Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa God

662 ẹsẹ · 46 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ọkùnrin náà sì wí pé, “Èyí ni egungun láti inú egungun mi àti ẹran-ara nínú ẹran-ara mi; ‘obìnrin’ ni a ó máa pè é, nítorí a mú un jáde láti ara ọkùnrin.”

  2. Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.

  3. Ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ sì wà ní ìhòhò, ojú kò sì tì wọ́n.

  4. Èyí ni àkọsílẹ̀ ìran Adamu. Nígbà tí Ọlọ́run dá ènìyàn, ní àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a.

  5. Àti akọ àti abo ni Ó dá wọn, ó sì súre fún wọn, ó sì pe orúkọ wọ́n ní Adamu ní ọjọ́ tí ó dá wọn.

  6. Inú Olúwa sì bàjẹ́ gidigidi nítorí pé ó dá ènìyàn sí ayé, ọkàn rẹ̀ sì gbọgbẹ́.

  7. Nítorí náà, Olúwa wí pé, “Èmi yóò pa ènìyàn tí mo ti dá run kúrò lórí ilẹ̀, ènìyàn àti ẹranko, àti ohun tí ń rákò, àti ẹyẹ ojú ọ̀run, nítorí inú mi bàjẹ́ pé mo ti dá wọn.”

  8. Èmi yóò rántí májẹ̀mú mi, tí ó wà láàrín èmi àti ẹ̀yin àti gbogbo ẹ̀dá alààyè, kì yóò sì tún sí ìkún omi mọ́ láti pa gbogbo ẹ̀dá run.

  9. Nígbàkígbà tí òṣùmàrè bá yọ ní àwọsánmọ̀, èmi yóò rí i, èmi yóò sì rántí májẹ̀mú ayérayé tí ń bẹ láàrín Ọlọ́run àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń bẹ ní ayé.”

  10. Èmí sì tún fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú wọn láti fún wọn ní ilẹ̀ Kenaani, ilẹ̀ tí wọn gbé gẹ́gẹ́ bí àjèjì.

  11. Èmi sì ti tún gbọ́ kíkùn àwọn ọmọ Israẹli àwọn tí àwọn ará Ejibiti mú gẹ́gẹ́ bí ẹrú, àti pé èmi sì ti rántí májẹ̀mú mi.

  12. ‘Ẹ̀yin ti rí ohun tí mo ti ṣe sí àwọn ará Ejibiti, àti bí mo ti gbé e yín ní apá ìyẹ́ idì.

  13. Nísinsin yìí, bí ẹ̀yin bá ṣe ìgbọ́ràn sí mi dé ojú àmì, tí ẹ sì pa májẹ̀mú mi mọ́, nígbà náà ni ẹ̀yin ó jẹ́ ìṣúra fún mi ju gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ayé ni tèmi.

  14. Ẹ̀yin yóò sì máa jẹ́ ilẹ̀ ọba àwọn àlùfáà fún mi, orílẹ̀-èdè mímọ́.’ Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ ti ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Israẹli.”

  15. Nígbà náà ni èmi yóò máa gbé láàrín àwọn ọmọ Israẹli, èmi yóò sì máa ṣe Ọlọ́run wọn.

  16. Wọn yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn, ẹni tí ó mú wọn jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá, nítorí kí èmi lè máa gbé àárín wọn. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn.

  17. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kí ẹ sì jẹ́ mímọ́ torí pé mo jẹ́ mímọ́. Ẹ má ṣe sọ ara yín di àìmọ́ nípasẹ̀ ohunkóhun tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀.

  18. Èmi ni Olúwa tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá láti jẹ́ Ọlọ́run yín torí náà, ẹ jẹ́ mímọ́ torí pé mímọ́ ni èmi.

  19. Ẹ má ṣe ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. Àwọn ọmọ Israẹli gbọdọ̀ mọ̀ mí ní mímọ́. Èmi ni Olúwa tí ó sọ yín di mímọ́.

  20. Tí ó sì mú yín jáde láti Ejibiti wá láti jẹ́ Ọlọ́run yín. Èmi ni Olúwa.”

  21. Pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, nígbà tí wọ́n bá wà nílé àwọn ọ̀tá wọn, èmi kì yóò ta wọ́n nù, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò kórìíra wọn pátápátá, èyí tí ó lè mú mi dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn.

  22. Nítorí wọn, èmi ó rántí májẹ̀mú mi tí mo ti ṣe pẹ̀lú baba ńlá wọn. Àwọn tí mo mú jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti lójú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè láti jẹ́ Ọlọ́run wọn. Èmi ni Olúwa.’ ”

  23. Olúwa kò torí pé ẹ pọ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ju àwọn ènìyàn yòókù lọ yàn yín, ẹ̀yin sá à lẹ kéré jù nínú gbogbo ènìyàn.

  24. Ṣùgbọ́n torí Olúwa fẹ́ràn yín, tí ó sì pa ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín mọ́ ni ó ṣe fi ọwọ́ agbára ńlá mú un yín jáde tí ó sì rà yín padà nínú oko ẹrú, àti láti ọwọ́ agbára Farao ọba Ejibiti.

  25. Nítorí náà ẹ mọ̀ dájúdájú pé Olúwa Ọlọ́run yín, Òun ni Ọlọ́run, Ọlọ́run olóòtítọ́ ni, tí ń pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìran, àwọn tí ó fẹ́ ẹ tí ó sì ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.