Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Nebuzar-Adan: Protects Jeremiah

9 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Protects Jeremiah

  1. Nísinsin yìí, Nebukadnessari ọba àwọn Babeli pàṣẹ lórí Jeremiah, láti ọ̀dọ̀ Nebusaradani olórí ogun wá wí pé:

  2. “Ẹ gbé e, kí ẹ sì bojútó o. Ẹ má ṣe ṣe ohun búburú fún un, ṣùgbọ́n ohunkóhun tó bá béèrè ni kí ẹ fi fún un.”

  3. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú, Nebusaradani balógun ìṣọ́, àti Nebusaradani olórí ìwẹ̀fà, àti Nergali-Ṣareseri, olórí amòye àti gbogbo àwọn ìjòyè ọba Babeli,

  4. ránṣẹ́ láti mú Jeremiah kúrò nínú túbú. Wọ́n gbé e lọ fún Gedaliah ọmọ Ahikamu ọmọ Ṣafani láti mú padà lọ sí ilé àti máa wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.

  5. Ọ̀rọ̀ náà sì tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa lẹ́yìn tí Nebusaradani balógun àwọn ẹ̀ṣọ́ ti tú u sílẹ̀ ní Rama. Ó rí Jeremiah tí a fi ẹ̀wọ̀n dè láàrín gbogbo àwọn tí wọ́n mú ní Jerusalẹmu àti Juda. Wọ́n kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì Babeli.

  6. Nígbà tí balógun ẹ̀ṣọ́ rí Jeremiah, ó sọ fún un wí pé, “Olúwa Ọlọ́run rẹ ni ó pàṣẹ ibí yìí fún mi.

  7. Nísinsin yìí, Olúwa ti mú un jáde; ó ti ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ pé òun yóò ṣe. Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ nítorí wí pé ẹ̀yin ènìyàn ṣẹ̀ sí Olúwa, àti pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀.

  8. Ṣùgbọ́n, ní òní yìí mò ń tú ọ sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n tí ó wà ní ọwọ́ rẹ. Bí o bá fẹ́, tẹ̀lé mi ká lọ sí Babeli, èmi yóò sì bojútó ọ; ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá fẹ́, dúró síbí. Wò ó, gbogbo orílẹ̀-èdè wà níwájú rẹ, lọ sí ibikíbi tí ó bá tẹ́ ọ lọ́rùn.”

  9. Ẹ̀wẹ̀, kí ó tó di pé Jeremiah pẹ̀yìndà láti máa lọ, Nebusaradani fi kún un wí pé, “Padà tọ Gedaliah ọmọ Ahikamu lọ, ọmọ Ṣafani, ẹni tí ọba Babeli ti fi jẹ baálẹ̀ lórí ìlú Juda, kí o sì máa gbé ní àárín àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o máa lọ ibikíbi tí ó bá tọ́ ní ojú rẹ.” Nígbà náà ni balógun náà fún un ní oúnjẹ àti ẹ̀bùn, ó sì jẹ́ kí ó lọ.