Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Charitableness

79 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. nítorí ẹni tí ó bá sin Kristi nínú nǹkan wọ̀nyí ni ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì ní ìyìn lọ́dọ̀ ènìyàn.

  2. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a ṣa gbogbo ipá wa láti máa lépa àlàáfíà, àti ohun tí àwa yóò fi gbé ara wa ró.

  3. Má ṣe bi iṣẹ́ Ọlọ́run ṣubú nítorí oúnjẹ. Gbogbo oúnjẹ ni ó mọ́, ṣùgbọ́n ohun búburú ni fún ẹni náà tí ó jẹ ohunkóhun tí ó le mú ẹlòmíràn kọsẹ̀.

  4. Ó dára kí a má tilẹ̀ jẹ ẹran tàbí mu wáìnì tàbí ṣe ohunkóhun tí yóò mú arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ ṣubú.

  5. Nítorí náà, ohun tí ìwọ bá gbàgbọ́ nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí, pa á mọ́ ní àárín ìwọ àti Ọlọ́run. Alábùkún fún ni ẹni náà tí kò dá ara rẹ̀ lẹ́bi nínú ohun tí ó yàn.

  6. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó ṣe iyèméjì, ó jẹ̀bi bí ó ba jẹ ẹ́, nítorí jíjẹ ẹ́ rẹ̀ kò ti inú ìgbàgbọ́ wá; bẹ́ẹ̀ sì ni, ohun gbogbo tí kò bá ti inú ìgbàgbọ́ wá, ẹ̀ṣẹ̀ ni.

  7. Bí ẹnikẹ́ni bá sì kìlọ̀ fún un yín pé, “A ti fi ẹran yìí rú ẹbọ,” ẹ má ṣe jẹ́ ẹ nítorí ẹni ti o sọ fun ọ àti nítorí ẹ̀rí ọkàn.

  8. Èmi ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀rí ọkàn ẹni tí ó sọ fún ọ kì í ṣe tirẹ̀. Nítorí kín ni a ó fi dá mi lẹ́jọ́ nítorí ẹ̀rí ọkàn ẹlòmíràn.

  9. Bí èmi ba fi ọpẹ́ jẹ ẹ́, èéṣe tí a fì ń sọ̀rọ̀ mi ní búburú nítorí ohun tí èmi dúpẹ́ fún.

  10. Nítorí náà tí ẹ̀yin bá jẹ tàbí tí ẹ bá mu tàbí ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sè, e máa ṣe gbogbo rẹ̀ fún ògo Ọlọ́run.

  11. Nítorí náà, má ṣe jẹ́ òkúta ìkọ̀sẹ̀ tí ó lè gbé ẹlòmíràn ṣubú ìbá à ṣe Júù tàbí Giriki tàbí ìjọ Ọlọ́run.

  12. Bí mo ṣè n gbìyànjú láti tẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan lọ́rùn nínú gbogbo nǹkan tí mo bá ń ṣe láì wa ohun rere fún ara mi bí kò ṣe ti ènìyàn púpọ̀ kí ó lè ṣe é ṣe fún wọn láti le ní ìgbàlà.

  13. Bí èmi tilẹ̀ lè sọ oríṣìíríṣìí èdè tí ènìyàn àti ti angẹli, tí n kò bá sì ní ìfẹ́, mo kàn ń pariwo bí ago lásán ni tàbí bí i kimbali olóhùn gooro.

  14. Bí mo bá ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, tí mo sì ní òye gbogbo ohun ìjìnlẹ̀, àti gbogbo ìmọ̀, bí mo sì ni gbogbo ìgbàgbọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí mo lè ṣí àwọn òkè ńlá nídìí, tí èmi kò sì ní ìfẹ́, èmi kò jẹ nǹkan kan.

  15. Bí mo bá fi gbogbo nǹkan tí mo ní tọrẹ fún àwọn aláìní, tí mo sì fi ara mi fún ni láti sùn ṣùgbọ́n tí n kò ní ìfẹ́, kò ní èrè kan fún mi.

  16. Ìfẹ́ a máa mú sùúrù, ìfẹ́ a máa ṣeun, ìfẹ́ kì í ṣe ìlara, ìfẹ́ kì í fẹ̀, ìfẹ́ kì í sọ̀rọ̀ ìgbéraga.

  17. Ìfẹ́ kì í hùwà àìtọ́, kì í wá ohun ara rẹ̀ nìkan. Ìfẹ́ kì í bínú fùfù, ìfẹ́ kì í fi búburú ọmọ ẹnìkejì sínú.

  18. Inú ìfẹ́ kì í dùn sí àìṣòótọ́. Ṣùgbọ́n inú rẹ̀ a máa dùn nígbà gbogbo.

  19. A máa faradà ohun gbogbo sí òtítọ́, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fàyàrán ohun gbogbo.

  20. Ìfẹ́ kì í kùnà láé, kì í sì í yẹ̀ ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, wọn yóò dópin, bí ó bá ṣe ẹ̀bùn ahọ́n ni, wọn yóò dákẹ́, bí ó bá ṣe pé ìmọ̀ ni yóò di asán.

  21. Nítorí àwa mọ̀ ní apá kan, àwa sì sọtẹ́lẹ̀ ní apá kan.

  22. Ṣùgbọ́n nígbà tí èyí ti o pé bá dé, èyí tí í ṣe tí apá kan yóò dópin.

  23. Nígbà tí mó wà ni èwe, èmi á máa sọ̀rọ̀ bi èwe, èmi a máa mòye bí èwe, èmi a máa gbèrò bí èwe. Ṣùgbọ́n nígbà tí mó di ọkùnrin tán, mo fi ìwà èwe sílẹ̀.

  24. Nítorí pé nísinsin yìí àwa ń ríran bàìbàì nínú dígí; nígbà náà a ó rí í lójúkojú. Nísinsin yìí mò mọ̀ pé ní apá kan; nígbà náà èmi o mọ̀ lẹ́kùnrẹ́rẹ́, kódà bí mo ti dí mí mọ̀ pẹ̀lú.

  25. Ǹjẹ́ nísinsin yìí àwọn nǹkan mẹ́ta wọ̀nyí dúró: ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́. Ṣùgbọ́n èyí tí o tóbi jù nínú wọn ni ìfẹ́.