Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Purity

35 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì jẹ aláìlábùkù, gẹ́gẹ́ bí fàdákà tí a yọ́ nínú ìléru amọ̀, tí a sọ di mímọ́ nígbà méje.

  2. Ìlànà Olúwa tọ̀nà, ó ń fi ayọ̀ fún ọkàn. Àṣẹ Olúwa ni mímọ́, ó ń fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú.

  3. Ta ni yóò gun orí òkè Olúwa lọ? Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ rẹ̀?

  4. Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun, ẹni tí kò gbé ọkàn rẹ̀ sókè sí asán tí kò sì búra èké.

  5. Òun ni yóò rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa, àti òdodo lọ́wọ́ Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀.

  6. Wẹ̀ mí pẹ̀lú ewé hísópù, èmi yóò sì mọ́; fọ̀ mí, èmi yóò sì funfun ju yìnyín lọ.

  7. Ọ̀ràn àìṣedéédéé borí mi bí ó ṣe ti ìrékọjá wa ni! Ìwọ ni yóò wẹ̀ wọ́n nù kúrò.

  8. Wọ́n ti dán ìpinnu rẹ wò pátápátá ìránṣẹ́ rẹ sì fẹ́ràn wọ́n.

  9. Olúwa kórìíra èrò ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n mímọ́ ni ọ̀rọ̀ ẹni pípé.

  10. Ta ni ó le è wí pé, “Mo ti ṣe ọkàn mi ní mímọ́, mo mọ́, n kò sì lẹ́ṣẹ̀”?

  11. Ọ̀nà ẹlẹ́ṣẹ̀ kún fún ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ṣùgbọ́n iṣẹ́ onínú funfun jẹ́ títọ́.

  12. Àwọn tí ó mọ́ ní ojú ara wọn síbẹ̀ tí wọn kò sì mọ́ kúrò nínú èérí wọn;

  13. “Ẹ wá ní ìsinsin yìí, ẹ jẹ́ kí a jọ ṣàṣàrò,” ni Olúwa wí. “Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín bá rí bí osùn, wọn ó sì funfun bí i yìnyín, bí wọn bá sì pọ́n bí ẹ̀jẹ̀, wọn ó sì dàbí ẹ̀gbọ̀n òwú.

  14. Èmi yóò pa ọwọ́ mi dà sí ọ, èmi ó sì ku ìpẹ́pẹ́ rẹ dànù, n ó sì mú gbogbo ìdọ̀tí rẹ kúrò.

  15. Èyí ni ó fi kàn mí ní ẹnu tí ó sì wí pé, “Wò ó, èyí ti kan ètè rẹ; a ti mú ẹ̀bi rẹ kúrò, a sì ti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù.”

  16. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni a ó fọ̀ mọ́, wọn yóò wà láìlábàwọ́n, a ó sì tún wọn ṣe, ṣùgbọ́n àwọn ẹni búburú yóò máa ṣe búburú lọ, kò sí ẹni búburú tí òye yóò yé ṣùgbọ́n òye yóò yé àwọn ọlọ́gbọ́n.

  17. Ǹjẹ́ èmi ha lè kà wọ́n sí mímọ́ pẹ̀lú òsùwọ̀n búburú, pẹ̀lú àpò òsùwọ̀n ẹ̀tàn?

  18. Ṣùgbọ́n ta ni o lè fi ara da ọjọ́ dídé rẹ̀? Ta ni yóò sì dúró nígbà tí ó bá fi ara hàn? Nítorí òun yóò dàbí iná ẹni tí ń da fàdákà àti bi ọṣẹ alágbàfọ̀.

  19. Òun yóò sì jókòó bí ẹni tí n yọ́, tí ó sì ń da fàdákà; yóò wẹ àwọn ọmọ Lefi mọ́, yóò sì tún wọn dàbí wúrà àti fàdákà, kí wọn bá a lè mú ọrẹ òdodo wá fún Olúwa,

  20. Alábùkún fún ni àwọn ọlọ́kàn mímọ́, nítorí wọn yóò rí Ọlọ́run.

  21. Gbogbo ẹ̀ka nínú mi tí kò bá so èso, òun a mú kúrò, gbogbo ẹ̀ka tí ó bá sì so èso, òun a wẹ̀ ẹ́ mọ́, kí ó lè so èso sí i.

  22. Ní àkótán, ará, ohunkóhun tí í ṣe òtítọ́, ohunkóhun tí í ṣe ọ̀wọ̀, ohunkóhun tí í ṣe títọ́ ohunkóhun tí í ṣe mímọ́, ohunkóhun tí í ṣe fífẹ́, ohunkóhun tí ó ni ìròyìn rere, bí ìwà títọ́ kan bá wà, bí ìyìn kan bá sì wà, ẹ máa gba nǹkan wọ̀nyí rò.

  23. Ète àṣẹ náà ni ìfẹ́ ti ń jáde wá láti inú ọkàn mímọ́ àti ẹ̀rí ọkàn rere àti ìgbàgbọ́ àìṣẹ̀tàn.

  24. Kí wọn máa di ohun ìjìnlẹ̀ ìgbàgbọ́ mú pẹ̀lú ọkàn funfun.

  25. Má ṣe fi ìkánjú gbe ọwọ́ lé ẹnikẹ́ni, bẹ́ẹ̀ ni kí ó má sì ṣe jẹ́ alábápín nínú ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn, pa ara rẹ mọ́ ní ìwà mímọ́.