Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Prisoners: John the Baptist

13 ẹsẹ · 22 abala

Àwọn ẹsẹ nípa John the Baptist

  1. Nígbà tí Johanu gbọ́ ohun tí Kristi ṣe nínú ẹ̀wọ̀n, ó rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀

  2. Nísinsin yìí Herodu ti mú Johanu, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì fi sínú túbú, nítorí Herodia aya Filipi arákùnrin rẹ̀,

  3. nítorí Johanu onítẹ̀bọmi ti sọ fún Herodu pé, “Kò yẹ fún ọ láti fẹ́ obìnrin náà.”

  4. Herodu fẹ́ pa Johanu, ṣùgbọ́n ó bẹ̀rù àwọn ènìyàn nítorí gbogbo ènìyàn gbàgbọ́ pé wòlíì ni.

  5. Ní ọjọ́ àsè ìrántí ọjọ́ ìbí Herodu, ọmọ Herodia obìnrin jó dáradára, ó sì tẹ́ Herodu lọ́run gidigidi.

  6. Nítorí náà ni ó ṣe fi ìbúra ṣe ìlérí láti fún un ní ohunkóhun ti ó bá béèrè fún.

  7. Pẹ̀lú ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ó béèrè pé, “Fún mi ni orí Johanu onítẹ̀bọmi nínú àwopọ̀kọ́”.

  8. Inú ọba bàjẹ́ gidigidi, ṣùgbọ́n nítorí ìbúra rẹ̀ àti kí ojú má ba à tì í níwájú àwọn àlejò tó wà ba jẹ àsè, ó pàṣẹ pé kí wọ́n fún un gẹ́gẹ́ bí o ti fẹ́.

  9. Nítorí náà, a bẹ́ orí Johanu onítẹ̀bọmi nínú ilé túbú.

  10. A sì gbé orí rẹ̀ jáde láti fi fún ọmọbìnrin náà nínú àwopọ̀kọ́, òun sì gbà á, ó gbé e tọ ìyá rẹ̀ lọ.

  11. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu wá gba òkú rẹ̀, wọ́n sì sin ín. Wọ́n sì wá sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Jesu.

  12. Herodu fúnra rẹ̀ sá ti ránṣẹ́ mú Johanu, tìkára rẹ̀ sínú túbú nítorí Herodia aya Filipi arákùnrin rẹ̀ nítorí tí ó fi ṣe aya.

  13. Ó fi èyí parí gbogbo rẹ̀ nígbà tí ó fi Johanu sínú túbú.