Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Death

177 ẹsẹ · 6 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ta ni ó mọ̀ bóyá ẹ̀mí ènìyàn ń lọ sí òkè tí ẹ̀mí ẹranko sì ń lọ sí ìsàlẹ̀ nínú ilẹ̀ ni?”

  2. Orúkọ rere sàn ju ìpara olóòórùn dídùn lọ, ọjọ́ ikú sì dára ju ọjọ́ tí a bí ènìyàn lọ.

  3. Ó dára láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀ ju ibi àsè, nítorí pé ikú jẹ́ àyànmọ́ gbogbo ènìyàn; kí alààyè ní èyí ní ọkàn.

  4. Nítorí pé ẹni tí ó wà láààyè mọ̀ wí pé àwọn yóò kú ṣùgbọ́n òkú kò mọ ohun kan wọn kò ní èrè kankan mọ́, àti pé kódà ìrántí wọn tí di ohun ìgbàgbé.

  5. Ìfẹ́ wọn, ìríra wọn, àti ìlara wọn ti parẹ́: láéláé kọ́ ni wọn yóò tún ní ìpín nínú ohunkóhun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn.

  6. Ìmọ́lẹ̀ dùn; Ó sì dára fún ojú láti rí oòrùn.

  7. Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ènìyàn jẹ̀gbádùn gbogbo iye ọdún tí ó le è lò láyé ṣùgbọ́n jẹ́ kí ó rántí ọjọ́ òkùnkùn nítorí wọn ó pọ̀. Gbogbo ohun tí ó ń bọ̀ asán ni.

  8. Èmi wí pé, “Ní àárín gbùngbùn ọjọ́ ayé mi èmi ó ha kọjá lọ ní ibodè ikú kí a sì dùn mí ní àwọn ọdún mi tí ó ṣẹ́kù?”

  9. Èmi wí pé, “Èmi kì yóò lè tún rí Olúwa mọ́, àní Olúwa, ní ilẹ̀ àwọn alààyè; èmi kì yóò lè síjú wo ọmọ ènìyàn mọ́, tàbí kí n wà pẹ̀lú àwọn tí ó sì ń gbe orílẹ̀ ayé báyìí.

  10. Gẹ́gẹ́ bí àgọ́ olùṣọ́-àgùntàn, ilé mi ni a ti wó lulẹ̀ tí a sì gbà kúrò lọ́wọ́ mi. Gẹ́gẹ́ bí ahunṣọ mo ti ká ayé mi nílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni òun sì ti ké mi kúrò lára àṣà; ọ̀sán àti òru ni ìwọ ṣe òpin mi.

  11. Èmi fi sùúrù dúró títí di àfẹ̀mọ́júmọ́, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí kìnnìún ó ti fọ́ gbogbo egungun mi; ọ̀sán àti òru ni ìwọ fi ṣe òpin mi.

  12. Nítorí pé isà òkú kò le è yìn ọ́, ipò òkú kò le è kọ orin ìyìn rẹ; àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ sínú ọ̀gbun kò lè ní ìrètí fún òtítọ́ rẹ.

  13. Alààyè, àwọn alààyè wọ́n ń yìn ọ́, gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń ṣe lónìí; àwọn baba sọ fún àwọn ọmọ wọn nípa òtítọ́ rẹ.

  14. Olódodo ṣègbé kò sí ẹnìkan tí ó rò ó lọ́kàn ara rẹ̀; a mú àwọn ẹni mímọ́ lọ, kò sì ṣí ẹni tó yé pé a ti mú àwọn olódodo lọ láti yọ wọ́n kúrò nínú ibi.

  15. Gbogbo àwọn tí ń rìn déédé ń wọ inú àlàáfíà; wọ́n rí ìsinmi bí wọ́n ti ń sùn nínú ikú.

  16. Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí nípa ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin tí wọ́n bá bí nílẹ̀ yìí, àti ìyá tí ó bí wọn àti baba wọn.

  17. “Wọn yóò kú ikú ààrùn, wọn kò ní sin wọ́n tàbí ṣọ̀fọ̀ fún wọn. Wọn ó dàbí ìdọ̀tí lórí ilẹ̀; wọn ó ṣègbé pẹ̀lú idà àti ìyàn. Òkú wọn yóò sì di oúnjẹ fún ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀.”

  18. “Ẹ di àmùrè yín, kí fìtílà yín sì máa jó.

  19. Kí ẹ̀yin tìkára yín dàbí ẹni tí ń retí olúwa wọn, nígbà tí òun ó padà ti ibi ìgbéyàwó dé, pé nígbà tí ó bá dé, tí ó sì kànkùn, kí wọn lè ṣí i sílẹ̀ fún un lọ́gán.

  20. Ìbùkún ni fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà nígbà tí olúwa náà bá dé tí yóò bá wọn tí wọn ń ṣọ́nà; lóòótọ́ ni mo wí fún yín, yóò di ara rẹ̀ ní àmùrè yóò sì mú wọn jókòó láti jẹun, yóò sì jáde wá láti ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.

  21. “Ó sì ṣe, alágbe kú, a sì ti ọwọ́ àwọn angẹli gbé e lọ sí oókan àyà Abrahamu: ọlọ́rọ̀ náà sì kú pẹ̀lú, a sì sin ín;

  22. Ní ipò òkú ni ó gbé ojú rẹ̀ sókè, ó ń bẹ nínú ìjìyà oró, ó sì rí Abrahamu ní òkèrè, àti Lasaru ní oókan àyà rẹ̀.

  23. Ó sì ké, ó wí pé, ‘Baba Abrahamu, ṣàánú fún mi, kí o sì rán Lasaru, kí ó tẹ orí ìka rẹ̀ bọ omi, kí ó sì fi tù mí ní ahọ́n; nítorí èmi ń joró nínú ọ̀wọ́n iná yìí.’

  24. “Ṣùgbọ́n Abrahamu wí pé, ‘Ọmọ, rántí pé, nígbà ayé rẹ, ìwọ ti gba ohun rere tìrẹ, àti Lasaru ohun búburú, ṣùgbọ́n nísinsin yìí ara rọ̀ ọ́, ìwọ sì ń joró.

  25. Àti pẹ̀lú gbogbo èyí, a gbé ọ̀gbun ńlá kan sí agbede-méjì àwa àti ẹ̀yin, kí àwọn tí ń fẹ́ má ba á le rékọjá láti ìhín lọ sọ́dọ̀ yín, kí ẹnikẹ́ni má sì le ti ọ̀hún rékọjá tọ̀ wá wá.’