Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Purifications

66 ẹsẹ · 25 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. àwọn ọmọ Israẹli sì la ìyàngbẹ ilẹ̀ kọjá nínú òkun pẹ̀lú ògiri omi ní ọ̀tún àti òsì.

  2. Olúwa sì wí fún Mose pé, “Tọ àwọn ènìyàn lọ kí o sì yà wọ́n sí mímọ́ ni òní àti ni ọ̀la. Jẹ́ kí wọn kí ó fọ aṣọ wọn.

  3. Nígbà náà ni ó rán àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Israẹli, wọ́n sì rú ẹbọ sísun, wọ́n fi ọ̀dọ́ màlúù rú ẹbọ àlàáfíà si Olúwa.

  4. Mose bu ìlàjì ẹ̀jẹ̀ ẹran sínú abọ́, ó sì fi ìlàjì tókù wọn ara pẹpẹ.

  5. Nígbà náà ni ó sì mú ìwé májẹ̀mú, ó sì kà á sí àwọn ènìyàn. Wọ́n dáhùn pé, “Àwa yóò ṣe gbogbo ohun tí Olúwa wí. Àwa yóò sì gbọ́rọ̀.”

  6. Nígbà náà ni Mose gbé ẹ̀jẹ̀, ó sì wọn sí àwọn ènìyàn náà lára pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Olúwa ti ṣe pẹ̀lú yín ni ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.”

  7. Nígbà náà ni ìwọ yóò mú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ, ìwọ yóò sì fi omi wẹ̀ wọ́n.

  8. “Ìwọ yóò sì ṣe agbada idẹ kan, àti ẹsẹ̀ rẹ̀ idẹ, fún wíwẹ̀. Ìwọ yóò sì gbé e sí àárín àgọ́ àjọ àti pẹpẹ náà, ìwọ yóò sì pọn omi sínú rẹ̀.

  9. Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa wẹ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn pẹ̀lú omi tí ó wà nínú rẹ̀.

  10. Nígbà náà ni Mose mú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá síwájú, ó sì fi omi wẹ̀ wọ́n.

  11. “Ẹni tí a fẹ́ wẹ̀mọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, fá gbogbo irun rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, lẹ́yìn èyí ó ti di mímọ́. Lẹ́yìn náà ó le wá sínú ibùdó ṣùgbọ́n kí ó wà lẹ́yìn àgọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ méje.

  12. Kí ó fá gbogbo irun rẹ̀ ní ọjọ́ keje: irun orí rẹ̀, irùngbọ̀n rẹ̀, irun ìpéǹpéjú rẹ̀, àti gbogbo irun rẹ̀ tókù. Kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóò sì mọ́.

  13. “Ẹ bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀, kí ẹ wí fún wọn pé, ‘Bí ìsunjáde bá ń jáde lára ọkùnrin kan lójú ara, ìsunjáde náà jẹ́ àìmọ́.

  14. Yálà ó ń jáde léraléra tàbí ó dúró, èyí yóò sọ ọ́ di aláìmọ́. Báyìí ni ìsunjáde rẹ̀ ṣe le è sọ ọ́ di aláìmọ́:

  15. “ ‘Gbogbo ibùsùn tí irú ẹni tí ó ní ìsunjáde náà bá sùn di àìmọ́.

  16. Bí ẹnikẹ́ni bá fi ara kan ibùsùn rẹ̀, ó gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀. Yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

  17. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jókòó lórí ohunkóhun tí ọkùnrin tí ó ní ìsunjáde bá jókòó le gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, kí ó sì wà láìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

  18. “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ọkùnrin náà tí ó ní ìsunjáde gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóò sì di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

  19. “ ‘Bí ẹni tí ó ní ìsunjáde bá tu itọ́ sí ẹni tí ó mọ́ lára, ẹni tí ó mọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀, yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

  20. “ ‘Gàárì ẹranko tí ẹni náà bá gùn yóò di àìmọ́.

  21. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ohunkóhun tí ó wà lábẹ́ ọkùnrin náà di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú irú nǹkan bẹ́ẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó wẹ ara rẹ̀. Yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

  22. “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ọkùnrin tí ó ní ìsunjáde ní ara rẹ̀ bá fi ara kàn láìfi omi fọ ọwọ́ rẹ̀, gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀. Yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

  23. “ ‘Ìkòkò amọ̀ tí ọkùnrin náà bá fọwọ́ kàn ni kí ẹ fọ́, gbogbo ohun èlò igi tí ó fọwọ́ kàn ni kí ẹ fi omi sàn.

  24. “ ‘Ẹnikẹ́ni tí a bá wẹ̀nù kúrò nínú ìsunjáde rẹ̀ gbọdọ̀ ka ọjọ́ méje fún àwọn ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́: kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì fi omi wẹ ara rẹ̀, yóò sì di mímọ́.

  25. Òun yóò sì wọ aṣọ funfun mímọ́ pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ funfun, yóò sì fi àmùrè funfun mímọ́ dì í, yóò sì dé fìlà funfun, àwọn aṣọ mímọ́ nìwọ̀nyí. Òun yóò sì fi omi wẹ̀, kí ó tó wọ̀ wọ́n.