Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Manna

57 ẹsẹ · 44 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nítorí pé oúnjẹ Ọlọ́run ni èyí tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, tí ó sì fi ìyè fún aráyé.”

  2. Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Olúwa, máa fún wa ní oúnjẹ yìí títí láé.”

  3. Jesu wí fún wọn pé, “Èmi ni oúnjẹ ìyè, ẹnikẹ́ni tí ó bá tọ̀ mí wá, ebi kì yóò pa á; ẹni tí ó bá sì gbà mí gbọ́, òǹgbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé.

  4. Èmi ni oúnjẹ ìyè.

  5. Àwọn baba yín jẹ manna ní aginjù, wọ́n sì kú.

  6. Èyí ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, kí ènìyàn lè máa jẹ nínú rẹ̀ kí ó má sì kú.

  7. Èmi ni oúnjẹ ìyè náà tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, bí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí, yóò yè títí láéláé, oúnjẹ náà tí èmi ó sì fi fún ni fún ìyè aráyé ni ara mi.”