Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Fool: General references

36 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ nípa General references

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Fi ìwà àìmọ̀kan rẹ sílẹ̀ ìwọ yóò sì yè; rìn ní ọ̀nà òye.

  2. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹlẹ́gàn wí, kọ lẹ́tà sí àbùkù ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹni búburú wí kọ lẹ́tà sí èébú.

  3. Má ṣe bá ẹlẹ́gàn wí, àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò kórìíra rẹ. Bá ọlọ́gbọ́n wí yóò sì fẹ́ràn rẹ;

  4. Òmùgọ̀ obìnrin jẹ́ aláriwo; ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláìní ìmọ̀.

  5. Ó jókòó ní ẹnu-ọ̀nà ilé rẹ̀ lórí ìjókòó níbi tí ó ga jù láàrín ìlú,

  6. ó ń pe àwọn tí ó ń kọjá lọ, tí wọn ń lọ tààrà ní ọ̀nà wọn.

  7. “Jẹ́ kí gbogbo ẹni tí ó jẹ́ aláìlóye súnmọ́ bí!” Ni ó wí fún ẹni tí òye kù díẹ̀ ká à tó fún.

  8. “Omi tí a jí mu dùn oúnjẹ tí a jẹ ní ìkọ̀kọ̀ a máa ládùn!”

  9. Ọgbọ́n ni a ń bá lẹ́nu àwọn olóye, ṣùgbọ́n kùmọ̀ wà fún ẹ̀yìn àwọn aláìlóye.

  10. Ọlọ́gbọ́n ènìyàn kó ìmọ̀ jọ, ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n a máa ṣokùnfà ìparun.

  11. Má ṣe súnmọ́ aláìgbọ́n ènìyàn, nítorí ìwọ kì yóò rí ìmọ̀ ní ètè rẹ̀.

  12. Ọgbọ́n olóye ni láti ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀nà wọn ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ aṣiwèrè ni ìtànjẹ.

  13. Aláìgbọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ nígbà tí ó yẹ kí ó ṣe àtúnṣe ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ṣùgbọ́n láàrín àwọn olódodo ni a ti rí ojúrere.

  14. Ọlọ́gbọ́n ọmọ mú inú baba rẹ̀ dùn, ṣùgbọ́n aṣiwèrè ènìyàn kẹ́gàn ìyá rẹ̀.

  15. Inú ènìyàn aláìlóye a máa dùn sí ìwà òmùgọ̀; ṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa rin ọ̀nà tààrà.

  16. Olóye ènìyàn gbójú wo ọgbọ́n níwájú, ṣùgbọ́n ojú aláìgbọ́n ń wò káàkiri ilẹ̀ ayé.

  17. Aṣiwèrè ọmọ mú ìbànújẹ́ bá baba rẹ̀ àti ìkorò fún ẹni tí ó bí i lọ́mọ.

  18. Ètè aláìgbọ́n dá ìjà sílẹ̀ ẹnu rẹ̀ sì ń ṣokùnfà ẹgba.

  19. Ẹnu aláìgbọ́n ni ó ba tirẹ̀ jẹ́, ètè rẹ̀ sì jẹ́ ìdẹ̀kùn fún ọkàn rẹ̀.

  20. Ẹgba fún ẹṣin, ìjánu fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti pàṣán fún ẹ̀yìn aṣiwèrè.

  21. Má ṣe dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ pẹ̀lú yóò dàbí i rẹ̀.

  22. Dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò dàbí ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ̀.

  23. Bí ìgbà tí ènìyàn gé ẹsẹ̀ ara rẹ̀ tàbí mú ìwà ipá ni kí a ránṣẹ́ nípasẹ̀ aṣiwèrè.

  24. Bí ẹsẹ̀ arọ tí ó ń mi dirodiro ni òwe lẹ́nu aṣiwèrè.

  25. Bí ìgbà tí a so òkúta mọ́ okùn títa ni fífún aláìgbọ́n ní ọlá.