Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Rock: Smitten by Moses for water
Àwọn ẹsẹ nípa Smitten by Moses for water
Òun ni ó mú un yín la aginjù ẹlẹ́rù ńlá já, ilẹ̀ tí kò sí omi tí ó sì kún fún òǹgbẹ, pẹ̀lú àwọn ejò olóró ńlá ńlá àti àkéekèe. Ó mú omi jáde fún un yín láti inú àpáta.
Ó sán àpáta ní aginjù ó sì fún wọn ní omi mímu lọ́pọ̀lọ́pọ̀ bí ẹni pé láti inú ibú wá.
Ó mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta omi ṣíṣàn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí odò.
Nígbà tí ó lu àpáta, omi tú jáde, odò sì sàn lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ṣùgbọ́n òun ha lè fún wa lóúnjẹ ó ha le pèsè ẹran fún àwọn ènìyàn rẹ̀?”