Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Retaliation

38 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Ẹ má ṣe dá ni lẹ́jọ́, kí a má bà dá yín lẹ́jọ́.

  2. Nítorí irú ìdájọ́ tí ẹ̀yin bá ṣe, òun ni a ó sì ṣe fún yín; irú òsùwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ́n, òun ni a ó sì fi wọ́n fún yín.

  3. Ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ lọ sí iwájú rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sì lọ wọ́n wọ ìletò kan tí í ṣe ti ará Samaria láti pèsè sílẹ̀ dè é.

  4. Wọn kò sì gbà á, nítorí pé ó ń lọ sí Jerusalẹmu.

  5. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ Jakọbu àti Johanu sì rí i, wọ́n ní, “Olúwa wa, jẹ́ kí a pe iná láti ọ̀run wá, kí a sì pa wọ́n run, bí Elijah ti ṣe?”

  6. Ṣùgbọ́n Jesu yípadà, ó sì bá wọn wí.

  7. Lẹ́yìn náà Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì lọ sí ìletò mìíràn.

  8. Ẹ má ṣe fi búburú san búburú fún ẹnikẹ́ni. Ẹ má pèsè ohun tí ó tọ́ níwájú gbogbo ènìyàn.

  9. Olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ṣùgbọ́n ẹ fi ààyè sílẹ̀ fún ìbínú Ọlọ́run; nítorí a ti kọ ọ́ pé, Olúwa wí pé, “Tèmi ni ẹ̀san, èmi ó gbẹ̀san.”

  10. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, àbùkù ni fún un yín pátápátá pé ẹ̀yin ń bá ara yín ṣe ẹjọ́. Kín ní ṣe tí ẹ kò kúkú gba ìyà? Kín ló dé tí ẹ kò kúkú gba ìrẹ́jẹ kí ẹ sì fi i sílẹ̀ bẹ́ẹ̀?

  11. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń jẹ ni ní ìyà, ẹ sì ń rẹ́ ni jẹ. Ẹ̀yin si ń ṣe èyí sí àwọn arákùnrin yín.

  12. Ẹ rí i pé kò sí ẹni tí ó fi búburú san búburú, ṣùgbọ́n ẹ máa lépa èyí tí í ṣe rere láàrín ara yín àti sí ènìyàn gbogbo.

  13. Ẹ má ṣe fi búburú san búburú, tàbí fi èébú san èébú: ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa súre; nítorí èyí ni a pè yín sí, kí ẹ̀yin lè jogún ìbùkún.