Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Righteousness Imputed

33 ẹsẹ · 27 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nítorí Kristi ni òpin òfin sí òdodo fún olúkúlùkù ẹni tí ó gbà á gbọ́.

  2. Ṣùgbọ́n òdodo tí í ṣe ìgbàgbọ́ wí pé, “Má ṣe wí ni ọkàn rẹ̀ pé, ‘Ta ni yóò gòkè lọ si ọ̀run?’ ” (èyí ni, láti mú Kristi sọ̀kalẹ̀),

  3. Nítorí rẹ̀ ni ẹ̀yin ṣe wà nínú Kristi Jesu ẹni ti ó jásí ọgbọ́n fún wa láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run—èyí ń ni, òdodo, ìwà mímọ́ àti ìràpadà wa.

  4. Nítorí ó tí fi í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ nítorí wa, ẹni tí kò mọ ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ rí, kí àwa lè di òdodo Ọlọ́run nínú rẹ̀.

  5. Gẹ́gẹ́ bí Abrahamu “Ó gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.”

  6. Ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó ti jásí èrè fún mi, àwọn ni mo ti kà sí òfo nítorí Kristi.

  7. Nítòótọ́ láìṣe àní àní mo sì ka ohun gbogbo sí òfo nítorí ìtayọ ìmọ̀ Kristi Jesu Olúwa mi; nítorí ẹni ti mo ti ṣòfò ohun gbogbo, mo si kà wọn sí ohun tí kò ní èrè, kí èmi lè jèrè Kristi,

  8. kí a sì lè bá mi nínú rẹ̀, láìní òdodo tí èmi tìkára mi, tí ó ti inú òfin wá, ṣùgbọ́n èyí tí ó ti inú ìgbàgbọ́ wá nínú Kristi, òdodo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ ìgbàgbọ́.