Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Fool

36 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Bí ẹ̀gún èṣùṣú lọ́wọ́ ọ̀mùtí ni òwe lẹ́nu aláìgbọ́n.

  2. Bí tafàtafà ti ń ṣe ni léṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni ẹni tí ó gba aṣiwèrè ṣíṣẹ́ tàbí ẹni tí ń kọjá lọ.

  3. Bí ajá ti í padà sí èébì rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè tún ń hu ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.

  4. Ǹjẹ́ o rí ènìyàn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara rẹ̀? Ìrètí ń bẹ fún aláìgbọ́n ènìyàn jù ú lọ.

  5. Bí ejò bá ṣán ni kí a tó lo oògùn rẹ̀, kò sí èrè kankan fún olóògùn rẹ̀.

  6. Ọ̀rọ̀ tí ó wá láti ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa ní oore-ọ̀fẹ́ ṣùgbọ́n ètè òmùgọ̀ fúnra rẹ̀ ni yóò parun.

  7. Ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ òmùgọ̀; ìparí rẹ̀ sì jẹ́ ìsínwín búburú.

  8. Wèrè a sì máa ṣàfikún ọ̀rọ̀. Kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí ó ń bọ̀ ta ni ó le è sọ fún un ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀?

  9. Iṣẹ́ aṣiwèrè a máa dá a lágara kò sì mọ ojú ọ̀nà sí ìlú.

  10. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí kò bá sì ṣe wọ́n, òun ni èmi yóò fiwé aṣiwèrè ènìyàn kan tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí iyanrìn.

  11. Òjò sì rọ̀, ìkún omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sì bì lu ilé náà, ilé náà sì wó; wíwó rẹ̀ sì pọ̀ jọjọ.”