Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Holy Boldness

23 ẹsẹ · 30 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Àwọn ọkùnrin náà yí padà, wọ́n sì ń lọ sí ìhà Sodomu. Ṣùgbọ́n Abrahamu dúró níbẹ̀ níwájú Olúwa.

  2. Nígbà náà ni Abrahamu súnmọ́ ọ̀dọ̀ Olúwa, ó sì wí pé, “Ìwọ yóò ha pa olódodo ènìyàn àti ènìyàn búburú run papọ̀ bí?”

  3. “Bí ó bá ṣe pé ìwọ rí àádọ́ta olódodo nínú ìlú náà, ìwọ yóò ha run ún, ìwọ kì yóò ha dá ìlú náà sí nítorí àwọn àádọ́ta olódodo tí ó wà nínú rẹ̀ náà?

  4. Kò jẹ́ rí bẹ́ẹ̀! Dájúdájú ìwọ kì yóò ṣe ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀, láti pa olódodo pẹ̀lú àwọn ènìyàn rere àti àwọn ènìyàn búburú. Dájúdájú, ìwọ kì yóò ṣe èyí tí ó tọ́ bi?”

  5. Olúwa wí pé, “Bí mo bá rí àádọ́ta olódodo ní ìlú Sodomu, èmi yóò dá ìlú náà sí nítorí tiwọn.”

  6. Abrahamu sì tún tẹ̀síwájú pé, “Wò ó nísinsin yìí, níwọ̀n bí èmi ti ní ìgboyà láti bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ níwájú Olúwa, èmi ẹni tí í ṣe erùpẹ̀ àti eérú,

  7. bí ó bá ṣe pe olódodo márùndínláàádọ́ta ni ó wà nínú ìlú, ìwọ yóò ha pa ìlú náà run nítorí ènìyàn márùn-ún bí?” Olúwa dáhùn pé, “Èmi kì yóò pa ìlú náà run bí mo bá rí olódodo márùndínláàádọ́ta nínú rẹ̀.”

  8. Òun sì tún wí lẹ́ẹ̀kan si pé, “Bí ó bá ṣe pé ogójì ni ń kọ́?” Olúwa sì tún wí pé, “Èmi kì yóò pa ìlú náà run bí mo bá rí olódodo ogójì nínú rẹ̀.”

  9. Abrahamu sì tún bẹ Olúwa pé, “Kí Olúwa má ṣe bínú, ṣùgbọ́n èmi yóò sọ̀rọ̀. Bí ó bá ṣe pé ọgbọ̀n ni a rí níbẹ̀ ń kọ́?” Olúwa dáhùn pé, “Bí mó bá rí ọgbọ̀n, èmi kì yóò pa ìlú run.”

  10. Abrahamu wí pé, “Níwọ́n bí mo ti ní ìgboyà láti bá Olúwa sọ̀rọ̀ báyìí, jẹ́ kí n tẹ̀síwájú. Bí o bá ṣe pé olódodo ogún péré ni ó wà nínú ìlú náà ń kọ́?” Olúwa sì dáhùn pé, “Èmi kì yóò pa á run nítorí ogún ènìyàn náà.”

  11. Abrahamu sì wí pé, “Jọ̀wọ́ má ṣe bínú Olúwa. Jẹ́ kí ń béèrè lẹ́ẹ̀kan si. Bí ó bá ṣe pé ènìyàn mẹ́wàá ni ó jẹ́ olódodo ń kọ́?” Olúwa wí pé, “Nítorí ènìyàn mẹ́wàá náà, èmi kì yóò pa á run.”

  12. Ó sì ku Jakọbu nìkan, ọkùnrin kan sì bá a ja ìjàkadì títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́.

  13. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà rí i pé òun kò le borí Jakọbu, ó fọwọ́ kàn án ní ọ̀ọ́kán ibi tí eegun itan ti bẹ̀rẹ̀, egungun náà sì yẹ̀ kúrò lórí ike, bí ó ti ń ja ìjàkadì.

  14. Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí fún un pé, “Jẹ́ kí ń máa lọ, nítorí ojúmọ́ ti mọ́.” Ṣùgbọ́n Jakọbu dá a lóhùn pé, “Èmi kò ní jẹ́ kí o lọ, àyàfi bí o bá súre fún mi.”

  15. Ọkùnrin náà béèrè orúkọ rẹ̀. Ó sì wí fún un pé, “Jakọbu ni òun ń jẹ́.”

  16. Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí pé, “Orúkọ rẹ kì yóò jẹ́ Jakọbu mọ́ bí kò ṣe Israẹli, nítorí pé ìwọ ti bá Ọlọ́run àti ènìyàn jà, o sì borí.”

  17. Jakọbu sì bẹ ọkùnrin náà pé, “Sọ orúkọ rẹ fún mi.” Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà sá à dáhùn pé, “Èéṣe tí o ń béèrè orúkọ mi?” Lẹ́yìn náà ó súre fún Jakọbu níbẹ̀.

  18. Nígbà náà ni Peteru kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin olórí àti ẹ̀yin alàgbà àwọn ènìyàn!

  19. Bí ó bá ṣe pé a ń wádìí wa lónìí ní tí iṣẹ́ rere ti a ṣe lára abirùn náà, bí a ti ṣe mú ọkùnrin yìí láradá,

  20. kí èyí yé gbogbo yín àti gbogbo ènìyàn Israẹli pé, ni orúkọ Jesu Kristi ti Nasareti, tí ẹ̀yin kàn mọ́ àgbélébùú, tí Ọlọ́run jí dìde kúrò nínú òkú, nípa rẹ̀ ni ọkùnrin yìí fi dúró níwájú yín ni ara dídá-ṣáṣá.

  21. Èyí ni “ ‘òkúta tí a ti ọwọ́ ẹ̀yin ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, tí ó sì di pàtàkì igun ilé.’

  22. Kò sì sí ìgbàlà lọ́dọ̀ ẹlòmíràn; nítorí kò sí orúkọ mìíràn lábẹ́ ọ̀run ti a fi fún ni nínú ènìyàn, nípa èyí tí a lè fi gbà wá là.”

  23. Nígbà tí wọ́n sì kíyèsi ìgboyà Peteru àti Johanu, tí wọ́n mọ̀ pé, aláìkẹ́kọ̀ọ́ àti òpè ènìyàn ni wọn, ẹnu yà wọ́n, wọ́n sì wòye pé, wọ́n ti ń bá Jesu gbé.