Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Polygamy: Forbidden

16 ẹsẹ · 6 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Forbidden

  1. “ ‘Má ṣe fẹ́ àbúrò ìyàwó rẹ obìnrin ní aya gẹ́gẹ́ bí orogún tàbí bá a lòpọ̀, nígbà tí ìyàwó rẹ sì wà láààyè.

  2. Kò gbọdọ̀ kó aya jọ, kí ọkàn rẹ̀ má bá a yapa kúrò. Kò gbọdọ̀ kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara rẹ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀.

  3. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, “Nítorí kín ní?” Nítorí Olúwa ti ṣe ẹlẹ́rìí láàrín ìwọ àti láàrín aya èwe rẹ, ẹni tí ìwọ ti ń hùwà ẹ̀tàn sí i: bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkejì rẹ ni òun jẹ́, àti aya májẹ̀mú rẹ.

  4. Ọlọ́run kò ha ti ṣe wọ́n ní ọ̀kan? Ni ara àti ni ẹ̀mí tirẹ̀ ni. Èéṣe tí Ọlọ́run da yín lọ́kàn? Kí òun bá à lè wá irú-ọmọ bí ti Ọlọ́run. Nítorí náà, ẹ tọ́jú ẹ̀mí yín, ẹ má sì ṣe hùwà ẹ̀tàn sí aya èwe yín.

  5. Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹyin kò ti kà á pé ‘ẹni tí ó dá wọn ní ìgbà àtètèkọ́ṣe, Ọlọ́run dá wọn ni ti akọ ti abo.’

  6. Ó sì wí fún un pé, ‘Nítorí ìdí èyí ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, òun yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan.’

  7. Àwọn Farisi kan tọ̀ ọ́ wá, láti dán an wò. Wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ó ha tọ̀nà fún ènìyàn láti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀?”

  8. Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni Mose pàṣẹ fún un yín?”

  9. Wọ́n dáhùn pé, “Mose yọ̀ǹda fún wa láti kọ ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún un, kí a sì fi sílẹ̀.”

  10. Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn, ó sì wí pé, “Nítorí líle àyà yín ni Mose fi kọ òfin yìí fun un yín.

  11. Ṣùgbọ́n láti ìgbà tí ayé ti ṣẹ̀, Ọlọ́run dá wọn ní akọ àti abo.

  12. Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ yóò sì fi ara mọ́ aya rẹ̀.

  13. Òun àti ìyàwó rẹ̀ yóò di ara kan náà. Nítorí náà, wọn kì í túnṣe méjì mọ́ bí kò ṣe ẹyọ ọ̀kan ṣoṣo.

  14. Ǹjẹ́ alábojútó yẹ kí ó jẹ́ aláìlẹ́gàn, ọkọ aya kan, olùṣọ̀ràn, aláìrékọjá, oníwà rere, olùfẹ́ àlejò ṣíṣe, ẹni tí ó lè ṣe olùkọ́.

  15. Kí àwọn díákónì jẹ́ ọkọ obìnrin kan, kí wọn káwọ́ àwọn ọmọ àti ilé ara wọn dáradára.

  16. Ẹni tí yóò jẹ́ alàgbà gbọdọ̀ jẹ́ aláìlábùkù, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ onìyàwó kan, ọmọ wọn náà gbọdọ̀ jẹ́ onígbàgbọ́ tí kò ní ẹ̀sùn ìwà ipá tàbí ẹ̀sùn àìgbọ́ràn kankan.