha le pèsè ẹran fún àwọn ènìyàn rẹ̀?”
Nítorí ìwọ ti gbàgbé Ọlọ́run ìgbàlà rẹ; tí ìwọ kò sì náání àpáta ìgbàlà rẹ̀, nítorí náà ni ìwọ ti gbin ọ̀gbìn dáradára ìwọ sì tọ́ àjèjì ẹ̀ka sínú rẹ̀.
Ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò jẹ́ bí ibi ìṣápamọ́ kúrò lọ́wọ́ afẹ́fẹ́ àti ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì, gẹ́gẹ́ bí odò omi ní ilẹ̀ aṣálẹ̀, àti bí òjìji àpáta ńlá ní ilẹ̀ gbígbẹ.
Ìpayà tí ìwọ ti fà sínú ìgbéraga ọkàn rẹ sì ti tàn ọ́ jẹ; ìwọ tí ń gbé ní pàlàpálá àpáta, tí o jókòó lórí ìtẹ́ gíga síbẹ̀ o kọ́ ìtẹ́ rẹ ga gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ idì; láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá,” ni Olúwa wí.
Ìgbéraga àyà rẹ ti tàn ọ́ jẹ, ìwọ tí ń gbé inú pálapàla àpáta, tí o sì kọ́ ibùgbé rẹ sí ibi gíga, ìwọ wí nínú ọkàn rẹ pé, ‘Ta ni yóò mú mi sọ̀kalẹ̀?’
“Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí ó bá sì ṣe wọn, èmi ó fiwé ọlọ́gbọ́n ènìyàn kan, ti ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí àpáta.
Òjò sì rọ̀, ìkún omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sí bì lu ilé náà; síbẹ̀síbẹ̀ náà kò sì wó, nítorí tí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta.
Èmi wí fún ọ, ìwọ ni Peteru àti pé orí àpáta yìí ni èmi yóò kọ́ ìjọ mi lé, àti ẹnu-ọ̀nà ipò òkú kì yóò lè borí rẹ̀.
Wọ́n mu nínú omi tí Kristi fi fún wọn. Wọ́n mu omi ẹ̀mí láti inú àpáta tí ó ń tẹ̀lé wọn, àpáta náà ni Kristi. Ó wà pẹ̀lú wọn nínú aginjù náà, òun ni àpáta tí ń fi omi ẹ̀mí tu ọkàn lára.